Tuesday, July 15
Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.—Jòh. 21:16.
Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn alàgbà nímọ̀ràn pé kí wọ́n “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (1 Pét. 5:1-4) Tó bá jẹ́ pé alàgbà ni ẹ́, ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ, ó sì wù ẹ́ kó o máa bójú tó wọn. Àmọ́ nígbà míì, ọwọ́ ẹ lè dí tàbí kó rẹ̀ ẹ́ débi pé o ò lè bójú tó àwọn ará. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Pétérù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni.” (1 Pét. 4:11) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan níṣòro tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ẹ̀. Àmọ́, máa rántí pé Jésù Kristi tó jẹ́ “olórí olùṣọ́ àgùntàn” máa ṣe ju ohun tó o lè ṣe fún wọn. Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí, á sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ayé tuntun. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́yin alàgbà máa ṣe ni pé kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, kẹ́ ẹ máa bójú tó wọn, kẹ́ ẹ sì “jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.” w23.09 29-30 ¶13-14
Wednesday, July 16
Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.—1 Kọ́r. 3:20.
Ó yẹ ká yẹra fún ọgbọ́n èèyàn tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun. Tá a bá ń ronú bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ṣe ń ronú, ó lè jẹ́ ká pa Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ tì. (1 Kọ́r. 3:19) “Ọgbọ́n ayé yìí” máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni kan tó wà nílùú Págámù àti Tíátírà ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe bíi tàwọn ará ìlú náà. Jésù bá ìjọ méjèèjì yìí wí lọ́nà tó le torí pé wọ́n gba ìṣekúṣe láyè. (Ìfi. 2:14, 20) Bákan náà lónìí, àwọn èèyàn ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn ará ilé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sì lè fẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé kò sóhun tó burú tá a bá ṣèṣekúṣe àti pé àwọn ìlànà Bíbélì ò bóde mu mọ́. Nígbà míì, a lè máa rò pé Jèhófà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó fẹ́ ká ṣe. Kódà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.—1 Kọ́r. 4:6. w23.07 16 ¶10-11
Thursday, July 17
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.
Màríà ìyá Jésù nílò okun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣègbéyàwó, ó máa lóyún. Kò tíì tọ́mọ rí, àmọ́ òun ló máa tọ́ ọmọ tó máa di Mèsáyà. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé Màríà kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, báwo ló ṣe máa ṣàlàyé fún Jósẹ́fù àfẹ́sọ́nà ẹ̀ pé òun ti lóyún? (Lúùkù 1:26-33) Báwo ni Màríà ṣe rí okun tó nílò gbà? Ó jẹ́ káwọn ẹlòmíì ran òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ní kí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì túbọ̀ ṣàlàyé iṣẹ́ náà fún òun. (Lúùkù 1:34) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó rìnrìn àjò lọ sí “ilẹ̀ olókè” ní Júdà láti lọ wo mọ̀lẹ́bí ẹ̀ Èlísábẹ́tì. Èlísábẹ́tì gbóríyìn fún Màríà, Jèhófà sì fẹ̀mí ẹ̀ darí Èlísábẹ́tì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá nípa ọmọ tí Màríà máa bí. (Lúùkù 1:39-45) Màríà sọ pé Jèhófà “ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára.” (Lúùkù 1:46-51) Torí náà, Jèhófà lo Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì láti fún Màríà lókun. w23.10 14-15 ¶10-12