Wednesday, July 16
Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.—1 Kọ́r. 3:20.
Ó yẹ ká yẹra fún ọgbọ́n èèyàn tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun. Tá a bá ń ronú bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ṣe ń ronú, ó lè jẹ́ ká pa Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ tì. (1 Kọ́r. 3:19) “Ọgbọ́n ayé yìí” máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni kan tó wà nílùú Págámù àti Tíátírà ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe bíi tàwọn ará ìlú náà. Jésù bá ìjọ méjèèjì yìí wí lọ́nà tó le torí pé wọ́n gba ìṣekúṣe láyè. (Ìfi. 2:14, 20) Bákan náà lónìí, àwọn èèyàn ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn ará ilé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sì lè fẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé kò sóhun tó burú tá a bá ṣèṣekúṣe àti pé àwọn ìlànà Bíbélì ò bóde mu mọ́. Nígbà míì, a lè máa rò pé Jèhófà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó fẹ́ ká ṣe. Kódà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.—1 Kọ́r. 4:6. w23.07 16 ¶10-11
Thursday, July 17
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.
Màríà ìyá Jésù nílò okun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣègbéyàwó, ó máa lóyún. Kò tíì tọ́mọ rí, àmọ́ òun ló máa tọ́ ọmọ tó máa di Mèsáyà. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé Màríà kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, báwo ló ṣe máa ṣàlàyé fún Jósẹ́fù àfẹ́sọ́nà ẹ̀ pé òun ti lóyún? (Lúùkù 1:26-33) Báwo ni Màríà ṣe rí okun tó nílò gbà? Ó jẹ́ káwọn ẹlòmíì ran òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ní kí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì túbọ̀ ṣàlàyé iṣẹ́ náà fún òun. (Lúùkù 1:34) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó rìnrìn àjò lọ sí “ilẹ̀ olókè” ní Júdà láti lọ wo mọ̀lẹ́bí ẹ̀ Èlísábẹ́tì. Èlísábẹ́tì gbóríyìn fún Màríà, Jèhófà sì fẹ̀mí ẹ̀ darí Èlísábẹ́tì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá nípa ọmọ tí Màríà máa bí. (Lúùkù 1:39-45) Màríà sọ pé Jèhófà “ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára.” (Lúùkù 1:46-51) Torí náà, Jèhófà lo Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì láti fún Màríà lókun. w23.10 14-15 ¶10-12
Friday, July 18
Ó mú ká di ìjọba kan, àlùfáà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀.—Ìfi. 1:6.
Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ yan díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n sì ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí máa jẹ́ àlùfáà pẹ̀lú Jésù. (Ìfi. 14:1) Ibi Mímọ́ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe fẹ̀mí yàn wọ́n láti jẹ́ ọmọ ẹ̀ nígbà tí wọ́n wà láyé. (Róòmù 8:15-17) Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣàpẹẹrẹ ọ̀run, ibi tí Jèhófà ń gbé. “Aṣọ ìdábùú” tó pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ṣàpẹẹrẹ ara Jésù tí ò jẹ́ kó lè wọlé sọ́run láti ṣiṣẹ́ Àlùfáà Àgbà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Jésù fi ara ẹ̀ rúbọ nítorí aráyé, ohun tó ṣe yìí mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn láti gba ìyè lọ́run. Kí wọ́n lè gba èrè wọn lọ́run, àwọn náà ò ní gbé ẹran ara wọn lọ sọ́run.—Héb. 10:19, 20; 1 Kọ́r. 15:50. w23.10 28 ¶13