Saturday, July 26
Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.—Éfé. 5:1.
Lónìí, a lè múnú Jèhófà dùn tá a bá ń dúpẹ́ oore tó ṣe wá, tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a bá ń wàásù ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jém. 4:8) Inú wa máa ń dùn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, onídàájọ́ òdodo ni, ó gbọ́n, ó lágbára, ó sì tún láwọn ànímọ́ míì tó jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn. A tún máa ń yin Jèhófà, a sì máa ń múnú ẹ̀ dùn bá a ṣe ń sapá láti fara wé e. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn máa kíyè sí pé ìwà wa yàtọ̀ sí tàwọn tí ò mọ Jèhófà nínú ayé burúkú yìí. (Mát. 5:14-16) Bá a ṣe ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, á ṣeé ṣe fún wa láti ṣàlàyé ìdí tí ìwà wa fi yàtọ̀, ìyẹn á sì mú káwọn olóòótọ́ ọkàn wá sin Jèhófà. Tá a bá ń yin Jèhófà lọ́nà yìí, inú ẹ̀ á máa dùn sí wa.—1 Tím. 2:3, 4. w24.02 10 ¶7
Sunday, July 27
Kó lè gbani níyànjú, kó sì báni wí.—Títù 1:9.
Kó o tó lè di ọkùnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ dáadáa nínú ìjọ, á jẹ́ kó o ríṣẹ́ tí wàá fi máa bójú tó ara ẹ tàbí ìdílé ẹ, á sì jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn ẹlòmíì gún. Bí àpẹẹrẹ, kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Bíbélì sọ pé tí ẹnì kan bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tó sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀, ó máa láyọ̀, gbogbo ohun tó bá ń ṣe á sì máa yọrí sí rere. (Sm. 1:1-3) Torí náà, tó bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, á máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́, á sì jẹ́ kó mọ bó ṣe máa fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. (Òwe 1:3, 4) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nílò àwọn ọkùnrin tó lè fi Bíbélì kọ́ni dáadáa, kí wọ́n sì fi gbà wọ́n níyànjú. Tó o bá mọ̀wé kọ tó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa, wàá lè múra àsọyé àti ìdáhùn tó máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, tí wọ́n á sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wàá lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára, wàá sì lè fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí. w23.12 26-27 ¶9-11
Monday, July 28
Ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín tóbi ju ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ayé.—1 Jòh. 4:4.
Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Sátánì ò ní sí mọ́. Àwòrán tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ agbègbè ọdún 2014 jẹ́ ká rí bí bàbá kan ṣe ń jíròrò ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:1-5 pẹ̀lú ìdílé ẹ̀, ó sì sọ ọ́ bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nínú Párádísè ló ń sọ. Ó sọ pé: “Inú ayé tuntun ni inú wa ti máa dùn jù. Àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, wọ́n máa mọ̀wọ̀n ara wọn, wọ́n máa nírẹ̀lẹ̀, wọ́n á máa yin Ọlọ́run, àwọn ọmọ á máa gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu, wọ́n á máa moore, wọ́n á jẹ́ olóòótọ́, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an, àwọn èèyàn á máa gbọ́ ara wọn yé, wọ́n á máa sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn ẹlòmíì, wọ́n á ní ìkóra-ẹni-níjàánu, wọ́n máa níwà tútù, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ohun rere, wọ́n á ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, wọ́n á máa fòye báni lò, wọn ò ní máa gbéra ga, wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dípò ìgbádùn, wọ́n á máa fọkàn sin Ọlọ́run, irú àwọn èèyàn yìí ni kó o máa bá ṣọ̀rẹ́.” Ṣé ìwọ àti ìdílé ẹ tàbí àwọn ará míì jọ máa ń sọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun? w24.01 6 ¶13-14