Friday, August 1
Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.—Sm. 34:19.
Ẹ kíyè sí kókó pàtàkì méjì tó wà nínú sáàmù yìí: (1) Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa ń níṣòro. (2) Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gbà wá? Ọ̀nà kan ni pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìṣòro lè dé bá wa nínú ayé burúkú yìí. Jèhófà ṣèlérí pé a máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun, àmọ́ kò ṣèlérí fún wa pé a ò ní níṣòro kankan. (Àìsá. 66:14) Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa ronú nípa ọjọ́ iwájú níbi tó ti fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé. (2 Kọ́r. 4:16-18) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. (Ìdárò 3:22-24) Kí la kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ àti tòde òní? Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká rí i pé ìṣòro lè dé bá wa nígbàkigbà, àmọ́ tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa bójú tó wa.—Sm. 55:22. w23.04 14-15 ¶3-4
Saturday, August 2
Máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.—Róòmù 13:1.
A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà tí wọ́n ṣègbọràn sí ìjọba bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. (Lúùkù 2:1-6) Nígbà tí oyún inú Màríà pé nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án, ìjọba ṣòfin kan tí ò rọrùn fún wọn láti pa mọ́. Augustus tó ń ṣàkóso ìjọba Róòmù pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ nílùú ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò gba òkè gbágungbàgun lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìrìn àjò náà sì tó nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà (150). Ó dájú pé ìrìn àjò yẹn ò lè rọrùn, pàápàá fún Màríà. Ẹ̀rù lè máa ba àwọn méjèèjì torí wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Màríà àti oyún inú ẹ̀. Wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí Màríà bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí. Ìdí sì ni pé oyún Mèsáyà tí gbogbo èèyàn ń dúró dè ló wà nínú ẹ̀. Ṣéyẹn á wá mú kí wọ́n má ṣègbọràn síjọba? Jósẹ́fù àti Màríà ò jẹ́ káwọn nǹkan yẹn dí wọn lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí òfin yẹn. Inú Jèhófà dùn sí wọn, ó sì jẹ́ kí ìrìn àjò wọn yọrí sí rere. Màríà dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láyọ̀ àti àlàáfíà, ó bí ọmọ náà wẹ́rẹ́, ó sì ṣe ohun tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ!—Míkà 5:2. w23.10 8 ¶9; 9 ¶11-12
Sunday, August 3
Ká máa gba ara wa níyànjú.—Héb. 10:25.
Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti dáhùn nípàdé? Múra ìdáhùn ẹ dáadáa. (Òwe 21:5) Bó o bá ṣe múra ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ lọkàn ẹ máa balẹ̀ láti dáhùn. Bákan náà, jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. (Òwe 15:23; 17:27) Tí ìdáhùn ẹ bá ṣe ṣókí, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́. Tó o bá dáhùn ṣókí lọ́rọ̀ ara ẹ, ìyẹn fi hàn pé o múra sílẹ̀ dáadáa àti pé ohun tá à ń kọ́ yé ẹ. Ká sọ pé o tẹ̀ lé gbogbo àwọn àbá tá a sọ yìí, àmọ́ tẹ́rù ṣì ń bà ẹ́ láti dáhùn ju ẹ̀ẹ̀kan lọ ńkọ́? Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti dáhùn. (Lúùkù 21:1-4) Rántí pé Jèhófà ò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Fílí. 4:5) Ó yẹ kíwọ fúnra ẹ mọ ohun tí agbára ẹ gbé, kó o mọ bó o ṣe máa ṣe é, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà kẹ́rù má bà ẹ́ mọ́. Ohun tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ni pé kó o dáhùn lẹ́ẹ̀kan nípàdé, kó o sì jẹ́ kó ṣe ṣókí. w23.04 21 ¶6-8