ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Thursday, July 31

Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.—Éfé. 5:10.

Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká máa fi òye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” ká sì ṣe é. (Éfé. 5:17) Tá a bá ń wá àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò wa mu, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá sì fi àwọn ìlànà náà sílò, àá ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn. Sátánì “ẹni burúkú náà” máa fẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. (1 Jòh. 5:19) Tí Kristẹni kan ò bá ṣọ́ra, ó máa fi àwọn nǹkan tara, ilé ìwé àti iṣẹ́ ṣáájú àwọn nǹkan tó yẹ kó máa ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe nìyẹn á fi hàn pé òun náà ti ń ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. w24.03 24 ¶16-17

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, August 1

Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.—Sm. 34:19.

Ẹ kíyè sí kókó pàtàkì méjì tó wà nínú sáàmù yìí: (1) Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa ń níṣòro. (2) Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gbà wá? Ọ̀nà kan ni pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìṣòro lè dé bá wa nínú ayé burúkú yìí. Jèhófà ṣèlérí pé a máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun, àmọ́ kò ṣèlérí fún wa pé a ò ní níṣòro kankan. (Àìsá. 66:14) Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa ronú nípa ọjọ́ iwájú níbi tó ti fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé. (2 Kọ́r. 4:​16-18) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. (Ìdárò 3:​22-24) Kí la kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ àti tòde òní? Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká rí i pé ìṣòro lè dé bá wa nígbàkigbà, àmọ́ tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa bójú tó wa.—Sm. 55:22. w23.04 14-15 ¶3-4

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Saturday, August 2

Máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.—Róòmù 13:1.

A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà tí wọ́n ṣègbọràn sí ìjọba bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. (Lúùkù 2:​1-6) Nígbà tí oyún inú Màríà pé nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án, ìjọba ṣòfin kan tí ò rọrùn fún wọn láti pa mọ́. Augustus tó ń ṣàkóso ìjọba Róòmù pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ nílùú ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò gba òkè gbágungbàgun lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìrìn àjò náà sì tó nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà (150). Ó dájú pé ìrìn àjò yẹn ò lè rọrùn, pàápàá fún Màríà. Ẹ̀rù lè máa ba àwọn méjèèjì torí wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Màríà àti oyún inú ẹ̀. Wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí Màríà bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí. Ìdí sì ni pé oyún Mèsáyà tí gbogbo èèyàn ń dúró dè ló wà nínú ẹ̀. Ṣéyẹn á wá mú kí wọ́n má ṣègbọràn síjọba? Jósẹ́fù àti Màríà ò jẹ́ káwọn nǹkan yẹn dí wọn lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí òfin yẹn. Inú Jèhófà dùn sí wọn, ó sì jẹ́ kí ìrìn àjò wọn yọrí sí rere. Màríà dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láyọ̀ àti àlàáfíà, ó bí ọmọ náà wẹ́rẹ́, ó sì ṣe ohun tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ!—Míkà 5:2. w23.10 8 ¶9; 9 ¶11-12

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́