ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Wednesday, July 30

A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.—Ìṣe 4:20.

Ó yẹ káwa náà máa wàásù bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé ká má wàásù mọ́. Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà àti ọgbọ́n. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fara da àìsàn, ìdààmú ọkàn, ikú èèyàn wa kan, ìṣòro ìdílé tó le gan-an, inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì. Àwọn nǹkan bí àjàkálẹ̀ àrùn àti ogun sì ti mú káwọn nǹkan yìí túbọ̀ nira fáwọn ará wa. Torí náà, sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Sọ ìṣòro tó o ní fún Jèhófà bó o ṣe máa sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa “gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.” (Sm. 37:​3, 5) Tá a bá tẹra mọ́ àdúrà, ó máa jẹ́ ká “fara da ìpọ́njú.” (Róòmù 12:12) Jèhófà mọ ohun táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ń bá yí, ‘ó sì máa ń gbọ́ igbe wa tá a bá ní kó ràn wá lọ́wọ́.’—Sm. 145:​18, 19. w23.05 5-6 ¶12-15

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Thursday, July 31

Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.—Éfé. 5:10.

Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká máa fi òye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” ká sì ṣe é. (Éfé. 5:17) Tá a bá ń wá àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò wa mu, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá sì fi àwọn ìlànà náà sílò, àá ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn. Sátánì “ẹni burúkú náà” máa fẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. (1 Jòh. 5:19) Tí Kristẹni kan ò bá ṣọ́ra, ó máa fi àwọn nǹkan tara, ilé ìwé àti iṣẹ́ ṣáájú àwọn nǹkan tó yẹ kó máa ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe nìyẹn á fi hàn pé òun náà ti ń ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. w24.03 24 ¶16-17

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, August 1

Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.—Sm. 34:19.

Ẹ kíyè sí kókó pàtàkì méjì tó wà nínú sáàmù yìí: (1) Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa ń níṣòro. (2) Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gbà wá? Ọ̀nà kan ni pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìṣòro lè dé bá wa nínú ayé burúkú yìí. Jèhófà ṣèlérí pé a máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun, àmọ́ kò ṣèlérí fún wa pé a ò ní níṣòro kankan. (Àìsá. 66:14) Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa ronú nípa ọjọ́ iwájú níbi tó ti fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé. (2 Kọ́r. 4:​16-18) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó. (Ìdárò 3:​22-24) Kí la kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ àti tòde òní? Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká rí i pé ìṣòro lè dé bá wa nígbàkigbà, àmọ́ tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa bójú tó wa.—Sm. 55:22. w23.04 14-15 ¶3-4

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́