Tuesday, July 29
Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.—Lúùkù 3:22.
Ó dájú pé ọkàn wa balẹ̀ gan-an bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí gbogbo àwa èèyàn ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm. 149:4) Àmọ́ nígbà míì, àwọn kan máa ń rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì máa ń bi ara wọn pé, ‘Ṣé inú Jèhófà ń dùn sí mi ṣá?’ Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn náà rẹ̀wẹ̀sì láwọn ìgbà kan, ó sì ṣòro fún wọn láti gbà pé inú Jèhófà ń dùn sí wọn. (1 Sám. 1:6-10; Jóòbù 29:2, 4; Sm. 51:11) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sí àwa èèyàn aláìpé. Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe kínú ẹ̀ tó lè dùn sí wa? A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ká sì ṣèrìbọmi. (Jòh. 3:16) Ìyẹn lá fi hàn pé a ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sì ti ṣèlérí fún Ọlọ́run pé ìfẹ́ rẹ̀ la máa ṣe. (Ìṣe 2:38; 3:19) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì kà wá sí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́.—Sm. 25:14. w24.03 26 ¶1-2
Wednesday, July 30
A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.—Ìṣe 4:20.
Ó yẹ káwa náà máa wàásù bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé ká má wàásù mọ́. Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà àti ọgbọ́n. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fara da àìsàn, ìdààmú ọkàn, ikú èèyàn wa kan, ìṣòro ìdílé tó le gan-an, inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì. Àwọn nǹkan bí àjàkálẹ̀ àrùn àti ogun sì ti mú káwọn nǹkan yìí túbọ̀ nira fáwọn ará wa. Torí náà, sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Sọ ìṣòro tó o ní fún Jèhófà bó o ṣe máa sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa “gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.” (Sm. 37:3, 5) Tá a bá tẹra mọ́ àdúrà, ó máa jẹ́ ká “fara da ìpọ́njú.” (Róòmù 12:12) Jèhófà mọ ohun táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ń bá yí, ‘ó sì máa ń gbọ́ igbe wa tá a bá ní kó ràn wá lọ́wọ́.’—Sm. 145:18, 19. w23.05 5-6 ¶12-15
Thursday, July 31
Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.—Éfé. 5:10.
Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká máa fi òye mọ “ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” ká sì ṣe é. (Éfé. 5:17) Tá a bá ń wá àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò wa mu, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá sì fi àwọn ìlànà náà sílò, àá ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn. Sátánì “ẹni burúkú náà” máa fẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ débi tá ò fi ní ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. (1 Jòh. 5:19) Tí Kristẹni kan ò bá ṣọ́ra, ó máa fi àwọn nǹkan tara, ilé ìwé àti iṣẹ́ ṣáájú àwọn nǹkan tó yẹ kó máa ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe nìyẹn á fi hàn pé òun náà ti ń ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí wọ́n gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. w24.03 24 ¶16-17