ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Sunday, August 3

Ká máa gba ara wa níyànjú.—Héb. 10:25.

Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti dáhùn nípàdé? Múra ìdáhùn ẹ dáadáa. (Òwe 21:5) Bó o bá ṣe múra ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ lọkàn ẹ máa balẹ̀ láti dáhùn. Bákan náà, jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. (Òwe 15:23; 17:27) Tí ìdáhùn ẹ bá ṣe ṣókí, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́. Tó o bá dáhùn ṣókí lọ́rọ̀ ara ẹ, ìyẹn fi hàn pé o múra sílẹ̀ dáadáa àti pé ohun tá à ń kọ́ yé ẹ. Ká sọ pé o tẹ̀ lé gbogbo àwọn àbá tá a sọ yìí, àmọ́ tẹ́rù ṣì ń bà ẹ́ láti dáhùn ju ẹ̀ẹ̀kan lọ ńkọ́? Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti dáhùn. (Lúùkù 21:​1-4) Rántí pé Jèhófà ò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Fílí. 4:5) Ó yẹ kíwọ fúnra ẹ mọ ohun tí agbára ẹ gbé, kó o mọ bó o ṣe máa ṣe é, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà kẹ́rù má bà ẹ́ mọ́. Ohun tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ni pé kó o dáhùn lẹ́ẹ̀kan nípàdé, kó o sì jẹ́ kó ṣe ṣókí. w23.04 21 ¶6-8

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, August 4

Gbé àwo ìgbàyà wọ̀, kí o sì dé akoto.—1 Tẹs. 5:8.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwa Kristẹni wé àwọn sójà tó máa ń wà lójúfò, tí wọ́n sì máa ń múra sílẹ̀ de ogun. Àwọn èèyàn gbà pé ó yẹ kí sójà kan múra sílẹ̀ láti jà torí ìgbàkigbà ni ogun lè dé. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ là ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà, ó yẹ ká gbé àwo ìgbàyà wọ̀, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, ká sì dé akoto, ìyẹn ìrètí tá a ní. Àwo ìgbàyà máa ń dáàbò bo àyà sójà kan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. Àwọn ànímọ́ yìí máa ń jẹ́ ká sin Jèhófà nìṣó, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ìgbàgbọ́ tá a ní máa ń jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa san èrè fún wa tá a bá sìn ín tọkàntọkàn. (Héb. 11:6) Ó máa ń jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jésù Aṣáájú wa kódà bá a tiẹ̀ ń fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro. A lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lásìkò wa yìí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fara da inúnibíni tàbí ìṣòro àìlówó lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá fẹ́ kó sínú ìdẹkùn kíkó ohun ìní jọ, ó yẹ ká máa fara wé àwọn tí wọ́n jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. w23.06 10 ¶8-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, August 5

Ẹni tó bá ń wo ṣíṣú òjò kò ní kórè.—Oníw. 11:4.

Ẹni tó bá ń kó ara ẹ̀ níjàánu máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa ṣe ohun tí ò dáa. A gbọ́dọ̀ kó ara wa níjàánu kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn wa, pàápàá tí ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn ò bá rọrùn tàbí tí kò bá wù wá. Máa rántí pé ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára àwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní, torí náà bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kó o lè túbọ̀ máa kó ara ẹ níjàánu. (Lúùkù 11:13; Gál. 5:​22, 23) Má dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dán mọ́rán. Kò dájú pé ìgbà kan máa wà tí gbogbo nǹkan á dán mọ́rán fún wa nínú ayé yìí. Torí náà, tá a bá sọ pé a fẹ́ dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dáa, ọwọ́ wa lè má tẹ àfojúsùn wa. A lè rẹ̀wẹ̀sì torí ó lè máa ṣe wá bíi pé ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn ti le jù, ọwọ́ wa ò sì ní lè tẹ̀ ẹ́. Tó bá jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, ṣé o lè ronú nípa àwọn àfojúsùn míì tọ́wọ́ ẹ lè tètè tẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ànímọ́ kan ló wù ẹ́ kó o ní, o ò ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ànímọ́ náà hàn díẹ̀díẹ̀? Tó bá jẹ́ àfojúsùn ẹ ni pé kó o ka gbogbo Bíbélì parí, á dáa kó o kọ́kọ́ máa fi àkókò díẹ̀ kà á lójoojúmọ́. w23.05 29 ¶11-13

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́