Saturday, September 13
O ṣeyebíye gan-an.—Dán. 9:23.
Ọ̀dọ́ ni wòlíì Dáníẹ́lì nígbà táwọn ará Bábílónì mú un nígbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sílùú Bábílónì. Àmọ́, ohun táwọn ìjòyè Bábílónì rí lára Dáníẹ́lì wú wọn lórí. Wọ́n rí i pé Dáníẹ́lì ‘kò ní àbùkù kankan, ìrísí ẹ̀ dáa,’ ilé ọlá ló sì ti wá. (1 Sám. 16:7) Àwọn nǹkan tí wọ́n rí lára Dáníẹ́lì yìí ló jẹ́ káwọn ará Bábílónì dá a lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa ṣiṣẹ́ láàfin. (Dán. 1:3, 4, 6) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì torí pé ó níwà ọmọlúàbí. Kódà, ó ṣeé ṣe kó ku díẹ̀ kí Dáníẹ́lì pé ọmọ ogún (20) ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lógún ọdún nígbà tí Jèhófà dárúkọ ẹ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀, irú bíi Nóà àti Jóòbù tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún bá Ọlọ́run rìn, tí wọ́n sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jẹ́n. 5:32; 6:9, 10; Jóòbù 42:16, 17; Ìsík. 14:14) Jèhófà ò yéé nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀.—Dán. 10:11, 19. w23.08 2 ¶1-2
Sunday, September 14
Ẹ lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́.—Éfé. 3:18.
Tó o bá fẹ́ ra ilé kan, ó dájú pé wàá fẹ́ lọ síbẹ̀ fúnra ẹ, kó o sì rí gbogbo ohun tó wà nínú ilé náà. A lè ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ tá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá yára kà á, “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ti Ọlọ́run” nìkan lo máa mọ̀. (Héb. 5:12) Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kó o lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà nínú ẹ̀, ìyẹn máa dà bíi pé o “wọnú” ilé tó o fẹ́ rà. Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kó o wo bí ohun tó sọ níbì kan ṣe tan mọ́ ohun tó sọ láwọn ibòmíì. Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó o gbà gbọ́ nìkan ló yẹ kó o mọ̀, ó tún yẹ kó o mọ ìdí tó o fi gba àwọn nǹkan náà gbọ́. Tá a bá fẹ́ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin níyànjú pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n “lè lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn á ‘ta gbòǹgbò, á sì fìdí múlẹ̀.’ (Éfé. 3:14-19) Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. w23.10 18 ¶1-3
Monday, September 15
Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí àwọn wòlíì tó sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ fún yín nínú jíjìyà ibi àti níní sùúrù.—Jém. 5:10.
Àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tó ní sùúrù wà nínú Bíbélì. O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nígbà tó o bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́? Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí Dáfídì ṣì kéré gan-an ni Jèhófà ti ní kí wọ́n yàn án láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún ló fi dúró kó tó di ọba. Síméónì àti Ánà náà jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn lásìkò tí wọ́n ń dúró kí Mèsáyà dé. (Lúùkù 2:25, 36-38) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtàn Bíbélì yẹn, wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló jẹ́ kí ẹni yìí ní sùúrù? Àǹfààní wo lẹni náà rí torí pé ó ní sùúrù? Báwo ni mo ṣe lè fara wé e? Bákan náà, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tí kò ní sùúrù, wàá jàǹfààní. (1 Sám. 13:8-14) O lè bi ara ẹ pé: ‘Kí ni ò jẹ́ kí wọ́n ní sùúrù? Àwọn nǹkan burúkú wo ló ṣẹlẹ̀ sí wọn torí pé wọn ò ní sùúrù?’ w23.08 25 ¶15