ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Friday, September 12

Ìrísí ayé yìí ń yí pa dà.—1 Kọ́r. 7:31.

Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o máa ń fòye báni lò. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó máa ń fòye báni lò, tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan, tó sì máa ń rára gba nǹkan sí? Ṣé kì í ṣe ẹni tó le koko tó sì lágídí làwọn èèyàn mọ̀ mí sí? Ṣé mo máa ń rin kinkin pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan bí mo ṣe lérò pé ó yẹ ká ṣe é gẹ́lẹ́? Ṣé mo máa ń tẹ́tí sáwọn ẹlòmíì, tí mo sì máa ń gba èrò wọn nígbà tí mo bá rí i pé ó yẹ kí n ṣe bẹ́ẹ̀?’ Bá a bá ṣe túbọ̀ ń fòye bá àwọn èèyàn lò, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fara wé Jèhófà àti Jésù. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń fòye báni lò, kò yẹ ká máa rin kinkin mọ́ èrò wa tí nǹkan bá yí pa dà nígbèésí ayé wa. Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ lè mú ká láwọn ìṣòro tá ò rò tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣe wá. Ohun míì ni pé lójijì, ọrọ̀ ajé lè dẹnu kọlẹ̀ tàbí kí ọ̀rọ̀ òṣèlú dá wàhálà sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè wa, gbogbo ìyẹn sì lè mú kí nǹkan tojú súni. (Oníw. 9:11) Kódà, nǹkan lè nira tí iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa bá yí pa dà. Àá lè fara da ipò èyíkéyìí tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, (1) gbà pé nǹkan ti yí pa dà báyìí, (2) má ṣe máa ronú nípa ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, ohun tó o máa ṣe sọ́rọ̀ náà ni kó o máa rò, (3) máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àti (4) máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. w23.07 21-22 ¶7-8

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Saturday, September 13

O ṣeyebíye gan-an.—Dán. 9:23.

Ọ̀dọ́ ni wòlíì Dáníẹ́lì nígbà táwọn ará Bábílónì mú un nígbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sílùú Bábílónì. Àmọ́, ohun táwọn ìjòyè Bábílónì rí lára Dáníẹ́lì wú wọn lórí. Wọ́n rí i pé Dáníẹ́lì ‘kò ní àbùkù kankan, ìrísí ẹ̀ dáa,’ ilé ọlá ló sì ti wá. (1 Sám. 16:7) Àwọn nǹkan tí wọ́n rí lára Dáníẹ́lì yìí ló jẹ́ káwọn ará Bábílónì dá a lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa ṣiṣẹ́ láàfin. (Dán. 1:​3, 4, 6) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì torí pé ó níwà ọmọlúàbí. Kódà, ó ṣeé ṣe kó ku díẹ̀ kí Dáníẹ́lì pé ọmọ ogún (20) ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lógún ọdún nígbà tí Jèhófà dárúkọ ẹ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀, irú bíi Nóà àti Jóòbù tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún bá Ọlọ́run rìn, tí wọ́n sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jẹ́n. 5:32; 6:​9, 10; Jóòbù 42:​16, 17; Ìsík. 14:14) Jèhófà ò yéé nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀.—Dán. 10:​11, 19. w23.08 2 ¶1-2

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Sunday, September 14

Ẹ lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́.—Éfé. 3:18.

Tó o bá fẹ́ ra ilé kan, ó dájú pé wàá fẹ́ lọ síbẹ̀ fúnra ẹ, kó o sì rí gbogbo ohun tó wà nínú ilé náà. A lè ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ tá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá yára kà á, “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ti Ọlọ́run” nìkan lo máa mọ̀. (Héb. 5:12) Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kó o lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà nínú ẹ̀, ìyẹn máa dà bíi pé o “wọnú” ilé tó o fẹ́ rà. Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kó o wo bí ohun tó sọ níbì kan ṣe tan mọ́ ohun tó sọ láwọn ibòmíì. Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó o gbà gbọ́ nìkan ló yẹ kó o mọ̀, ó tún yẹ kó o mọ ìdí tó o fi gba àwọn nǹkan náà gbọ́. Tá a bá fẹ́ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin níyànjú pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n “lè lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn á ‘ta gbòǹgbò, á sì fìdí múlẹ̀.’ (Éfé. 3:​14-19) Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. w23.10 18 ¶1-3

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́