Thursday, September 11
Ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn.—2 Kọ́r. 8:24.
Àwa náà lè fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń bá wọn ṣọ̀rẹ́. (2 Kọ́r. 6:11-13) Ọ̀pọ̀ lára wa ló wà nínú ìjọ tí ìwà àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn á túbọ̀ máa lágbára tá a bá ń wo ibi tí wọ́n dáa sí. Torí náà, tá a bá ń wo àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn nìyẹn. Ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà ìpọ́njú ńlá. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà ní káwọn èèyàn òun ṣe nígbà táwọn kan gbógun ja ìlú Bábílónì àtijọ́. Ó sọ pé: “Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú, kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín. Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀, títí ìbínú náà fi máa kọjá lọ.” (Àìsá. 26:20) Ó ṣeé ṣe káwa náà tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn yìí nígbà ìpọ́njú ńlá. w23.07 6-7 ¶14-16
Friday, September 12
Ìrísí ayé yìí ń yí pa dà.—1 Kọ́r. 7:31.
Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o máa ń fòye báni lò. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó máa ń fòye báni lò, tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan, tó sì máa ń rára gba nǹkan sí? Ṣé kì í ṣe ẹni tó le koko tó sì lágídí làwọn èèyàn mọ̀ mí sí? Ṣé mo máa ń rin kinkin pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan bí mo ṣe lérò pé ó yẹ ká ṣe é gẹ́lẹ́? Ṣé mo máa ń tẹ́tí sáwọn ẹlòmíì, tí mo sì máa ń gba èrò wọn nígbà tí mo bá rí i pé ó yẹ kí n ṣe bẹ́ẹ̀?’ Bá a bá ṣe túbọ̀ ń fòye bá àwọn èèyàn lò, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fara wé Jèhófà àti Jésù. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń fòye báni lò, kò yẹ ká máa rin kinkin mọ́ èrò wa tí nǹkan bá yí pa dà nígbèésí ayé wa. Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ lè mú ká láwọn ìṣòro tá ò rò tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣe wá. Ohun míì ni pé lójijì, ọrọ̀ ajé lè dẹnu kọlẹ̀ tàbí kí ọ̀rọ̀ òṣèlú dá wàhálà sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè wa, gbogbo ìyẹn sì lè mú kí nǹkan tojú súni. (Oníw. 9:11) Kódà, nǹkan lè nira tí iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa bá yí pa dà. Àá lè fara da ipò èyíkéyìí tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, (1) gbà pé nǹkan ti yí pa dà báyìí, (2) má ṣe máa ronú nípa ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, ohun tó o máa ṣe sọ́rọ̀ náà ni kó o máa rò, (3) máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àti (4) máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. w23.07 21-22 ¶7-8
Saturday, September 13
O ṣeyebíye gan-an.—Dán. 9:23.
Ọ̀dọ́ ni wòlíì Dáníẹ́lì nígbà táwọn ará Bábílónì mú un nígbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sílùú Bábílónì. Àmọ́, ohun táwọn ìjòyè Bábílónì rí lára Dáníẹ́lì wú wọn lórí. Wọ́n rí i pé Dáníẹ́lì ‘kò ní àbùkù kankan, ìrísí ẹ̀ dáa,’ ilé ọlá ló sì ti wá. (1 Sám. 16:7) Àwọn nǹkan tí wọ́n rí lára Dáníẹ́lì yìí ló jẹ́ káwọn ará Bábílónì dá a lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa ṣiṣẹ́ láàfin. (Dán. 1:3, 4, 6) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì torí pé ó níwà ọmọlúàbí. Kódà, ó ṣeé ṣe kó ku díẹ̀ kí Dáníẹ́lì pé ọmọ ogún (20) ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lógún ọdún nígbà tí Jèhófà dárúkọ ẹ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀, irú bíi Nóà àti Jóòbù tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún bá Ọlọ́run rìn, tí wọ́n sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jẹ́n. 5:32; 6:9, 10; Jóòbù 42:16, 17; Ìsík. 14:14) Jèhófà ò yéé nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀.—Dán. 10:11, 19. w23.08 2 ¶1-2