ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Wednesday, September 10

Síbẹ̀ tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.—1 Kọ́r. 9:17.

Kí lo lè ṣe tó o bá rí i pé àdúrà ẹ ò tọkàn wá mọ́ tàbí pé o ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Má ṣe ronú pé ẹ̀mí Jèhófà ti fi ẹ́ sílẹ̀. Torí pé aláìpé ni ẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ á máa yàtọ̀ látìgbàdégbà. Tí ìtara ẹ bá ń jó rẹ̀yìn, ronú nípa àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gbìyànjú láti fara wé Jésù, nígbà míì kì í lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù ti pinnu pé òun máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun parí láìka bí nǹkan ṣe rí fún un lásìkò yẹn. Lọ́nà kan náà, má ṣe ìpinnu torí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Pinnu pé ohun tó tọ́ lo máa ṣe, tí ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ṣe nǹkan tó tọ́ nígbà gbogbo, tó bá yá, nǹkan tó dáa lá máa wù ẹ́ ṣe.—1 Kọ́r. 9:16. w24.03 11 ¶12-13

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Thursday, September 11

Ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn.—2 Kọ́r. 8:24.

Àwa náà lè fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń bá wọn ṣọ̀rẹ́. (2 Kọ́r. 6:​11-13) Ọ̀pọ̀ lára wa ló wà nínú ìjọ tí ìwà àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn á túbọ̀ máa lágbára tá a bá ń wo ibi tí wọ́n dáa sí. Torí náà, tá a bá ń wo àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn nìyẹn. Ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà ìpọ́njú ńlá. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà ní káwọn èèyàn òun ṣe nígbà táwọn kan gbógun ja ìlú Bábílónì àtijọ́. Ó sọ pé: “Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú, kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín. Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀, títí ìbínú náà fi máa kọjá lọ.” (Àìsá. 26:20) Ó ṣeé ṣe káwa náà tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn yìí nígbà ìpọ́njú ńlá. w23.07 6-7 ¶14-16

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, September 12

Ìrísí ayé yìí ń yí pa dà.—1 Kọ́r. 7:31.

Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o máa ń fòye báni lò. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó máa ń fòye báni lò, tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan, tó sì máa ń rára gba nǹkan sí? Ṣé kì í ṣe ẹni tó le koko tó sì lágídí làwọn èèyàn mọ̀ mí sí? Ṣé mo máa ń rin kinkin pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan bí mo ṣe lérò pé ó yẹ ká ṣe é gẹ́lẹ́? Ṣé mo máa ń tẹ́tí sáwọn ẹlòmíì, tí mo sì máa ń gba èrò wọn nígbà tí mo bá rí i pé ó yẹ kí n ṣe bẹ́ẹ̀?’ Bá a bá ṣe túbọ̀ ń fòye bá àwọn èèyàn lò, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fara wé Jèhófà àti Jésù. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń fòye báni lò, kò yẹ ká máa rin kinkin mọ́ èrò wa tí nǹkan bá yí pa dà nígbèésí ayé wa. Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ lè mú ká láwọn ìṣòro tá ò rò tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣe wá. Ohun míì ni pé lójijì, ọrọ̀ ajé lè dẹnu kọlẹ̀ tàbí kí ọ̀rọ̀ òṣèlú dá wàhálà sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè wa, gbogbo ìyẹn sì lè mú kí nǹkan tojú súni. (Oníw. 9:11) Kódà, nǹkan lè nira tí iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa bá yí pa dà. Àá lè fara da ipò èyíkéyìí tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, (1) gbà pé nǹkan ti yí pa dà báyìí, (2) má ṣe máa ronú nípa ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, ohun tó o máa ṣe sọ́rọ̀ náà ni kó o máa rò, (3) máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àti (4) máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. w23.07 21-22 ¶7-8

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́