Tuesday, September 9
Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo. Òpè ni.—Òwe 9:13.
Àwọn tó ń gbọ́ ohun tí “òmùgọ̀ obìnrin” yẹn ń sọ máa ní láti ṣe ìpinnu: Ṣé wọ́n máa lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ àbí wọn ò ní lọ? Ìdí pàtàkì wà tí ò fi yẹ ká ṣèṣekúṣe. Bíbélì ní “òmùgọ̀ obìnrin” ń sọ pé: “Omi tí a jí gbé máa ń dùn.” (Òwe 9:17) Kí ni “omi tí a jí gbé”? Bíbélì sọ pé ìbálòpọ̀ tó wà láàárín tọkọtaya dà bí omi tó ń tuni lára. (Òwe 5:15-18) Ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó sì máa ń gbádùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wọn tí wọ́n bá ṣe é lọ́nà tó tọ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí “omi tí a jí gbé,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbálòpọ̀ tí ò bófin mu tó ń wáyé láàárín àwọn tí ò bá ara wọn ṣègbéyàwó. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n ń bára wọn lò pọ̀. Ṣe ló dà bí olè tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ tó bá fẹ́ jí nǹkan. “Omi tí a jí gbé” máa ń dùn lẹ́nu àwọn tó ń mu ún torí wọ́n rò pé wọn ò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ẹ ò rí i pé wọ́n ń tan ara wọn jẹ ni! Jèhófà ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Kò sí nǹkan tó korò tó kéèyàn pàdánù ojú rere Jèhófà, torí náà kò sí adùn kankan níbẹ̀.—1 Kọ́r. 6:9, 10. w23.06 22 ¶7-9
Wednesday, September 10
Síbẹ̀ tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.—1 Kọ́r. 9:17.
Kí lo lè ṣe tó o bá rí i pé àdúrà ẹ ò tọkàn wá mọ́ tàbí pé o ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Má ṣe ronú pé ẹ̀mí Jèhófà ti fi ẹ́ sílẹ̀. Torí pé aláìpé ni ẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ á máa yàtọ̀ látìgbàdégbà. Tí ìtara ẹ bá ń jó rẹ̀yìn, ronú nípa àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gbìyànjú láti fara wé Jésù, nígbà míì kì í lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù ti pinnu pé òun máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun parí láìka bí nǹkan ṣe rí fún un lásìkò yẹn. Lọ́nà kan náà, má ṣe ìpinnu torí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Pinnu pé ohun tó tọ́ lo máa ṣe, tí ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ṣe nǹkan tó tọ́ nígbà gbogbo, tó bá yá, nǹkan tó dáa lá máa wù ẹ́ ṣe.—1 Kọ́r. 9:16. w24.03 11 ¶12-13
Thursday, September 11
Ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn.—2 Kọ́r. 8:24.
Àwa náà lè fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń bá wọn ṣọ̀rẹ́. (2 Kọ́r. 6:11-13) Ọ̀pọ̀ lára wa ló wà nínú ìjọ tí ìwà àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn á túbọ̀ máa lágbára tá a bá ń wo ibi tí wọ́n dáa sí. Torí náà, tá a bá ń wo àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn nìyẹn. Ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà ìpọ́njú ńlá. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà ní káwọn èèyàn òun ṣe nígbà táwọn kan gbógun ja ìlú Bábílónì àtijọ́. Ó sọ pé: “Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú, kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín. Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀, títí ìbínú náà fi máa kọjá lọ.” (Àìsá. 26:20) Ó ṣeé ṣe káwa náà tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn yìí nígbà ìpọ́njú ńlá. w23.07 6-7 ¶14-16