Monday, September 8
Ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa.—1 Tẹs. 5:12.
Kò tíì pé ọdún kan tí wọ́n dá ìjọ Tẹsalóníkà sílẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí wọn. Torí náà, àwọn alábòójútó tí wọ́n yàn síbẹ̀ lè má fi bẹ́ẹ̀ nírìírí, wọ́n sì lè ṣe àwọn àṣìṣe kan. Síbẹ̀, àwọn ará ìjọ náà ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé, ó máa gba pé ká túbọ̀ máa ṣe ohun táwọn alàgbà ìjọ wa bá sọ fún wa ju bá a ṣe ń ṣe lọ báyìí. Ìdí ni pé ó lè má ṣeé ṣe láti kàn sí orílé iṣẹ́ wa tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa mọ́ nígbà yẹn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́, ká sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ wa báyìí. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ronú bó ṣe tọ́. Ká má máa wo kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ohun tó yẹ ká máa wò ni pé Jèhófà ti yan Kristi láti máa darí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí. Bí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí tá a ní pé Jèhófà máa gbà wá là lọ́jọ́ iwájú máa ń dáàbò bò wá ká lè máa ronú bó ṣe tọ́. A mọ̀ pé kò sóhun rere kankan tí ayé yìí lè fún wa. (Fílí. 3:8) Ìrètí yìí ló ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. w23.06 11-12 ¶11-12
Tuesday, September 9
Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo. Òpè ni.—Òwe 9:13.
Àwọn tó ń gbọ́ ohun tí “òmùgọ̀ obìnrin” yẹn ń sọ máa ní láti ṣe ìpinnu: Ṣé wọ́n máa lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ àbí wọn ò ní lọ? Ìdí pàtàkì wà tí ò fi yẹ ká ṣèṣekúṣe. Bíbélì ní “òmùgọ̀ obìnrin” ń sọ pé: “Omi tí a jí gbé máa ń dùn.” (Òwe 9:17) Kí ni “omi tí a jí gbé”? Bíbélì sọ pé ìbálòpọ̀ tó wà láàárín tọkọtaya dà bí omi tó ń tuni lára. (Òwe 5:15-18) Ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó sì máa ń gbádùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wọn tí wọ́n bá ṣe é lọ́nà tó tọ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí “omi tí a jí gbé,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbálòpọ̀ tí ò bófin mu tó ń wáyé láàárín àwọn tí ò bá ara wọn ṣègbéyàwó. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n ń bára wọn lò pọ̀. Ṣe ló dà bí olè tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ tó bá fẹ́ jí nǹkan. “Omi tí a jí gbé” máa ń dùn lẹ́nu àwọn tó ń mu ún torí wọ́n rò pé wọn ò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ẹ ò rí i pé wọ́n ń tan ara wọn jẹ ni! Jèhófà ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Kò sí nǹkan tó korò tó kéèyàn pàdánù ojú rere Jèhófà, torí náà kò sí adùn kankan níbẹ̀.—1 Kọ́r. 6:9, 10. w23.06 22 ¶7-9
Wednesday, September 10
Síbẹ̀ tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.—1 Kọ́r. 9:17.
Kí lo lè ṣe tó o bá rí i pé àdúrà ẹ ò tọkàn wá mọ́ tàbí pé o ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Má ṣe ronú pé ẹ̀mí Jèhófà ti fi ẹ́ sílẹ̀. Torí pé aláìpé ni ẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ á máa yàtọ̀ látìgbàdégbà. Tí ìtara ẹ bá ń jó rẹ̀yìn, ronú nípa àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gbìyànjú láti fara wé Jésù, nígbà míì kì í lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù ti pinnu pé òun máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun parí láìka bí nǹkan ṣe rí fún un lásìkò yẹn. Lọ́nà kan náà, má ṣe ìpinnu torí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Pinnu pé ohun tó tọ́ lo máa ṣe, tí ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ṣe nǹkan tó tọ́ nígbà gbogbo, tó bá yá, nǹkan tó dáa lá máa wù ẹ́ ṣe.—1 Kọ́r. 9:16. w24.03 11 ¶12-13