ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Monday, September 15

Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí àwọn wòlíì tó sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ fún yín nínú jíjìyà ibi àti níní sùúrù.—Jém. 5:10.

Àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tó ní sùúrù wà nínú Bíbélì. O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nígbà tó o bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́? Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí Dáfídì ṣì kéré gan-an ni Jèhófà ti ní kí wọ́n yàn án láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún ló fi dúró kó tó di ọba. Síméónì àti Ánà náà jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn lásìkò tí wọ́n ń dúró kí Mèsáyà dé. (Lúùkù 2:​25, 36-38) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtàn Bíbélì yẹn, wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló jẹ́ kí ẹni yìí ní sùúrù? Àǹfààní wo lẹni náà rí torí pé ó ní sùúrù? Báwo ni mo ṣe lè fara wé e? Bákan náà, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tí kò ní sùúrù, wàá jàǹfààní. (1 Sám. 13:​8-14) O lè bi ara ẹ pé: ‘Kí ni ò jẹ́ kí wọ́n ní sùúrù? Àwọn nǹkan burúkú wo ló ṣẹlẹ̀ sí wọn torí pé wọn ò ní sùúrù?’ w23.08 25 ¶15

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, September 16

A ti gbà gbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.—Jòh. 6:69.

Àpọ́sítẹ́lì Pétérù jẹ́ olóòótọ́, kò sì jẹ́ kó sú òun láti máa tẹ̀ lé Jésù. Nígbà kan tí Jésù sọ ohun tí kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, Pétérù ṣe ohun tó fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́. (Jòh. 6:68) Dípò kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ní sùúrù, kí wọ́n sì gbọ́ àlàyé tí Jésù máa ṣe, ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára wọn fi Jésù sílẹ̀. Àmọ́ Pétérù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó mọ̀ pé Jésù ló ní “àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” Jésù mọ̀ pé Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù máa sá fi òun sílẹ̀. Síbẹ̀, Jésù sọ fún Pétérù pé ó máa pa dà, ó sì máa jẹ́ olóòótọ́. (Lúùkù 22:​31, 32) Jésù mọ̀ dáadáa pé “ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.” (Máàkù 14:38) Kódà, lẹ́yìn tí Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rárá, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Pétérù dá wà. (Máàkù 16:7; Lúùkù 24:34; 1 Kọ́r. 15:5) Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa fún Pétérù lókun gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣàṣìṣe! w23.09 22 ¶9-10

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Wednesday, September 17

Aláyọ̀ ni àwọn tí a dárí ìwà wọn tí kò bófin mu jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.—Róòmù 4:7.

Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ jì wọ́n. Ó máa ń dárí jì wọ́n pátápátá, kò sì ní ka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. (Sm. 32:​1, 2) Jèhófà máa ń ka irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí aláìlẹ́bi àti olódodo torí pé wọ́n nígbàgbọ́. Jèhófà pe Ábúráhámù, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ míì ní olódodo, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Àmọ́ torí pé wọ́n nígbàgbọ́, Ọlọ́run kà wọ́n sí aláìlẹ́bi pàápàá tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí ò mọ Ọlọ́run rárá. (Éfé. 2:12) Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ Ábúráhámù àti Dáfídì ṣe rí nìyẹn. Torí pé àwa náà nígbàgbọ́, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. w23.12 3 ¶6-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́