Tuesday, September 16
A ti gbà gbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.—Jòh. 6:69.
Àpọ́sítẹ́lì Pétérù jẹ́ olóòótọ́, kò sì jẹ́ kó sú òun láti máa tẹ̀ lé Jésù. Nígbà kan tí Jésù sọ ohun tí kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, Pétérù ṣe ohun tó fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́. (Jòh. 6:68) Dípò kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ní sùúrù, kí wọ́n sì gbọ́ àlàyé tí Jésù máa ṣe, ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára wọn fi Jésù sílẹ̀. Àmọ́ Pétérù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó mọ̀ pé Jésù ló ní “àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” Jésù mọ̀ pé Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù máa sá fi òun sílẹ̀. Síbẹ̀, Jésù sọ fún Pétérù pé ó máa pa dà, ó sì máa jẹ́ olóòótọ́. (Lúùkù 22:31, 32) Jésù mọ̀ dáadáa pé “ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.” (Máàkù 14:38) Kódà, lẹ́yìn tí Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rárá, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Pétérù dá wà. (Máàkù 16:7; Lúùkù 24:34; 1 Kọ́r. 15:5) Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa fún Pétérù lókun gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣàṣìṣe! w23.09 22 ¶9-10
Wednesday, September 17
Aláyọ̀ ni àwọn tí a dárí ìwà wọn tí kò bófin mu jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.—Róòmù 4:7.
Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ jì wọ́n. Ó máa ń dárí jì wọ́n pátápátá, kò sì ní ka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. (Sm. 32:1, 2) Jèhófà máa ń ka irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí aláìlẹ́bi àti olódodo torí pé wọ́n nígbàgbọ́. Jèhófà pe Ábúráhámù, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ míì ní olódodo, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Àmọ́ torí pé wọ́n nígbàgbọ́, Ọlọ́run kà wọ́n sí aláìlẹ́bi pàápàá tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí ò mọ Ọlọ́run rárá. (Éfé. 2:12) Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ Ábúráhámù àti Dáfídì ṣe rí nìyẹn. Torí pé àwa náà nígbàgbọ́, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. w23.12 3 ¶6-7
Thursday, September 18
Ẹ máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.—Héb. 13:15.
Gbogbo àwa Kristẹni lónìí láǹfààní láti rúbọ sí Jèhófà bá a ṣe ń lo àkókò wa, okun wa àti ohun ìní wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti jọ́sìn Jèhófà bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà. (Héb. 10:22-25) Àwọn nǹkan náà ni: Ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká máa wàásù fáwọn èèyàn, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa fún ara wa níṣìírí “ní pàtàkì jù lọ bí [a] ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” Nígbà tí ìwé Ìfihàn ń parí lọ, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ gbólóhùn yìí pé: “Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!” (Ìfi. 19:10; 22:9) Torí náà, ká má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tá a kọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, ká sì mọyì àǹfààní tá a ní láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa atóbilọ́lá! w23.10 29 ¶17-18