ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Wednesday, September 17

Aláyọ̀ ni àwọn tí a dárí ìwà wọn tí kò bófin mu jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.—Róòmù 4:7.

Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ jì wọ́n. Ó máa ń dárí jì wọ́n pátápátá, kò sì ní ka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. (Sm. 32:​1, 2) Jèhófà máa ń ka irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí aláìlẹ́bi àti olódodo torí pé wọ́n nígbàgbọ́. Jèhófà pe Ábúráhámù, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ míì ní olódodo, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Àmọ́ torí pé wọ́n nígbàgbọ́, Ọlọ́run kà wọ́n sí aláìlẹ́bi pàápàá tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí ò mọ Ọlọ́run rárá. (Éfé. 2:12) Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ Ábúráhámù àti Dáfídì ṣe rí nìyẹn. Torí pé àwa náà nígbàgbọ́, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. w23.12 3 ¶6-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Thursday, September 18

Ẹ máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.—Héb. 13:15.

Gbogbo àwa Kristẹni lónìí láǹfààní láti rúbọ sí Jèhófà bá a ṣe ń lo àkókò wa, okun wa àti ohun ìní wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti jọ́sìn Jèhófà bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà. (Héb. 10:​22-25) Àwọn nǹkan náà ni: Ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká máa wàásù fáwọn èèyàn, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa fún ara wa níṣìírí “ní pàtàkì jù lọ bí [a] ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” Nígbà tí ìwé Ìfihàn ń parí lọ, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ gbólóhùn yìí pé: “Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!” (Ìfi. 19:10; 22:9) Torí náà, ká má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tá a kọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, ká sì mọyì àǹfààní tá a ní láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa atóbilọ́lá! w23.10 29 ¶17-18

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, September 19

Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.—1 Jòh. 4:7.

Gbogbo wa ló wù pé “ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.” Àmọ́, ó yẹ ká rántí ìkìlọ̀ Jésù pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.” (Mát. 24:12) Jésù ò sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò ní fìfẹ́ hàn síra wọn mọ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má fìwà jọ àwọn èèyàn ayé tí wọn kì í fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí: Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará ò tíì tutù? Ọ̀nà kan tá a lè fi mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú ni pé ká wo ohun tá a máa ń ṣe tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀ láàárín wa. (2 Kọ́r. 8:8) Àpọ́sítélì Pétérù sọ ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká ṣe, ó ní: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín, torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pét. 4:8) Torí náà, ohun tá a bá ṣe nígbà táwọn ará bá ṣẹ̀ wá tàbí tá a bá rí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. w23.11 10 ¶12-13

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́