Thursday, September 18
Ẹ máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.—Héb. 13:15.
Gbogbo àwa Kristẹni lónìí láǹfààní láti rúbọ sí Jèhófà bá a ṣe ń lo àkókò wa, okun wa àti ohun ìní wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti jọ́sìn Jèhófà bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá ń jọ́sìn Jèhófà. (Héb. 10:22-25) Àwọn nǹkan náà ni: Ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká máa wàásù fáwọn èèyàn, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa fún ara wa níṣìírí “ní pàtàkì jù lọ bí [a] ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” Nígbà tí ìwé Ìfihàn ń parí lọ, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ gbólóhùn yìí pé: “Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!” (Ìfi. 19:10; 22:9) Torí náà, ká má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tá a kọ́ nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, ká sì mọyì àǹfààní tá a ní láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa atóbilọ́lá! w23.10 29 ¶17-18
Friday, September 19
Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.—1 Jòh. 4:7.
Gbogbo wa ló wù pé “ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.” Àmọ́, ó yẹ ká rántí ìkìlọ̀ Jésù pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.” (Mát. 24:12) Jésù ò sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò ní fìfẹ́ hàn síra wọn mọ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má fìwà jọ àwọn èèyàn ayé tí wọn kì í fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí: Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará ò tíì tutù? Ọ̀nà kan tá a lè fi mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú ni pé ká wo ohun tá a máa ń ṣe tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀ láàárín wa. (2 Kọ́r. 8:8) Àpọ́sítélì Pétérù sọ ọ̀kan lára ohun tó yẹ ká ṣe, ó ní: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín, torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pét. 4:8) Torí náà, ohun tá a bá ṣe nígbà táwọn ará bá ṣẹ̀ wá tàbí tá a bá rí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. w23.11 10 ¶12-13
Saturday, September 20
Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín.—Jòh. 13:34.
Kò sí bá a ṣe lè sọ pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa tó bá jẹ́ pé àwọn kan là ń fìfẹ́ hàn sí nínú ìjọ, tá a sì ń pa àwọn yòókù tì. Lóòótọ́, a lè sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ bíi ti Jésù. (Jòh. 13:23; 20:2) Àmọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pétérù gbà wá níyànjú ni pé ká ní “ìfẹ́ ará” sí gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ìyẹn irú ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín àwọn ọmọ ìyá. (1 Pét. 2:17) Pétérù rọ̀ wá pé ká “ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara [wa] látọkàn wá.” (1 Pét. 1:22) Nínú ẹsẹ yìí, ‘ìfẹ́ tó tọkàn wá’ ni pé ká fìfẹ́ hàn sẹ́nì kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kí la máa ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ wá tàbí tó ṣe ohun tó dùn wá gan-an? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó máa kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn ni bá a ṣe máa gbẹ̀san dípò ká fìfẹ́ hàn sí i. Àmọ́ ohun tí Jésù kọ́ Pétérù ni pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn tó bá ń gbẹ̀san. (Jòh. 18:10, 11) Pétérù sọ pé: “Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.” (1 Pét. 3:9) Torí náà, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tó tọkàn wá mú ká máa finúure hàn sáwọn ará, ká sì máa gba tiwọn rò. w23.09 28-29 ¶9-11