Saturday, September 20
Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín.—Jòh. 13:34.
Kò sí bá a ṣe lè sọ pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa tó bá jẹ́ pé àwọn kan là ń fìfẹ́ hàn sí nínú ìjọ, tá a sì ń pa àwọn yòókù tì. Lóòótọ́, a lè sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ bíi ti Jésù. (Jòh. 13:23; 20:2) Àmọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pétérù gbà wá níyànjú ni pé ká ní “ìfẹ́ ará” sí gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ìyẹn irú ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín àwọn ọmọ ìyá. (1 Pét. 2:17) Pétérù rọ̀ wá pé ká “ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara [wa] látọkàn wá.” (1 Pét. 1:22) Nínú ẹsẹ yìí, ‘ìfẹ́ tó tọkàn wá’ ni pé ká fìfẹ́ hàn sẹ́nì kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kí la máa ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ wá tàbí tó ṣe ohun tó dùn wá gan-an? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó máa kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn ni bá a ṣe máa gbẹ̀san dípò ká fìfẹ́ hàn sí i. Àmọ́ ohun tí Jésù kọ́ Pétérù ni pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn tó bá ń gbẹ̀san. (Jòh. 18:10, 11) Pétérù sọ pé: “Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.” (1 Pét. 3:9) Torí náà, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tó tọkàn wá mú ká máa finúure hàn sáwọn ará, ká sì máa gba tiwọn rò. w23.09 28-29 ¶9-11
Sunday, September 21
Kí àwọn obìnrin . . . má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.—1 Tím. 3:11.
Ó máa ń yà wá lẹ́nu gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ọmọdé ń yára dàgbà. Ńṣe làwọn àyípadà yẹn máa ń ṣàdédé wáyé bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni ò rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa. (1 Kọ́r. 13:11; Héb. 6:1) Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. A tún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, ká kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe wá láǹfààní, ká sì múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tá a máa ní lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 1:5) Nígbà tí Jèhófà dá àwa èèyàn, akọ àti abo ló dá wa. (Jẹ́n. 1:27) Ó hàn gbangba pé ìrísí ọkùnrin yàtọ̀ sí ti obìnrin, àmọ́ wọ́n tún yàtọ̀ síra láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe kan, torí náà ó yẹ kí wọ́n láwọn ànímọ́ tó dáa, kí wọ́n sì kọ́ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe náà.—Jẹ́n. 2:18. w23.12 18 ¶1-2
Monday, September 22
Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ.—Mát. 28:19.
Ṣé Jésù fẹ́ káwọn èèyàn máa lo orúkọ Bàbá ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn olórí ẹ̀sìn tó ka ara wọn sí olódodo sọ pé orúkọ Ọlọ́run mọ́ ju kéèyàn máa pè é lọ, àmọ́ Jésù ò jẹ́ kí àṣà tí Ìwé Mímọ́ ò fọwọ́ sí yẹn dí òun lọ́wọ́ láti bọlá fún orúkọ Bàbá òun. Ẹ jẹ́ ká wo ìgbà kan tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin kan ní agbègbè àwọn ará Gérásà. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà gan-an, torí náà wọ́n sọ pé kí Jésù máa lọ, ó sì kúrò níbẹ̀. (Máàkù 5:16, 17) Síbẹ̀, Jésù fẹ́ káwọn èèyàn tó wà lágbègbè yẹn mọ orúkọ Jèhófà. Torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé kó sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ló wo òun sàn. (Máàkù 5:19) Ohun tó fẹ́ káwa náà ṣe lónìí nìyẹn, ó fẹ́ ká sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ fún gbogbo èèyàn! (Mát. 24:14; 28:20) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa múnú Jésù Ọba wa dùn. w24.02 10 ¶10