ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Sunday, September 21

Kí àwọn obìnrin . . . má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.—1 Tím. 3:11.

Ó máa ń yà wá lẹ́nu gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ọmọdé ń yára dàgbà. Ńṣe làwọn àyípadà yẹn máa ń ṣàdédé wáyé bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni ò rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa. (1 Kọ́r. 13:11; Héb. 6:1) Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. A tún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, ká kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe wá láǹfààní, ká sì múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tá a máa ní lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 1:5) Nígbà tí Jèhófà dá àwa èèyàn, akọ àti abo ló dá wa. (Jẹ́n. 1:27) Ó hàn gbangba pé ìrísí ọkùnrin yàtọ̀ sí ti obìnrin, àmọ́ wọ́n tún yàtọ̀ síra láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe kan, torí náà ó yẹ kí wọ́n láwọn ànímọ́ tó dáa, kí wọ́n sì kọ́ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe náà.—Jẹ́n. 2:18. w23.12 18 ¶1-2

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, September 22

Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ.—Mát. 28:19.

Ṣé Jésù fẹ́ káwọn èèyàn máa lo orúkọ Bàbá ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn olórí ẹ̀sìn tó ka ara wọn sí olódodo sọ pé orúkọ Ọlọ́run mọ́ ju kéèyàn máa pè é lọ, àmọ́ Jésù ò jẹ́ kí àṣà tí Ìwé Mímọ́ ò fọwọ́ sí yẹn dí òun lọ́wọ́ láti bọlá fún orúkọ Bàbá òun. Ẹ jẹ́ ká wo ìgbà kan tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin kan ní agbègbè àwọn ará Gérásà. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà gan-an, torí náà wọ́n sọ pé kí Jésù máa lọ, ó sì kúrò níbẹ̀. (Máàkù 5:​16, 17) Síbẹ̀, Jésù fẹ́ káwọn èèyàn tó wà lágbègbè yẹn mọ orúkọ Jèhófà. Torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé kó sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ló wo òun sàn. (Máàkù 5:19) Ohun tó fẹ́ káwa náà ṣe lónìí nìyẹn, ó fẹ́ ká sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ fún gbogbo èèyàn! (Mát. 24:14; 28:20) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa múnú Jésù Ọba wa dùn. w24.02 10 ¶10

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, September 23

O ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra nítorí orúkọ mi.—Ìfi. 2:3.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn tó ń sin Jèhófà nínú ètò ẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé, Jèhófà fi àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a jọ wà níṣọ̀kan kẹ́ wa. (Sm. 133:1) Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìdílé aláyọ̀. (Éfé. 5:33–6:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó ń fún wa ní ọgbọ́n àti òye tí àá fi máa fara da àwọn ìṣòro wa kọ́kàn wa lè balẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe ohun tó dùn wá. Ó tún lè nira fún wa láti fara da àwọn àṣìṣe wa, pàápàá tó bá jẹ́ pé léraléra là ń ṣe àwọn àṣìṣe náà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa sin Jèhófà nìṣó (1) táwọn ará bá ṣẹ̀ wá, (2) tí ọkọ tàbí aya wa bá já wa kulẹ̀ àti (3) tá a bá rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn àṣìṣe wa. w24.03 14 ¶1-2

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́