Monday, September 22
Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ.—Mát. 28:19.
Ṣé Jésù fẹ́ káwọn èèyàn máa lo orúkọ Bàbá ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn olórí ẹ̀sìn tó ka ara wọn sí olódodo sọ pé orúkọ Ọlọ́run mọ́ ju kéèyàn máa pè é lọ, àmọ́ Jésù ò jẹ́ kí àṣà tí Ìwé Mímọ́ ò fọwọ́ sí yẹn dí òun lọ́wọ́ láti bọlá fún orúkọ Bàbá òun. Ẹ jẹ́ ká wo ìgbà kan tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọkùnrin kan ní agbègbè àwọn ará Gérásà. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà gan-an, torí náà wọ́n sọ pé kí Jésù máa lọ, ó sì kúrò níbẹ̀. (Máàkù 5:16, 17) Síbẹ̀, Jésù fẹ́ káwọn èèyàn tó wà lágbègbè yẹn mọ orúkọ Jèhófà. Torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé kó sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ló wo òun sàn. (Máàkù 5:19) Ohun tó fẹ́ káwa náà ṣe lónìí nìyẹn, ó fẹ́ ká sọ orúkọ Bàbá ẹ̀ fún gbogbo èèyàn! (Mát. 24:14; 28:20) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa múnú Jésù Ọba wa dùn. w24.02 10 ¶10
Tuesday, September 23
O ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra nítorí orúkọ mi.—Ìfi. 2:3.
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn tó ń sin Jèhófà nínú ètò ẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé, Jèhófà fi àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a jọ wà níṣọ̀kan kẹ́ wa. (Sm. 133:1) Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìdílé aláyọ̀. (Éfé. 5:33–6:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó ń fún wa ní ọgbọ́n àti òye tí àá fi máa fara da àwọn ìṣòro wa kọ́kàn wa lè balẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe ohun tó dùn wá. Ó tún lè nira fún wa láti fara da àwọn àṣìṣe wa, pàápàá tó bá jẹ́ pé léraléra là ń ṣe àwọn àṣìṣe náà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa sin Jèhófà nìṣó (1) táwọn ará bá ṣẹ̀ wá, (2) tí ọkọ tàbí aya wa bá já wa kulẹ̀ àti (3) tá a bá rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn àṣìṣe wa. w24.03 14 ¶1-2
Wednesday, September 24
Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.—Fílí. 3:16.
Látìgbàdégbà, wàá máa gbọ́ ìrírí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tàbí kí wọ́n kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Tí ipò ẹ bá gbà ẹ́ láyè, irú àwọn nǹkan tó yẹ kíwọ náà fi ṣe àfojúsùn ẹ nìyẹn. Ìdí sì ni pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. (Ìṣe 16:9) Àmọ́ ká sọ pé o ò tíì lè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí ńkọ́? Má ṣe rò pé o ò dáa tó àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa fi ìfaradà sá eré ìje náà nìṣó. (Mát. 10:22) Má gbàgbé pé ohun tó máa múnú Jèhófà dùn ni pé kó o máa ṣe nǹkan tágbára ẹ gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tó o lè ṣe láti máa tẹ̀ lé Jésù nìyẹn lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.—Sm. 26:1. w24.03 10 ¶11