ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Tuesday, September 23

O ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra nítorí orúkọ mi.—Ìfi. 2:3.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn tó ń sin Jèhófà nínú ètò ẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé, Jèhófà fi àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a jọ wà níṣọ̀kan kẹ́ wa. (Sm. 133:1) Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìdílé aláyọ̀. (Éfé. 5:33–6:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó ń fún wa ní ọgbọ́n àti òye tí àá fi máa fara da àwọn ìṣòro wa kọ́kàn wa lè balẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà nìṣó. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe ohun tó dùn wá. Ó tún lè nira fún wa láti fara da àwọn àṣìṣe wa, pàápàá tó bá jẹ́ pé léraléra là ń ṣe àwọn àṣìṣe náà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa sin Jèhófà nìṣó (1) táwọn ará bá ṣẹ̀ wá, (2) tí ọkọ tàbí aya wa bá já wa kulẹ̀ àti (3) tá a bá rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn àṣìṣe wa. w24.03 14 ¶1-2

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Wednesday, September 24

Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.—Fílí. 3:16.

Látìgbàdégbà, wàá máa gbọ́ ìrírí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tàbí kí wọ́n kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Tí ipò ẹ bá gbà ẹ́ láyè, irú àwọn nǹkan tó yẹ kíwọ náà fi ṣe àfojúsùn ẹ nìyẹn. Ìdí sì ni pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. (Ìṣe 16:9) Àmọ́ ká sọ pé o ò tíì lè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí ńkọ́? Má ṣe rò pé o ò dáa tó àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa fi ìfaradà sá eré ìje náà nìṣó. (Mát. 10:22) Má gbàgbé pé ohun tó máa múnú Jèhófà dùn ni pé kó o máa ṣe nǹkan tágbára ẹ gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tó o lè ṣe láti máa tẹ̀ lé Jésù nìyẹn lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.—Sm. 26:1. w24.03 10 ¶11

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Thursday, September 25

Ó dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá tinútinú.—Kól. 2:13.

Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ṣèlérí pé òun máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà. (Sm. 86:5) Torí náà, tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá, ó yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ pé òun ti dárí jì wá. Máa rántí pé Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Kì í retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. Ó mọyì ohunkóhun tá a bá ṣe, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé gbogbo ohun tágbára wa gbé là ń ṣe. Bákan náà, a tún lè ronú nípa àwọn tó sin Jèhófà tọkàntọkàn nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó rin ìrìn ọ̀pọ̀ máìlì, ó sì dá ìjọ tó pọ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé inú Jèhófà ò dùn sí i mọ́? Rárá o. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, Jèhófà sì bù kún un. (Ìṣe 28:​30, 31) Lọ́nà kan náà, àwọn ìgbà míì wà tá a lè má lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lójú Jèhófà ni ìdí tá a fi ń ṣe é. w24.03 27 ¶7, 9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́