ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Sunday, September 28

Àwọn ọ̀tá mi á sá pa dà ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ó dá mi lójú pé: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.—Sm. 56:9.

Ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí sọ nǹkan tí Dáfídì ṣe láti borí ẹ̀rù tó ń bà á. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ẹ̀ fẹ́ pa á, ó ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún òun lọ́jọ́ iwájú. Dáfídì mọ̀ pé àsìkò tó tọ́ ni Jèhófà máa gba òun sílẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà ti sọ pé Dáfídì ló máa jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 16:​1, 13) Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ohun tí Jèhófà ṣèlérí máa ṣẹ. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún ẹ? A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá pé kí ìṣòro má dé bá wa. Síbẹ̀, ìṣòro yòówù kó dé bá wa nísinsìnyí, Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀ kúrò nínú ayé tuntun. (Àìsá. 25:​7-9) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti jí àwọn òkú dìde, láti wò wá sàn, kó sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá wa run.—1 Jòh. 4:4. w24.01 5-6 ¶12-13

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, September 29

Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí àṣìṣe rẹ̀ jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.—Sm. 32:1.

Máa ronú nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó o ṣe. Ìdí tó o fi ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi ni pé Jèhófà ló wù ẹ́ pé kó o máa ṣègbọràn sí. Máa rántí àwọn nǹkan tó jẹ́ kó o gbà pé o ti rí òtítọ́. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́ ló jẹ́ kó o mọ Jèhófà Bàbá rẹ ọ̀run, ó ti jẹ́ kó o máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ẹ̀kọ́ tó o kọ́ tún jẹ́ kó o nígbàgbọ́, kó o sì ronú pìwà dà. O ti fi àwọn ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí sílẹ̀, o sì ń ṣe ohun tó fẹ́. Ara tù ẹ́ nígbà tó o mọ̀ pé Ọlọ́run ti dárí jì ẹ́. (Sm. 32:2) O bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ìjọ, o sì ń sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó o ti kọ́ fáwọn èèyàn. Ní báyìí tó o ti ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ti ṣèrìbọmi, o ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ọ̀nà ìyè, o sì ti pinnu pé o ò ní kúrò níbẹ̀. (Mát. 7:​13, 14) Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o dúró gbọn-in, kó o máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, kó o sì máa pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́. w23.07 17 ¶14; 19 ¶19

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, September 30

Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.—1 Kọ́r. 10:13.

Tó o bá ń ronú lórí àdúrà tó o gbà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, wàá nígboyà láti borí ìdẹwò èyíkéyìí. Bí àpẹẹrẹ, ṣé wàá tage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ìdí ni pé o ti pinnu tẹ́lẹ̀ pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Tí o ò bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbilẹ̀ lọ́kàn ẹ, kò ní sídìí fún ẹ láti máa wá bó o ṣe máa gbé e kúrò lọ́kàn tó bá yá. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní “gba ọ̀nà àwọn ẹni burúkú.” (Òwe 4:​14, 15) Tó o bá rántí bí Jésù ṣe pinnu pé òun máa múnú Bàbá òun dùn, kíákíá lo máa kọ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá sì pinnu pé o ò ní ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún. (Mát. 4:10; Jòh. 8:29) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìṣòro àti ìdẹwò máa fún ẹ láǹfààní láti fi hàn pé o ti pinnu láti máa tẹ̀ lé Jésù. Tó o bá pinnu láti máa tẹ̀ lé Jésù, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. w24.03 9-10 ¶8-10

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́