ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Saturday, September 27

A ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, èyí tí a fún wa.—Róòmù 5:5.

Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà, ‘tú jáde’ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé a tún lè pe ọ̀rọ̀ yìí ní “dà jáde sórí wa bí omi.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tá a fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn ẹni àmì òróró yìí bá a mu gan-an! Ó dá àwọn ẹni àmì òróró lójú pé ‘Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́’ àwọn. (Júùdù 1) Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ní: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ní sí wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run!” (1 Jòh. 3:1) Àmọ́, ṣé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́? Rárá o, Jèhófà ti fi hàn pé gbogbo wa lòun nífẹ̀ẹ́. Kí lohun tó ga jù lọ tí Jèhófà ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa? Ìràpadà ni. Kò tíì sẹ́ni tó fi irú ìfẹ́ yìí hàn láyé àtọ̀run!—Jòh. 3:16; Róòmù 5:8. w24.01 28 ¶9-10

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Sunday, September 28

Àwọn ọ̀tá mi á sá pa dà ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ó dá mi lójú pé: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.—Sm. 56:9.

Ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí sọ nǹkan tí Dáfídì ṣe láti borí ẹ̀rù tó ń bà á. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ẹ̀ fẹ́ pa á, ó ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún òun lọ́jọ́ iwájú. Dáfídì mọ̀ pé àsìkò tó tọ́ ni Jèhófà máa gba òun sílẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà ti sọ pé Dáfídì ló máa jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 16:​1, 13) Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ohun tí Jèhófà ṣèlérí máa ṣẹ. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún ẹ? A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá pé kí ìṣòro má dé bá wa. Síbẹ̀, ìṣòro yòówù kó dé bá wa nísinsìnyí, Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀ kúrò nínú ayé tuntun. (Àìsá. 25:​7-9) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti jí àwọn òkú dìde, láti wò wá sàn, kó sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá wa run.—1 Jòh. 4:4. w24.01 5-6 ¶12-13

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, September 29

Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí àṣìṣe rẹ̀ jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.—Sm. 32:1.

Máa ronú nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó o ṣe. Ìdí tó o fi ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi ni pé Jèhófà ló wù ẹ́ pé kó o máa ṣègbọràn sí. Máa rántí àwọn nǹkan tó jẹ́ kó o gbà pé o ti rí òtítọ́. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́ ló jẹ́ kó o mọ Jèhófà Bàbá rẹ ọ̀run, ó ti jẹ́ kó o máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ẹ̀kọ́ tó o kọ́ tún jẹ́ kó o nígbàgbọ́, kó o sì ronú pìwà dà. O ti fi àwọn ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí sílẹ̀, o sì ń ṣe ohun tó fẹ́. Ara tù ẹ́ nígbà tó o mọ̀ pé Ọlọ́run ti dárí jì ẹ́. (Sm. 32:2) O bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ìjọ, o sì ń sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó o ti kọ́ fáwọn èèyàn. Ní báyìí tó o ti ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ti ṣèrìbọmi, o ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ọ̀nà ìyè, o sì ti pinnu pé o ò ní kúrò níbẹ̀. (Mát. 7:​13, 14) Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o dúró gbọn-in, kó o máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, kó o sì máa pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́. w23.07 17 ¶14; 19 ¶19

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́