Friday, September 26
Ní àárọ̀ kùtù, tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, [Jésù] dìde, ó jáde lọ síbi tó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbẹ̀.—Máàkù 1:35.
Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà tó gbàdúrà sí Jèhófà. Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń gbàdúrà. Ńṣe ni Jésù máa ń wáyè gbàdúrà torí pé ọwọ́ ẹ̀ máa ń dí gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń wà lọ́dọ̀ ẹ̀. (Máàkù 6:31, 45, 46) Ó máa ń jí láàárọ̀ kùtù láti lọ dá gbàdúrà. Kódà, ìgbà kan wà tó fi gbogbo òru gbàdúrà nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. (Lúùkù 6:12, 13) Yàtọ̀ síyẹn, ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, léraléra ló gbàdúrà sí Jèhófà bó ṣe ń ronú nípa bó ṣe máa parí èyí tó le jù lára iṣẹ́ tó wá ṣe láyé. (Mát. 26:39, 42, 44) Àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa pé bó ti wù kí ọwọ́ wa dí tó, ó yẹ ká máa wáyè gbàdúrà. Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà ya àkókò sọ́tọ̀ láti máa gbàdúrà, ó sì lè gba pé ká tètè jí láàárọ̀ tàbí ká gbàdúrà ká tó lọ sùn lálẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti gbàdúrà. w23.05 3 ¶4-5
Saturday, September 27
A ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, èyí tí a fún wa.—Róòmù 5:5.
Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà, ‘tú jáde’ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé a tún lè pe ọ̀rọ̀ yìí ní “dà jáde sórí wa bí omi.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tá a fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn ẹni àmì òróró yìí bá a mu gan-an! Ó dá àwọn ẹni àmì òróró lójú pé ‘Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́’ àwọn. (Júùdù 1) Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ní: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ní sí wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run!” (1 Jòh. 3:1) Àmọ́, ṣé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́? Rárá o, Jèhófà ti fi hàn pé gbogbo wa lòun nífẹ̀ẹ́. Kí lohun tó ga jù lọ tí Jèhófà ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa? Ìràpadà ni. Kò tíì sẹ́ni tó fi irú ìfẹ́ yìí hàn láyé àtọ̀run!—Jòh. 3:16; Róòmù 5:8. w24.01 28 ¶9-10
Sunday, September 28
Àwọn ọ̀tá mi á sá pa dà ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ó dá mi lójú pé: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.—Sm. 56:9.
Ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí sọ nǹkan tí Dáfídì ṣe láti borí ẹ̀rù tó ń bà á. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ẹ̀ fẹ́ pa á, ó ronú nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún òun lọ́jọ́ iwájú. Dáfídì mọ̀ pé àsìkò tó tọ́ ni Jèhófà máa gba òun sílẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà ti sọ pé Dáfídì ló máa jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 16:1, 13) Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ohun tí Jèhófà ṣèlérí máa ṣẹ. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún ẹ? A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá pé kí ìṣòro má dé bá wa. Síbẹ̀, ìṣòro yòówù kó dé bá wa nísinsìnyí, Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀ kúrò nínú ayé tuntun. (Àìsá. 25:7-9) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa lágbára láti jí àwọn òkú dìde, láti wò wá sàn, kó sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá wa run.—1 Jòh. 4:4. w24.01 5-6 ¶12-13