Thursday, September 25
Ó dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá tinútinú.—Kól. 2:13.
Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ṣèlérí pé òun máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà. (Sm. 86:5) Torí náà, tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá, ó yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ pé òun ti dárí jì wá. Máa rántí pé Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Kì í retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. Ó mọyì ohunkóhun tá a bá ṣe, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé gbogbo ohun tágbára wa gbé là ń ṣe. Bákan náà, a tún lè ronú nípa àwọn tó sin Jèhófà tọkàntọkàn nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó rin ìrìn ọ̀pọ̀ máìlì, ó sì dá ìjọ tó pọ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé inú Jèhófà ò dùn sí i mọ́? Rárá o. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, Jèhófà sì bù kún un. (Ìṣe 28:30, 31) Lọ́nà kan náà, àwọn ìgbà míì wà tá a lè má lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lójú Jèhófà ni ìdí tá a fi ń ṣe é. w24.03 27 ¶7, 9
Friday, September 26
Ní àárọ̀ kùtù, tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, [Jésù] dìde, ó jáde lọ síbi tó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbẹ̀.—Máàkù 1:35.
Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà tó gbàdúrà sí Jèhófà. Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń gbàdúrà. Ńṣe ni Jésù máa ń wáyè gbàdúrà torí pé ọwọ́ ẹ̀ máa ń dí gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń wà lọ́dọ̀ ẹ̀. (Máàkù 6:31, 45, 46) Ó máa ń jí láàárọ̀ kùtù láti lọ dá gbàdúrà. Kódà, ìgbà kan wà tó fi gbogbo òru gbàdúrà nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. (Lúùkù 6:12, 13) Yàtọ̀ síyẹn, ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, léraléra ló gbàdúrà sí Jèhófà bó ṣe ń ronú nípa bó ṣe máa parí èyí tó le jù lára iṣẹ́ tó wá ṣe láyé. (Mát. 26:39, 42, 44) Àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa pé bó ti wù kí ọwọ́ wa dí tó, ó yẹ ká máa wáyè gbàdúrà. Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà ya àkókò sọ́tọ̀ láti máa gbàdúrà, ó sì lè gba pé ká tètè jí láàárọ̀ tàbí ká gbàdúrà ká tó lọ sùn lálẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti gbàdúrà. w23.05 3 ¶4-5
Saturday, September 27
A ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, èyí tí a fún wa.—Róòmù 5:5.
Kíyè sí ọ̀rọ̀ náà, ‘tú jáde’ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé a tún lè pe ọ̀rọ̀ yìí ní “dà jáde sórí wa bí omi.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tá a fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn ẹni àmì òróró yìí bá a mu gan-an! Ó dá àwọn ẹni àmì òróró lójú pé ‘Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́’ àwọn. (Júùdù 1) Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ní: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ní sí wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run!” (1 Jòh. 3:1) Àmọ́, ṣé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́? Rárá o, Jèhófà ti fi hàn pé gbogbo wa lòun nífẹ̀ẹ́. Kí lohun tó ga jù lọ tí Jèhófà ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa? Ìràpadà ni. Kò tíì sẹ́ni tó fi irú ìfẹ́ yìí hàn láyé àtọ̀run!—Jòh. 3:16; Róòmù 5:8. w24.01 28 ¶9-10