ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọ̀sẹ̀ Yìí
August 25-31
Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́—2025 | July

AUGUST 25-31

ÒWE 28

Orin 150 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ẹni Burúkú àti Olódodo

(10 min.)

Ẹ̀rù máa ń ba ẹni burúkú àmọ́ olódodo máa ń láyà (Owe 28:1; w93 5/15 26 ¶1)

Ẹni burúkú ò lè ṣèpinnu tó tọ́, àmọ́ olódodo máa ń ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání (Owe 28:5; it-2 1139 ¶3)

Tí ẹni burúkú bá tiẹ̀ lówó, olódodo tó tálákà ṣeyebíye jù ú lọ (Owe 28:6; it-1 1211 ¶4)

Arákùnrin kan gbójú sókè bó ṣe ń gbàdúrà nínú ẹ̀wọ̀n tó wà, ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 28:14—Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (w01 12/1 12 ¶1)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 28:1-17 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)

6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

7. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé ogun àti ìwà ipá máa dópin. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 112

8. Ṣé O Kórìíra Ìwà Ipá?

(6 min.) Ìjíròrò.

Ọmọkùnrin kan ń gbádùn géèmù tó ń gbá lórí kọ̀ǹpútà.

Ọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù tí Jésù pè ní “apààyàn” ni ìwà ipá ti bẹ̀rẹ̀. (Jo 8:44) Lẹ́yìn táwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀, ìwà ipá wá pọ̀ láyé débi tí Ọlọ́run fi sọ pé ayé ti bà jẹ́. (Jẹ 6:11) Bí ayé tó kún fún ìwà ipá yìí ṣe ń lọ sópin, ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn ń hùwà tó burú gan-an, tí wọn ò sì lè kó ara wọn níjàánu.—2Ti 3:1, 3.

Ka Sáàmù 11:5. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó fẹ́ràn ìwà ipá, kí sì nìdí?

  • Kí la kíyè sí nípa ọ̀pọ̀ eré ìdárayá àti eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe lónìí tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn fẹ́ràn ìwà ipá?

Ka Òwe 22:24, 25. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni irú eré ìnàjú tá à ń wò àtàwọn tá à ń bá ṣọ̀rẹ́ ṣe lè mú ká kórìíra tàbí nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá?

  • Báwo ni eré ìnàjú tá à ń wò ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá?

9. Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù September

(9 min.)

Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ̀rọ̀ lọ́nà táá jẹ́ kó wu àwọn ará láti kópa nínú àkànṣe ìwàásù náà, kó o sì sọ ètò tí ìjọ ti ṣe.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Àlàáfíà Ayérayé! (Orin Àpéjọ Agbègbè 2022).

10. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 12-13

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 113 àti Àdúrà

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025 | June

Àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ 25: August 25-31, 2025

8 Ohun Tá A Kọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Jékọ́bù Sọ Nígbà Tó Fẹ́ Kú—Apá Kejì

Àfikún

Àwọn àpilẹ̀kọ míì tó wà nínú ìwé yìí

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́