ORIN 7
Jèhófà Ni Agbára Wa
1. Okun wa, agbára wa, ààbò wa;
Jèhófà, ayọ̀ wa, ìgbàlà wa.
A ó fayọ̀ sọ nípa rẹ fáráyé,
Bóyá wọ́n fẹ́ gbọ́ tàbí wọn kò fẹ́.
(ÈGBÈ)
Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa,
A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ.
Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù,
Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù.
2. Ẹlẹ́rìí rẹ tá a jẹ́ ńmú ká láyọ̀.
A mọ òtítọ́ àtohun tó tọ́.
Àṣẹ rẹ tó wà nínú Bíbélì
Mú ká lè kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ.
(ÈGBÈ)
Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa,
A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ.
Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù,
Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù.
3. Bí Èṣù ń gàn wá, a kò ní bẹ̀rù
Títí láé la ó máa fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ.
Bí Sátánì bá tiẹ̀ fẹ́ gbẹ̀mí wa,
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.
(ÈGBÈ)
Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa,
A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ.
Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù,
Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù.
(Tún wo 2 Sám. 22:3; Sm. 18:2; Àìsá. 43:12.)