Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Singapore Àpilẹ̀kọ náà, “Singapore—Ọ̀ṣọ́ Iyebíye Ilẹ̀ Éṣíà Tí Wọ́n Bà Jẹ́” (June 8, 1997), tú àṣírí bí ìjọba òde òní yìí ṣe ń hùwà sí àwọn Kristẹni olùfẹ́ àlàáfíà. Èmi bí ẹnì kan mọ ọ̀pọ̀ Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin níbẹ̀, gbogbo wọn sì jẹ́ ènìyàn rere, onífẹ̀ẹ́. Ó ń fún mi níṣìírí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà láìka inúnibíni sí.
I. O., Malaysia
Ìbínú Nínú àpilẹ̀kọ náà, “Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí O Ṣàkóso Ìbínú Rẹ?” (June 8, 1997), ẹ sọ pé baba Síméónì àti Léfì fi wọ́n bú. Ó dá mi lójú pé mo ti kà á níbì kan pé ìbínú wọn ni Jékọ́bù fi bú.
S. L., United States
Òǹkàwé wa tọ̀nà lórí kókó yìí. “Ile-Iṣọ Na” ti November 1, 1963, ṣàlàyé pé: “Jakobu ko fi Simeoni ati Lefi gegun ni awọn ti kalawọn. O fi ‘ìbinu wọn gegun nitori ti o roro.’ O fi ikannu wọn gegun ‘nitori ti o ni ika.’”—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Oúnjẹ Àpilẹ̀kọ náà, “Oúnjẹ Rẹ—Ó Ha Lè Pa Ọ́ Bí?” (June 22, 1997), gbà mí là. Lẹ́yìn tí mo kà á, mo sọ fún ìyàwó mi pé kí ó tẹ dókítà láago lọ́gán, nítorí pé àpilẹ̀kọ náà ṣàpèjúwe ipò mi gẹ́lẹ́. Lẹ́yìn tí dókítà yẹ̀ mí wò, ó ṣètò pé kí n ṣe iṣẹ́ abẹ lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì. Ó gbà mí sílé ìwòsàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á pé mo lè kú kílẹ̀ tó mọ́. Mo ti padà sílé báyìí, mo sì ń kọ́fẹ padà lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ti lo òpójẹ̀ àtọwọ́dá mẹta.
F. S., United States
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èmi àti ọkọ mi kì í lè kó ara wa níjàánu nídìí oúnjẹ. Mo ti ka àwọn àpilẹ̀kọ mìíràn nípa oúnjẹ, ṣùgbọ́n èyí jíròrò àwọn nǹkan lọ́nà rírọrùn tó sì gbéṣẹ́. Ó dá mi lójú pé nípa lílo àwọn àbá tí ẹ dá, yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa ní ìlera nìṣó.
V. A., Brazil
Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Oúnjẹ Rẹ—Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí O Ṣàníyàn.” Ó ràn mí lọ́wọ́ láti rí ewu tó wà nínú sísanrajù. Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé gbogbo àbá tó wà níbẹ̀, mo sì mọ̀ pé, pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, n óò lè ṣàkóso bí mo ṣe ń jẹun.
V. Y. D., Liberia
Àwọn Lámilámi Ẹ ṣeun púpọ̀ fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ohun Iyebíye Etídò” (June 22, 1997), tó gbádùn mọ́ni gan-an. Ó sọ nípa ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá tí ń fò, tí mo fẹ́ràn jù, lámilámi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà mi ni lámilámi kan ń fò lókè tàbí tí ó ń sinmi nítòsí. Mo béèrè ìdí tí ó fi ń rí bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan tí ń ṣiṣẹ́ àbójútó ìrísí ojú ilẹ̀. Ó sọ pé yànmùyánmú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ lámilámi, àti pé àwọn yànmùyánmú máa ń wà níbi tí ènìyàn bá wà. Nítorí náà, ní báyìí, mo ń wo ẹ̀dá rírẹwà yìí bí ẹ̀ṣọ́ ara ẹni kan!
J. F., United States
Wíwá Àìṣègbè Mo gbádùn àpilẹ̀kọ náà, “Wíwá Tí A Wá Àìṣègbè Kiri.” (June 22, 1997) Dájúdájú, àwọn ànímọ́ òdodo Ọlọ́run ń fa àwọn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń sunkún nítorí ìṣègbè, mọ́ra. Ìṣègbè máa ń bí mi nínú ní pàtàkì, mo sì ní láti sapá gidigidi láti tún èrò mi àti ìwà mi ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run.
D. L., Taiwan
N kò fara mọ́ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ẹ lò. Nígbà tí ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Texas tí ń jà fún Alamo, ẹ kò sọ pé wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí tí ń sapá láti já àgbègbè ilẹ̀ tó jẹ́ ti Mexico gbà.
A. C., Mexico
A kò jíròrò àwọn ọ̀ràn dídíjú tó wé mọ́ ìjà Alamo, nítorí kò jọ pé wọ́n tan mọ́ ìtàn ìgbésí ayé Antonio Villa. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtẹ̀jáde “Jí!” wa, ti May 22, 1971, [Gẹ̀ẹ́sì], sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Amẹ́ríkà ló gbàgbé, tàbí ni kò tilẹ̀ mọ̀, pé San Antonio ti jẹ́ apá kan Mexico rí. Mexico ka ogun náà sí títẹ-ọ̀tẹ̀-rì ní àgbègbè ilẹ̀ rẹ̀. Amẹ́ríkà lò ó . . . láti fi dá bí ó ṣe ń dá sí àwọn àlámọ̀rí Mexico láre.”—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.