ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/1 ojú ìwé 3-4
  • Ìsìn ha ń kúnjú àwọn àìní rẹ bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìsìn ha ń kúnjú àwọn àìní rẹ bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—2004
  • Bawo ni Jesu Kristi Ṣe Jẹ́ Wolii kan bii Mose?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Bí O Ṣe Ń Jọ́sìn Ha Ṣe Pàtàkì Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/1 ojú ìwé 3-4

Ìsìn ha ń kúnjú àwọn àìní rẹ bí?

AFẸ́FẸ́, omi, oúnjẹ, ibùgbé​—⁠ìwọ̀nyí ni a mọ̀ yíká ayé gẹ́gẹ́ bí àìní àwọn ènìyàn. Láìsí wọn ìwọ dojúkọ ìlálàṣí àti ikú. Bí ó ti wù kí ó rí, tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni aṣáájú àwọn ọmọ Israeli náà Mose ti pe àfiyèsí sí àìní mìíràn tí ènìyàn ní, ọ̀kan tí ó tilẹ̀ ṣe pàtàkì ju oúnjẹ tàbí omi lọ. Mose wí pé: “Ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wàláàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde ni ènìyàn wàláàyè.”​—⁠Deuteronomi 8:⁠3.

Nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ jíjinlẹ̀ wọ̀nyí, Mose fi ìjẹ́pàtàkì kíkúnjú àwọn àìní wa nípa ti ìsìn tàbí nípa tẹ̀mí hàn. Ó fihàn pé ìwàláàyè wa gan-⁠an sinmilórí títẹ́ àwọn àìní náà lọ́rùn! Ní gbogbo 40 ọdún tí wọ́n fi rìn ní aginjù, níti gidi ni àwọn ọmọ Israeli wàláàyè nípa “ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde.” Wọn la ohun tí ìbá ti jásí ìrírí mímúná tí ń yọrísí ikú já. Nípasẹ̀ àṣẹ Ọlọrun, oúnjẹ kan tí a pé orúkọ rẹ̀ ní mánnà rọ̀ sílẹ̀ láti ọ̀run wá lọ́nà ìyanu. Omi ti inú àpáta jáde wá láti pòùngbẹ wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọrun ṣe ju bíbójútó àwọn àìní wọn nípa ti ara lọ. Mose wí pé: “Bí ènìyàn tií bá ọmọ rẹ̀ wí, bẹ́ẹ̀ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wí.”​—⁠Deuteronomi 8:​4, 5; Eksodu 16:31, 32; 17:5, 6.

A kò fi àwọn ọmọ Israeli sílẹ̀ láti dá bójútó araawọn níti pípinnu ohun tí ó tọ̀nà tàbí tí kò tọ̀nà, níti ìwàrere tàbí níti ìsìn. Wọn ń gba ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun fúnraarẹ̀. Ó fún wọn ní Òfin Mose, àkójọ òfin kan tí ó ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ ètò oúnjẹ tí ń fúnninílera, akójọ òfin ìmọ́tótó ṣíṣe pàtó, àti àwọn ìlànà ti ìwàhíhù àti ti ìsìn tí ó gbámúṣé. Nítorí náà, Ọlọrun gbé ire Israeli ga nípa ti ìlera àti nípa tẹ̀mí. Wọ́n wàláàyè nípa “ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde.”

Lọ́nà yìí Israeli ní ìdúró tí ó yàtọ̀ gedegbe sí ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Ní ọjọ́ Mose Egipti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí agbára ayé tí ó mú ipò iwájú jùlọ. Ó jẹ́ ilẹ̀ kan tí ó lẹ́mìí ìsìn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Book Encyclopedia sọ pé: “Àwọn ará Egipti ìgbàanì gbàgbọ́ pé onírúurú àwọn ọlọrun àjọ́sìnfún (àwọn akọ àti abo ọlọrun) ń nípalórí gbogbo apá ìhà ànímọ́ ẹ̀dá àti gbogbo ìgbòkègbodò ènìyàn. Nítorí náà wọ́n ń jọ́sìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọrun àjọ́sìnfún. . . . Ní ìlú-ńlá àti ìlú Egipti kọ̀ọ̀kan, àwọn ènìyàn ń jọ́sìn àkànṣe ọlọrun tiwọn fúnraawọn ní àfikún sí àwọn ọlọrun àjọ́sìnfún pàtàkì mìíràn.”

Ìjọsìn ọ̀pọ̀ ọlọrun yìí ha kúnjú àwọn àìní tẹ̀mí ti àwọn ará Egipti bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Egipti di ilẹ̀ kan tí ó rì wọnú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àwọn àṣà ìbálòpọ̀ tí ń rẹnisílẹ̀. Jìnnà réré sí mímú ìgbésí-ayé àti ìlera wọn sunwọ̀n síi, ọ̀nà ìgbésí-ayé àwọn ará Egipti jálẹ̀ sí àwọn “àrùn búburú.” (Deuteronomi 7:15) Kò yanilẹ́nu, nígbà náà, pé Bibeli sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọrun Egipti lọ́nà ìyọṣùtìsí, ní pípè wọ́n ní “òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ.”​—⁠Esekieli 20:​7, 8, NW.

Ipò kan tí ó farajọ ọ́ wà lónìí. Ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn ní irú oríṣi ìgbàgbọ́ ìsìn kan ó kérétán; àwọn díẹ̀ pe araawọn ní aláìgbọlọ́rungbọ́. Àmọ́ ṣáá o, lọ́nà tí ó ṣe kedere, ìsìn ní gbogbogbòò ti kùnà láti tẹ́ àwọn àìní aráyé nípa tẹ̀mí lọ́rùn. Ǹjẹ́ ìṣòro ogun, èrò ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá, ìjìyà lọ́wọ́ ebi, àti ipò òṣì tí ń báa lọ láìdẹwọ́ yóò ha wà lónìí bí ó bá jẹ́ pé nítòótọ́ ni àwọn ènìyàn ń gbé “nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde” bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀kọ́! Bí ó bá tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ pàápàá, ìwọ̀nba ni àwọn ènìyàn ti yóò ronú nípa yíyí ìsìn wọn padà. Họ́wù, àwọn kan kò tilẹ̀ múratán láti jíròrò ìsìn tàbí láti fiyèsí àwọn èrò ìsìn titun!

Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan ní Ghana, Ìwọ̀-Oòrùn Africa, sọ fún Kristian òjíṣẹ́ kan pé: “Mo gbàgbọ́ pé Ọlọrun ti ṣí araarẹ̀ payá fún àwa ará Africa nípasẹ̀ àwọn àlùfáà ọkùnrin àti àlùfáà obìnrin wa lílágbára, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣí araarẹ̀ payá fún àwọn Ju nípasẹ̀ àwọn wòlíì wọn. Ó ṣeniláàánú pé díẹ̀ lára àwa ará Africa kùnà láti mọ àwọn àlùfáà tiwa ṣùgbọ́n a wulẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa Jesu, Muhammad, àti àwọn mìíràn.”

Nínú ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ ìbílẹ̀ ti àwọn ará Africa, ìsìn Kristian ni a ń wò gẹ́gẹ́ bí ìsìn àwọn aláwọ̀ funfun​—⁠ètò ìgbékalẹ̀ kan tí a mú wọlé wá látòkèèrè tí ibi tí ó ti ṣe pọ̀ ju ire lọ. Ṣùgbọ́n ìṣarasíhùwà aláìṣí-ọkàn payá yóò ha ṣèrànwọ́ fún àwọn ìsapá rẹ láti mú kí a kúnjú àwọn àìní tẹ̀mí rẹ tàbí yóò ṣèdíwọ́ fún wọn bí? Òwe ilẹ̀ Africa kan sọ pé: “Ebi ò ní ká kọwọ́ méjì bọnú àwo.” Irú ọ̀nà ìgbà jẹun bẹ́ẹ̀ jẹ́ àìmọ̀wàáhù ó sì léwu​—⁠pàápàá bí ìwọ kò bá mọ ohun tí ń bẹ nínú àwo! Síbẹ̀, àwọn kan kò gbé yíyan ìsìn wọn karí àyẹ̀wò kínníkínní, bíkòṣe karí ìmọ̀lára tàbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìdílé.

Ìjọsìn náà tí ó kúnjú àwọn àìní tẹ̀mí rẹ níláti jẹ́ “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò [rẹ].” (Romu 12:⁠1, NW) Ó níláti jẹ́ yíyàn ọlọgbọ́n, tí a kò fi àìmọ̀kan ṣe. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò kókó ọ̀ràn ti yíyan ìsìn ẹni lọ́nà tí àwọn ará Africa gbà wò ó. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn òǹkàwé níbi gbogbo ni wọn yóò lọ́kàn-ìfẹ́ sí ohun tí ó tẹ̀lé e.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Mose fi ìjẹ́pàtàkì kíkúnjú àwọn àìní tẹ̀mí wa hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìrírí tí àwọn ará Africa ní pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì Kristẹndọm ti sé ọkàn àwọn kan sí Bibeli

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́