-
A Ti Sọ Yín Di Mímọ́Ilé Ìṣọ́—2013 | August 15
-
-
Báwo ni Nehemáyà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 6)
5, 6. Ta ni Élíáṣíbù? Tani Tobáyà? Kí ló pa Élíáṣíbù àti Tobáyà pọ̀?
5 Ka Nehemáyà 13:4-9. Torí pé àwọn tí kò fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló yí wa ká, kì í rọrùn rárá láti jẹ́ mímọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Élíáṣíbù àti Tobáyà yẹ̀ wò. Àlùfáà àgbà ni Élíáṣíbù. Àmọ́ ọmọ Ámónì ni Tobáyà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ aṣojú kan lábẹ́ ìjọba Páṣíà nígbà tí Páṣíà ń ṣàkóso ilẹ̀ Jùdíà. Tobáyà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ta ko Nehemáyà nígbà tó fẹ́ tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. (Neh. 2:10) Jèhófà sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ Ámónì ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dé itòsí tẹ́ńpìlì. (Diu. 23:3) Kí wá nìdí tí àlùfáà àgbà fi gbà pé kí Tobáyà máa gbé nínú ọ̀kan lára yàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì?
6 Àjọṣe tímọ́tímọ́ ló wà láàárín Tobáyà àti Élíáṣíbù. Nígbà tí Tobáyà máa fẹ́yàwó, Júù ló fẹ́, nígbà tọ́mọ rẹ̀ náà sì máa láyà, Júù lòun náà fẹ́. Ọ̀pọ̀ Júù ló sì máa ń sọ dáadáa nípa Tobáyà. (Neh. 6:17-19) Ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ Élíáṣíbù fẹ́ ọmọbìnrin Sáńbálátì. Gómìnà Samáríà ni Sáńbálátì, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Tobáyà. (Neh. 13:28) Àjọṣe tó wà láàárín wọn yìí jẹ́ ká lóye ìdí tí Élíáṣíbù àlùfáà àgbà fi jẹ́ kí Tobáyà tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti alátakò mú òun ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́, torí pé Nehemáyà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ńṣe ló kó àwọn ohun èlò ilé bí àga, tábìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́ tí Tobáyà ní jù síta.
-
-
A Ti Sọ Yín Di Mímọ́Ilé Ìṣọ́—2013 | August 15
-
-
8. Kí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó bá ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà máa rántí tó bá dọ̀rọ̀ irú àwọn tó yẹ kí wọ́n mú lọ́rẹ̀ẹ́?
8 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:33) Àwọn ìbátan wa kan lè mú kó ṣòro fún wa láti máa ṣe ohun tó tọ́. Ohun tó dáa ni Élíáṣíbù ṣe bó ṣe ti Nehemáyà lẹ́yìn nígbà tó ń tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, èyí sì mú káwọn Júù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Neh. 3:1) Àmọ́ nígbà tó yá, Tobáyà àtàwọn míì ní ipa búburú lórí rẹ̀, èyí ló sì sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin lójú Jèhófà. Tá a bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dára, wọ́n á fún wa níṣìírí láti máa ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí, bíi kíka Bíbélì lójoojúmọ́, lílọ sípàdé àti lílọ sí òde ẹ̀rí déédéé. Ó dájú pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ìbátan tó ń fún wa níṣìírí láti máa ṣe ohun tó tọ́, a sì mọrírì wọn gan-an.
-