ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Àwọn tí kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run (1-8)

      • Kí ibùdó máa wà ní mímọ́ (9-14)

      • Ẹrú tó sá lọ (15, 16)

      • Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe aṣẹ́wó (17, 18)

      • Èlé àti ẹ̀jẹ́ (19-23)

      • Ohun tí ẹni tó ń kọjá lọ lè jẹ (24, 25)

Diutarónómì 23:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:18, 20; Ais 56:4, 5

Diutarónómì 23:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:14; Le 20:10

Diutarónómì 23:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 13:1, 2

Diutarónómì 23:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pe ibi wá sórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 11:18
  • +Nọ 22:6; Joṣ 24:9

Diutarónómì 23:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:35
  • +Nọ 23:11, 25; 24:10
  • +Di 7:7, 8

Diutarónómì 23:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:2; 12:31

Diutarónómì 23:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:25, 26; 36:1; Nọ 20:14
  • +Jẹ 46:6; Le 19:34; Sm 105:23

Diutarónómì 23:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ń sọni di aláìmọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 21:5; 2Sa 11:11

Diutarónómì 23:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:16

Diutarónómì 23:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:31

Diutarónómì 23:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ilé ìyàgbẹ́.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2012, ojú ìwé 6

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 47-48

Diutarónómì 23:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2012, ojú ìwé 6

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 47-48

Diutarónómì 23:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:12
  • +1Pe 1:16

Diutarónómì 23:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:21

Diutarónómì 23:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:29; 21:9
  • +1Ọb 14:24; 2Ọb 23:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/1997, ojú ìwé 29

Diutarónómì 23:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “owó tí ọkùnrin kan gbà.”

  • *

    Ní Héb., “owó tí wọ́n san fún ajá.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/1997, ojú ìwé 29

Diutarónómì 23:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:25; Le 25:36, 37; Ne 5:10; Sm 15:5

Diutarónómì 23:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:6
  • +Owe 28:8
  • +Di 15:4, 7, 10; Owe 19:17; Lk 6:34, 35

Diutarónómì 23:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 11:30, 31; 1Sa 1:11
  • +Jon 2:9
  • +Onw 5:4, 6

Diutarónómì 23:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 5:5

Diutarónómì 23:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 30:2; Sm 15:4; Owe 20:25
  • +Ond 11:35; 1Sa 14:24; Mt 5:33

Diutarónómì 23:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 6:11; Ro 13:10

Diutarónómì 23:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 12:1; Lk 6:1

Àwọn míì

Diu. 23:1Le 21:18, 20; Ais 56:4, 5
Diu. 23:2Ẹk 20:14; Le 20:10
Diu. 23:3Ne 13:1, 2
Diu. 23:4Ond 11:18
Diu. 23:4Nọ 22:6; Joṣ 24:9
Diu. 23:5Nọ 22:35
Diu. 23:5Nọ 23:11, 25; 24:10
Diu. 23:5Di 7:7, 8
Diu. 23:62Sa 8:2; 12:31
Diu. 23:7Jẹ 25:25, 26; 36:1; Nọ 20:14
Diu. 23:7Jẹ 46:6; Le 19:34; Sm 105:23
Diu. 23:91Sa 21:5; 2Sa 11:11
Diu. 23:10Le 15:16
Diu. 23:11Le 15:31
Diu. 23:14Le 26:12
Diu. 23:141Pe 1:16
Diu. 23:16Ẹk 22:21
Diu. 23:17Le 19:29; 21:9
Diu. 23:171Ọb 14:24; 2Ọb 23:7
Diu. 23:19Ẹk 22:25; Le 25:36, 37; Ne 5:10; Sm 15:5
Diu. 23:20Di 15:6
Diu. 23:20Owe 28:8
Diu. 23:20Di 15:4, 7, 10; Owe 19:17; Lk 6:34, 35
Diu. 23:21Ond 11:30, 31; 1Sa 1:11
Diu. 23:21Jon 2:9
Diu. 23:21Onw 5:4, 6
Diu. 23:22Onw 5:5
Diu. 23:23Nọ 30:2; Sm 15:4; Owe 20:25
Diu. 23:23Ond 11:35; 1Sa 14:24; Mt 5:33
Diu. 23:24Mt 6:11; Ro 13:10
Diu. 23:25Mt 12:1; Lk 6:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 23:1-25

Diutarónómì

23 “Ọkùnrin èyíkéyìí tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tí wọ́n fọ́ kórópọ̀n rẹ̀ tàbí tí wọ́n gé ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ kúrò kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+

2 “Ọmọ àlè kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran rẹ̀ kẹwàá, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.

3 “Ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran wọn kẹwàá, àtọmọdọ́mọ wọn kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà láé, 4 torí pé wọn ò fún yín ní oúnjẹ àti omi láti fi ràn yín lọ́wọ́ nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n sì tún gba Báláámù ọmọ Béórì láti Pétórì ti Mesopotámíà pé kó wá gégùn-ún fún* yín.+ 5 Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ò gbọ́ ti Báláámù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yí ègún náà pa dà sí ìbùkún fún ọ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ 6 O ò gbọ́dọ̀ wá ire wọn tàbí ìtẹ̀síwájú wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+

7 “O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Édómù, torí arákùnrin rẹ ni.+

“O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Íjíbítì, torí o di àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀.+ 8 Ìran kẹta àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí fún wọn lè wá sínú ìjọ Jèhófà.

9 “Tí o bá pàgọ́ láti gbógun ja àwọn ọ̀tá rẹ, kí o yẹra fún ohunkóhun tí kò dáa.*+ 10 Tí ọkùnrin kan bá di aláìmọ́ torí pé àtọ̀ dà lára rẹ̀ ní òru,+ kó kúrò nínú ibùdó, kó má sì pa dà síbẹ̀. 11 Tó bá di ìrọ̀lẹ́, kó fi omi wẹ̀, tí oòrùn bá sì ti wọ̀, kó pa dà sínú ibùdó.+ 12 Kí ibi ìkọ̀kọ̀* kan wà tí wàá máa lò lẹ́yìn ibùdó, ibẹ̀ sì ni kí o lọ. 13 Kí igi tó ṣeé fi gbẹ́lẹ̀ wà lára àwọn ohun èlò rẹ. Tí o bá lóṣòó ní ìta láti yàgbẹ́, kí o fi igi náà gbẹ́lẹ̀, kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ. 14 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn kiri nínú ibùdó rẹ+ láti gbà ọ́, kó sì fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́. Kí ibùdó rẹ máa wà ní mímọ́,+ kó má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu láàárín rẹ, kó sì pa dà lẹ́yìn rẹ.

15 “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹrú lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ tó bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. 16 Ó lè máa gbé láàárín rẹ níbikíbi tó bá yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, níbikíbi tó bá wù ú. Má fìyà jẹ ẹ́.+

17 “Ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì.+ 18 O ò gbọ́dọ̀ mú owó tí wọ́n san fún obìnrin kan nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí owó tí wọ́n san fún ọkùnrin kan* nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* wá sínú ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́, torí méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.

19 “O ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ ì báà jẹ́ èlé lórí owó, lórí oúnjẹ tàbí ohunkóhun tí wọ́n ń gba èlé lé lórí. 20 O lè gba èlé lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+

21 “Tí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ má ṣe lọ́ra láti san án.+ Torí ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 22 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́jẹ̀ẹ́, kò ní di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 23 Máa mú ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ṣẹ,+ tí o bá sì fi ẹnu ara rẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ pé wàá ṣe ọrẹ àtinúwá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, o gbọ́dọ̀ ṣe é.+

24 “Tí o bá lọ sínú ọgbà àjàrà ọmọnìkejì rẹ, o lè jẹ èso àjàrà débi tó bá tẹ́ ọ* lọ́rùn, àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ kó ìkankan sínú àpò rẹ.+

25 “Tí o bá wọ inú oko ọkà ọmọnìkejì rẹ, o lè fọwọ́ ya àwọn ṣírí ọkà tó ti gbó, àmọ́ má yọ dòjé ti ọkà ọmọnìkejì rẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́