25 Èyí àkọ́kọ́ sì jáde, ó pupa látòkè délẹ̀, ó dà bí aṣọ onírun,+ torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísọ̀.+ 26 Lẹ́yìn náà, àbúrò rẹ̀ jáde, ó sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú, torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.+ Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Ísákì nígbà tí Rèbékà bí àwọn ọmọ náà.