Jehofa Ńgbọ́ Igbe Wa Kanjukanju fun Iranlọwọ
IRANLỌWỌ ni a nilo ni kanjukanju. Iyẹn han gbangba ninu ifajuro nla ti o han loju agbọ́tí ọba naa. Nigba ti a beere ohun ti o ṣẹlẹ, agbọ́tí naa sọ ibanujẹ rẹ̀ jade lori ipo iparun dahoro ti Jerusalẹmu ati awọn ogiri rẹ̀ wà. Nigba naa ni a beere pe: ‘Ẹ̀bẹ̀ ki ni iwọ fẹ́ bẹ̀?’ “Bẹẹ ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun,” ni agbọ́tí naa Nehemaya kọwe lẹhin naa. Iyẹn jẹ igbe kanjukanju fun iranwọ Jehofa ni kiakia, ati ni idakẹjẹẹ. Abajade rẹ̀? Họọwu, ọba Atasasita ti Paṣia loju ẹsẹ paṣẹ fun Nehemaya lati tun Jerusalẹmu ati ògiri rẹ̀ kọ́!—Nehemaya 2:1-6.
Bẹẹni, Ọlọrun ngbọ ẹ̀bẹ̀ kanjukanju awọn wọnni ti wọn nifẹẹ rẹ̀. (Saamu 65:2) Nitori naa bi idanwo kan ba dabi eyi ti o tobi ju eyi ti iwọ lè farada, iwọ lè gbadura gẹgẹ bi onisaamu naa Dafidi ti ṣe ninu Saamu 70, nigba ti oun nilo iranlọwọ atọrunwa ni kiakia. Akọle ori iwe saamu yii fihan pe ète rẹ̀ ni “lati mú un wa si iranti.” Pẹlu awọn iyipada diẹ, oun ṣakọtunkọ Saamu 40:13-17 lẹẹkan sii. Ṣugbọn bawo ni Saamu 70 ṣe le ran wa lọwọ gẹgẹ bi awọn eniyan Jehofa?
Ẹ̀bẹ̀ fun Idande Kiakia
Dafidi bẹrẹ pẹlu ẹ̀bẹ̀ naa: “Óò Ọlọrun, dá mi nídè, Óò Jehofa, si iranlọwọ mi ni ki o yarakankan.” (Saamu 70:1, NW) Nigba ti a bá wà ninu isorikọ, awa le gbadura pe ki Ọlọrun wá si iranlọwọ wa ni kiakia. Jehofa kii fi buburu dan wa wo, oun sì “mọ̀ bi a ti nyọ awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo.” (2 Peteru 2:9; Jakọbu 1:13) Ṣugbọn ki ni bi oun ba fàyègbà idanwo kan lati maa baa lọ, boya lati kọ́ wa lẹkọọ ohun kan? Nigba naa awa le beere fun ọgbọ́n rẹ̀ lati koju rẹ̀. Bi awa ba beere ninu igbagbọ, oun yoo fun wa ni ọgbọ́n. (Jakọbu 1:5-8) Ọlọrun pẹlu nfun wa ni agbara ti a nílò lati farada awọn adanwo wa. Fun apẹẹrẹ, oun ‘yoo gbà wá niyanju lori ẹní àrùn.’—Saamu 41:1-3; Heberu 10:36.
Awọn ẹ̀ṣẹ̀ ajogunba wa, bakan naa pẹlu iṣisilẹ wa igba gbogbo si idẹwo ati awọn isapa Eṣu lati ba ibatan wa pẹlu Jehofa jẹ, nilati sun wa lati gbadura si Ọlọrun fun iranlọwọ ni ojoojumọ. (Saamu 51:1-5; Roomu 5:12; 12:12) Eyi ti o yẹ fun afiyesi ni awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ninu adura awokọṣe Jesu: “Má sì mu wa bọ sinu idẹwo, ṣugbọn gbà wá lọwọ ẹni buruku naa.” (Matiu 6:13, NW) Bẹẹni, awa lè beere lọwọ Ọlọrun pe ki o maṣe jẹ ki a juwọ silẹ nigba ti a ba dán wa wò lati ṣe aigbọran sii ati pe ki o ṣe idena fun Satani, “ẹni buruku naa,” lati ma bori wa. Ṣugbọn ẹ jẹ ki a pa awọn igbe wa fun idande pọ̀ pẹlu awọn igbesẹ lati yẹra fun awọn ipo ti yoo ṣí wa silẹ lainidii si idẹwo ati awọn idẹkun Satani.—2 Kọrinti 2:11.
Awọn Ti Nwipe, “Àháà!”
A le dẹ wa wo lọna lilekoko nitori ti awọn ọta nkẹgan wa fun igbagbọ ti a ni. Bi iyẹn ba ṣẹlẹ si ọ, ronu jinlẹ lori awọn ọ̀rọ̀ Dafidi: “Njẹ ki oju tì ki a sì dààmú awọn wọnni ti nwa ọkàn mi. Njẹ ki wọn pẹhinda ki a sì tẹ wọn lógo awọn wọnni ti nni inudidun ninu àjálù mi. Njẹ ki awọn wọnni pada nitori itiju wọn awọn ti nwipe: ‘Àháà, àháà!’” (Saamu 70:2, 3, NW) Awọn ọta Dafidi fẹ rii pe ó kú: wọn ‘nlepa ọkàn’ tabi iwalaaye rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, kaka ti iba fi gbiyanju lati gbẹsan, lo igbagbọ pe Ọlọrun yoo kó itiju ba wọn. Dafidi gbadura pe “ki oju tì ki a sì daamu” awọn ọta rẹ̀—kí á marani wọn, sọ wọn dasan, dí wọn lọ́nà, mu wọn jakulẹ ninu igbiyanju wọn lati mu awọn ete buruku wọn ṣẹ. Bẹẹni, jẹ ki awọn ti nwa ifarapa rẹ̀ ati awọn ti wọn ni inudidun ninu wahala rẹ̀ kọsẹ ki wọn sì niriiri itiju.
Bi awa ba ni ohun ti a lè pe ni idunnu alarankan nigba ti wahala ba ṣubu lu ọta kan, awa yoo nilati jihin fun Jehofa fun ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Owe 17:5; 24:17, 18) Bi o ti wu ki o ri, nigba ti awọn ọta ba kẹgan Ọlọrun ati awọn eniyan rẹ̀, awa lè gbadura pe nitori orukọ mimọ rẹ̀, ki Jehofa ‘dá wọn pada ki o sì jẹ ki wọn jiya irẹsilẹ’ niwaju awọn eniyan naa ti wọn ti nwa ọla. (Saamu 106:8) Ẹsan jẹ ti Ọlọrun, oun lè dojuti wọn, ki o si rẹ awọn ọta rẹ ati tiwa silẹ. (Deuteronomi 32:35) Fun apẹẹrẹ, aṣiwaju Nazi naa Adolf Hitler wa ọna lati pa awọn Ẹlẹrii Jehofa rẹ́ kuro ni Germany. Wo bi oun ti kuna gidigidi tó, nitori ọpọlọpọ ẹgbẹẹgbẹrun wọn nisinsinyi ni wọn npolongo ihin iṣẹ Ijọba naa nibẹ!
Ninu ìfiniṣẹ̀sín ẹlẹya, awọn ọta wa le wipe: “Àháà, àháà!” Niwọnbi wọn ti gan Ọlọrun ati awọn eniyan rẹ̀, jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ wọnni “pada nitori itiju wọn,” ni jijiya ikotijubani. Nigba ti a ba ngbadura fun eyi, ẹ jẹ ki a di iwatitọ wa mu ki a sì mu ọkan Jehofa yọ, ki oun baa lè da Satani lohun ati ẹnikẹni miiran ti o ńgàn Án. (Owe 27:11) Ki awa maṣe bẹru awọn ọta wa agberaga lae, nitori “ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa [“Jehofa,” NW] ni a o gbé leke.” (Owe 29:25) Nebukadinesari ọba Babiloni agberaga, ẹni ti o ti mu awọn eniyan Ọlọrun ni igbekun, ni iriri ikotijubani ti o sì nilati gba pe ‘Ọba awọn ọrun naa lagbara lati rẹ awọn wọnni ti nrin ni igberaga silẹ.’—Daniẹli 4:37.
“Ki Ọlọrun Di Gbígbégalọ́lá!”
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọta lè fa ijangbọn ba wa, ẹ jẹ ki a maa fi igbagbogbo gbe Jehofa ga pẹlu awọn olujọsin ẹlẹgbẹ wa. Kaka ti iba fi gba ara rẹ̀ laaye lati di ẹni ti a gbémì nipasẹ ikarisọ ti oun yoo fi kuna lati gbe Ọlọrun galọla, Dafidi wipe: “Njẹ ki wọn maa yọ ayọ aṣeyọri ki wọn sì maa yọ ninu rẹ, gbogbo awọn ẹni ti nṣafẹri rẹ, njẹ ki wọn sì lè maa sọ nigba gbogbo pe: ‘Ki Ọlọrun di gbígbégalọ́lá!’—awọn ti nfẹ igbala rẹ.” (Saamu 70:4, NW) Awọn eniyan Jehofa nbaa lọ lati jẹ oninudidun gidi nitori pe wọn “nyọ ayọ aṣeyọri ti wọn sì nyọ” ninu rẹ̀. Gẹgẹ bi awọn ẹlẹrii rẹ̀ oluṣeyasimimọ, ti a sì ti baptisi, wọn ni idunnu naa ti o njade lati inu ibatan timọtimọ pẹlu rẹ̀. (Saamu 25:14) Sibẹsibẹ, a lè woye wọn gẹgẹ bi awọn onirẹlẹ oluṣafẹri Ọlọrun. Bi wọn ṣe jẹ onigbagbọ wọn nbaa lọ lati maa pa awọn aṣẹ Ọlọrun mọ́, wọn nfi igbagbogbo tubọ ṣafẹri ìmọ̀ sii nipa rẹ̀ ati ọrọ rẹ̀.—Oniwaasu 3:11; 12:13, 14; Aisaya 54:13.
Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹrii Jehofa ti npolongo ihinrere naa, ni iyọrisi rẹ̀ wọn nfi igba gbogbo wipe: “Ki Ọlọrun di gbígbégalọ́lá!” Wọn n pokiki Jehofa, ni kika a si ẹni ti o yẹ fun iyì giga julọ. Pẹlu idunnu, wọn ran awọn olùwá otitọ kiri lọwọ lati kẹkọọ nipa Ọlọrun ati lati fi ògo fun un pẹlu. Laidabi awọn ẹni ayé olùfẹ́ adùn, awọn eniyan Jehofa ‘fẹran igbala rẹ̀.’ (2 Timoti 3:1-5) Ni mimọ ipo ẹṣẹ ajogunba wa, wọn mọriri lọna jijinlẹ fun ipese Jehofa Ọlọrun onifẹẹ fun igbala si iye ayeraye, eyi ti a mu ki o ṣeeṣe nipasẹ ẹbọ etutu ipẹtu Ọmọkunrin rẹ̀ olufẹ, Jesu Kristi. (Johanu 3:16; Roomu 5:8; 1 Johanu 2:1, 2) Iwọ ha ngbe Ọlọrun ga lọla ti iwọ sì nfihan pe iwọ ‘fẹran igbala rẹ̀’ nipa ṣiṣe ijọsin tootọ si iyin rẹ̀ bi?—Johanu 4:23, 24.
Gbẹkẹle Olupese Asala Naa
Nigba ti Dafidi ṣalaye ara rẹ̀ ninu saamu yii, oun nimọlara aini lọna igbekuta ti oun fi wipe: “Ṣugbọn emi jẹ òtòṣì ati ẹni ti a npọn loju. Óò Ọlọrun, gbe igbesẹ ni kiakia nitori mi. Iwọ jẹ iranwọ mi ati Olupese asala fun mi. Óò Jehofa, maṣe pẹ́ jù.” (Saamu 70:5, NW) Nigba ti a ba pọ́n wa loju pẹlu idanwo ti ndeba awọn onigbagbọ—iru awọn ipọnju bii inunibini, idẹwo, ati ifipakọluni lojiji lati ọdọ Satani—a lè dabi “òtòṣì.” Bi o tilẹ jẹ pe awa lè ma jẹ abòṣì, o dabi ẹni pe awa wà laisi aabo lodisi awọn ọta alaibikita. Bi o ti wu ki o ri, awa lè ni igbẹkẹle pe Jehofa lè yoo sì gbà wa là gẹgẹ bi awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ.—Saamu 9:17-20.
Jehofa ni “Olupese asala” nigba ti a ba nilo rẹ̀. Aidoju ìwọ̀n tiwa funraawa ti lè mú wa bọ sinu ipo ti ndanniwo. Ṣugbọn bi ‘iwa omugọ wa ba yi ọna wa po,’ ẹ maṣe jẹ ki ọkan-aya wa ‘di eyi ti a mu binu lodisi Jehofa.’ (Owe 19:3) Kii ṣe oun ni o ni ẹbi, oun sì ti ṣetan lati ran wa lọwọ bi a ba gbadura si i pẹlu igbagbọ. (Saamu 37:5) Ki ni bi awa ba njijakadi lati yẹra fun ẹ̀ṣẹ̀? Nigba naa ẹ jẹ ki a ṣe pato nipa eyi ninu adura, ki a beere fun iranlọwọ atọrunwa lati maa baa lọ ni lilepa ọna ododo. (Matiu 5:6; Roomu 7:21-25) Ọlọrun yoo dahun adura atọkanwa wa awa yoo sì laasiki nipa tẹmi bi awa ba juwọsilẹ si idari ẹmi mimọ rẹ̀.—Saamu 51:17; Efesu 4:30.
Nigba ti a ba wà ninu awọn irora idanwo igbagbọ, awa le nimọlara pe awa kò lè farada a siwaju sii mọ. Niwọnbi ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wa ti jẹ alailera, o lè yánhànhàn fun ajabọ ti o yarakankan. (Maaku 14:38) Nitori naa awa lè bẹbẹ pe: “Óò Jehofa, maṣe pẹ́ jù.” Ni pataki julọ bi awa ba daniyan nipa mimu ẹgan wa sori orukọ Ọlọrun, a lè sun wa lati gbadura gẹgẹ bi wolii Daniẹli ti ṣe: “Oluwa, gbọ́; Oluwa, dariji. Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o sì ṣe é; maṣe jafara, nitori ti iwọ tikaraarẹ, Ọlọrun mi, nitori orukọ rẹ ni a fi npe . . . awọn eniyan rẹ.” (Daniẹli 9:19) Awa lè ni igbagbọ pe Baba wa ọrun ki yoo pẹ́ jù, nitori apọsteli Pọọlu funni ni idaloju yii: “Ẹ jẹ ki a sunmọ ìtẹ́ inurere ailẹtọọsi pẹlu ominira ọ̀rọ̀ sisọ, ki a lè ri aanu gbà ki a sì ri inurere ailẹtọọsi fun iranlọwọ ni akoko ti o tọ́.”—Heberu 4:16, NW.
Maṣe gbagbe lae pe Jehofa jẹ Olupese asala. Gẹgẹ bi awọn iranṣẹ rẹ̀, yoo ṣe wa ni rere bi a ba ranti eyi ati awọn ọ̀rọ̀ ironu ti o kun fun adura ti o wa ninu Saamu 70. Ni igba miiran awa lè nilo lati gbadura leralera nipa ọran kan ti o jẹni lọkan gidigidi. (1 Tẹsalonia 5:17) O le dabi ẹni pe ko si ojutuu si iṣoro pataki kan, ko si ọna abajade si ẹtì wa. Ṣugbọn Baba wa ọrun onifẹẹ yoo fun wa lokun kì yoo sì jẹ ki a dán wa wò rekọja ohun ti a lè farada. Nitori naa, maṣe ṣaarẹ lae ni lilọ siwaju itẹ Ọba Ayeraye naa ninu adura atọkanwa. (1 Kọrinti 10:13; Filipi 4:6, 7, 13; Iṣipaya 15:3) Gbadura pẹlu igbagbọ, ki o sì ni igbẹkẹle ninu rẹ̀ laiṣimeji, nitori Jehofa ngbọ igbe wa kanjukanju fun iranlọwọ.