Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Jésù ha ti mọ ìgbà tí Amágẹ́dónì yóò jà báyìí bí?
Ó dà bí ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé ó mọ̀ ọ́n.
Àwọn kan lè ṣe kàyéfì nípa ohun tí ó gbé ìbéèrè náà dìde pàápàá. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí Jésù tí a ri nínú Mátíù 24:36 pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn kò sí ẹnì kan tí ó mọ̀, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì àwọn ọ̀run tàbí Ọmọkùnrin, bí kò ṣe Bàbá nìkan.” Ṣàkíyèsí àpólà ọ̀rọ̀ náà “tàbí Ọmọkùnrin.”
Ẹsẹ yìí jẹ́ apá kan èsì Jésù sí ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó lókìkí nísinsìnyí nípa àwọn ẹ̀rí tí ó para pọ̀ jẹ́ “àmì,” ó sàsọtẹ́lẹ̀ ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀, inúnibíni sí àwọn Kristẹni tòótọ́, àti àwọn nǹkan mìíràn lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò fi wíwà níhìn-ín rẹ̀ hàn. Nípasẹ̀ àmì yìí, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé. Ó fi ìsúnmọ́lé yìí wé àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ bá bẹ̀rẹ̀ sí í rúwé, ó ń fi hàn pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Ó fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé òún ti sún mọ́ itòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.”—Mátíù 24:33.
Àmọ́ Jésù kò sọ ní pàtó ìgbà tí òpin náà yóò dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ ohun tí a kà ní Mátíù 24:36. Bí ó ṣe kà nínú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures nìyẹn, kíkà ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì òde òní sì fara jọ ọ́. Síbẹ̀, àwọn ìtumọ̀ àtijọ́ kan kò ní “tàbí Ọmọkùnrin” nínú.
Fún àpẹẹrẹ, ìtumọ̀ Douay Version ti Kátólíìkì kà pé: “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó mọ ọjọ́ náà, kì í tilẹ̀ẹ́ ṣe àwọn áńgẹ́lì ọ̀run, bí kò ṣe Bàbá nìkan ṣoṣo.” Ìtumọ̀ King James Version kà lọ́nà tí ó fara jọ ọ́. Èé ṣe tí wọ́n fi fo “tàbí [yálà] Ọmọkùnrin,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí i nínú Máàkù 13:32? Nítorí pé nígbà náà lọ́hùn-ún ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹtàdínlógún nígbà tí a ń ṣe àwọn ìtumọ̀ méjèèjì wọ̀nyí lọ́wọ́, àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí àwọn olùtumọ̀ lò kò ní gbólóhùn yẹn. Ṣùgbọ́n, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì wá sójú táyé. Àwọn wọ̀nyí, tí wọ́n sún mọ́ àkókò tí a kọ ìwé Mátíù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ní “tàbí Ọmọkùnrin,” nínú Mátíù 24:36.
Ó dùn mọ́ni pé, ìtumọ̀ Jerusalem Bible ti Kátólíìkì ní àpólà ọ̀rọ̀ náà nínú, pẹ̀lú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé tí ó sọ pé ìtumọ̀ Vulgate lédè Látìnì fo gbólóhùn náà, “bóyá nítorí ìdí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìsìn.” Họ́wù, dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! A lè dán àwọn olùtumọ̀ àti adàwékọ tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan wò láti fo àpólà ọ̀rọ̀ kan tí ó fi hàn pé Jésù kò mọ ohun tí Bàbá rẹ̀ mọ́. Báwo ni Jésù kò ṣe ní mọ òkodoro òtítọ́ kan bí òun àti Bàbá rẹ̀ bá jẹ́ apá kan Ọlọ́run mẹ́ta nínú ẹyọ kan?
Lọ́nà jíjọra, ìwé náà, A Textual Commentary on the Greek New Testament, tí B. M. Metzger ṣe, sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ náà ‘tàbí Ọmọkùnrin’ kò sí nínú ọ̀pọ̀ [ìwé àfọwọ́kọ] àwọn ẹlẹ́rìí Mátíù, títí kan ìwé Byzantine tí ó dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, aṣojú dídára jù lọ fún Alexandria, fún Ìwọ̀ Oòrùn, àti oríṣi ìwé ti àwọn ará Kesaríà ní àpólà ọ̀rọ̀ náà. Fífo àwọn ọ̀rọ̀ náà nítorí ìṣòro ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní ṣeé ṣe láti gbà ju gbígbà pé àfikún ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́” sí Máàkù 13:32 lọ.—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
“Àwọn aṣojú dídára jù lọ” fún àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti ìjímìjí yẹn, ti ìwé tí ó gbé bí ìmọ̀ ṣe ń tẹ̀ síwájú lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu kalẹ̀ lẹ́yìn. Àwọn áńgẹ́lì kò mọ wákàtí tí òpin yóò dé; bẹ́ẹ̀ ni Ọmọkùnrin kò mọ̀ ọ́n; bí kò ṣe Bàbá nìkan ṣoṣo. Èyí sì bá ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí nínú Mátíù 20:23 mu, níbi tí ó ti gbà pé òun kò ní ọlá àṣẹ láti fúnni ní àyè títayọ nínú Ìjọba náà, ṣùgbọ́n Bàbá lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù alára fi hàn pé nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, kò mọ ọjọ́ náà tí ‘òpin ayé yóò dé.’ Ó ha ti mọ̀ ọ́n láti ìgbà náà bí?
Ìṣípayá 6:2 ṣàpèjúwe Jésù pé, ó jókòó lórí ẹṣin funfun, ó sì jáde lọ “ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Lẹ́yìn èyí, ni àwọn ẹlẹ́ṣin tí ó dúró fún ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, irú èyí tí a ti ń nírìírí rẹ̀ láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé ní ọdún 1914, Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀run, ẹni náà tí yóò mú ipò iwájú nínú ogun tí ń bọ̀ lòdì sí ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 6:3-8; 19:11-16) Níwọ̀n bí a ti gbé agbára wọ Jésù báyìí gẹ́gẹ́ bí ẹni náà tí yóò ṣẹ́gun ní orúkọ Ọlọ́run, ó dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu pé, Bàbá rẹ̀ yóò ti sọ ìgbà tí òpin yóò dé fún un, ìgbà tí yóò “parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”
A kò tí ì sọ ọjọ́ yẹn fún àwa tí a wà lórí ilẹ̀ ayé, nítorí náà, ọ̀rọ̀ Jésù kàn wá pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ máa wà lójúfò, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́. . . . Ohun tí mo wí fún yín ni mo wí fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Máàkù 13:33-37.