ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 7/8 ojú ìwé 18-19
  • Ǹjẹ́ Ó Lòdì Láti Yangàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Lòdì Láti Yangàn?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyangàn Tí Ń Ṣeni Léṣe
  • Ǹjẹ́ Ó Tọ̀nà Láti Yangàn?
  • Èrè Ìgbéraga—Báwo Ló Ṣe Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • O Lè Bá Sátánì Jà Kó o sì Borí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Fífi Ẹ̀yà Ẹni Yangàn Ńkọ́?
    Jí!—1998
  • Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀ àbí Ọlọgbọ́n?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 7/8 ojú ìwé 18-19

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Lòdì Láti Yangàn?

ÀWỌN èèyàn máa ń sọ pé ìyangàn ni àkọ́kọ́ lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ méje tí ń ṣekú pani. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ló gbà gbọ́ pé irú èròǹgbà bẹ́ẹ̀ kò bóde mu mọ́ rárá. Nída yìí, tí ọ̀rúndún kọkànlélógún ti dé tán, àwọn èèyàn ò ka ìyangàn sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ o, ojú ohun tó ṣeyebíye ni wọ́n fi ń wò ó.

Ṣùgbọ́n nígbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ìyangàn, ohun tí kò dáa ló sábà máa ń pè é. Ọ̀pọ̀ gbólóhùn ló wà nínú ìwé Òwe Bíbélì nìkan, tó bẹnu àtẹ́ lu ìyangàn. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 8:13 sọ pé: “Mo kórìíra ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn àti ọ̀nà búburú àti ẹnu tí ń ṣàyídáyidà.” Òwe 16:5 sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” Ẹsẹ kejìdínlógún sì kìlọ̀ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”

Ìyangàn Tí Ń Ṣeni Léṣe

A lè ṣàpèjúwe ìyangàn tí Bíbélì bẹnu àtẹ́ lù gẹ́gẹ́ bí gbígbéra ẹni níyì ju bó ti yẹ lọ, èrò mo-tó-tán, bóyá torí ẹ̀bùn àbínibí, ẹwà, ọrọ̀, ìmọ̀ ìwé, ipò iyì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń fara hàn nínú ìwà ìṣefọ́nńté, fífọ́nnu, ṣíṣàfojúdi, tàbí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú. Ríro ara ẹni ju bó ti yẹ lọ lè yọrí sí kíkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìbáwí tó yẹ; kíkọ̀ láti gbà pé a ṣàṣìṣe ká sì túúbá, kíkọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀, àti àìfẹ́ rẹ ara wa sílẹ̀; tàbí ó lè yọrí sí bíbínú rangbandan nítorí ohun tẹ́nì kan ṣe tàbí tó sọ.

Àwọn agbéraga èèyàn lè máa fi dandan lé e ṣáá pé ohun táwọn bá sọ labẹ gé. Kò ṣòro láti rí ìdí tí irú ìwà bẹ́ẹ̀ fi máa ń yọrí sí ìfagagbága. Fífi ìran tàbí orílẹ̀-èdè ẹni yangàn ti yọrí sí àìmọye ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, ìgbéraga ló sún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run láti ṣọ̀tẹ̀, tó sì wá sọ ara rẹ̀ di Sátánì Èṣù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí yóò mú kí Kristẹni kan tóótun láti di alàgbà, ó gbani nímọ̀ràn pé: “Kì í ṣe ọkùnrin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn padà, fún ìbẹ̀rù pé ó lè wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, kí ó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.” (1 Tímótì 3:6; fi wé Ìsíkíẹ́lì 28:13-17.) Bó bá ṣe pé ohun tí ìgbéraga ń fà nìwọ̀nyí, abájọ tí Ọlọ́run fi kà á sí ohun búburú. Àmọ́ ṣá o, o lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ó tọ̀nà lábẹ́ ipòkípò láti yangàn?’

Ǹjẹ́ Ó Tọ̀nà Láti Yangàn?

Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà kau·khaʹo·mai, táa tú sí “fi yangàn, yọ ayọ̀ ńláǹlà, ṣògo,” lọ́nà rere àti lọ́nà búburú. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé a lè “máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, lórí ìpìlẹ̀ ìrètí ògo Ọlọ́run.” Ó tún gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.” (Róòmù 5:2; 2 Kọ́ríńtì 10:17) Èyí túmọ̀ sí ṣíṣògo nínú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wa, èrò tó lè jẹ́ ká máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nítorí orúkọ rere àti ìfùsì rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe: Ǹjẹ́ ó lòdì láti fẹ́ gbèjà orúkọ rere nígbà táa bá fọ̀rọ̀ èké bà á jẹ́? Rárá o, kò lòdì. Báwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ tàbí nípa àwọn mìíràn tóo fẹ́ràn tóo sì bọ̀wọ̀ fún, ǹjẹ́ inú ò ní bí ẹ, ǹjẹ́ o ò sì ní fẹ́ gbèjà wọn? Bíbélì sáà sọ pé: “Orúkọ [rere] ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀.” (Òwe 22:1) Ní ìgbà kan, Ọlọ́run Olódùmarè sọ fún Fáráò, agbéraga ọba Íjíbítì pé: “Fún ìdí yìí ni mo ṣe mú kí o máa wà nìṣó, nítorí àtifi agbára mi hàn ọ́ àti nítorí kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Ẹ́kísódù 9:16) Nítorí náà, Ọlọ́run máa ń yọ ayọ̀ ńláǹlà nítorí orúkọ rere àti ìfùsì tirẹ̀, ó sì ní ìtara fún un. Àwa náà lè nífẹ̀ẹ́ sí gbígbèjà orúkọ rere àti ìfùsì wa, ṣùgbọ́n a kò ní ṣe é pẹ̀lú ẹ̀mí ìṣefọ́nńté àti ìgbéraga.—Òwe 16:18.

Ọ̀wọ̀ ṣe pàtàkì nínú ìbátan rere èyíkéyìí. Ìgbésí ayé wa láwùjọ àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa yóò máa jó rẹ̀yìn tí a kò bá fọkàn tán àwọn alájọṣe wa. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe tàbí àjọṣepọ̀ lè bà jẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo lára àwọn tí ń kọ́wọ́ tì í bá ṣe ohun kan tó ba orúkọ ara rẹ̀ tàbí tàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ jẹ́ láwùjọ. Bí wọn yóò bá lé góńgó wọn bá, ohun yòówù kí góńgó ọ̀hún jẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ pa orúkọ rere wọn mọ́. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìdí táwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni fi gbọ́dọ̀ ní “ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀” látọ̀dọ̀ àwọn ará òde. (1 Tímótì 3:7) Ìdí tí wọ́n fi ń fẹ́ láti ní orúkọ rere kì í ṣe láti máa gbéra ga, bí kò ṣe láti fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti ṣojú fún Ọlọ́run lọ́nà tó yẹ ẹ́, tó sì buyì kún un. Ó ṣe tán, báwo làwọn ará òde ṣe lè gba òjíṣẹ́ tí kò lórúkọ rere gbọ́?

Fífi àwọn àṣeyọrí ẹni yangàn ńkọ́? Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa bí inú àwọn òbí ti lè dùn tó nígbà tọ́mọ wọn bá ṣe dáadáa níléèwé. Irú àṣeyọrí bẹ́ẹ̀ jẹ́ orísun ìtẹ́lọ́rùn tó yẹ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Tẹsalóníkà, ó fi hàn pé inú òun náà máa ń dùn sí àṣeyọrí, ó ní: “Ó di dandan fún wa láti fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí ìgbàgbọ́ yín ń gbèrú lọ́nà tí ó peléke, ìfẹ́ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i lẹ́nì kìíní sí ẹnì kejì. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, àwa fúnra wa ń fi yín yangàn láàárín àwọn ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni yín àti àwọn ìpọ́njú tí ẹ ń mú mọ́ra.” (2 Tẹsalóníkà 1:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ni inú wa máa ń dùn nígbà táwọn táa fẹ́ràn bá ṣe àṣeyọrí. Nítorí náà, kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyangàn tó lòdì àti ìyangàn tó tọ́?

Kò sóhun tó burú nínú pé kí a fẹ́ láti pa orúkọ rere wa mọ́, ká fẹ́ láti ṣe àṣeyọrí, kí inú wa sì dùn táa bá ṣe àṣeyọrí ọ̀hún. Àmọ́ o, ìganpá, ìrera, àti fífọ́nnu nípa ara wa tàbí àwọn ẹlòmíràn lòdì lójú Ọlọ́run. Yóò mà kúkú burú o, bí ẹnikẹ́ni bá bẹ̀rẹ̀ sí “wú fùkẹ̀” nínú ẹ̀mí ìgbéraga, tàbí kí ó máa “ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” Kò sídìí fáwọn Kristẹni láti máa ṣògo tàbí láti máa fi ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun yangàn yàtọ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ohun tó ti ṣe fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 4:6, 7; Róòmù 12:3) Wòlíì nì, Jeremáyà, fún wa ní ìlànà tó dáa láti tẹ̀ lé, ó ní: “Kí ẹni tí ń fọ́nnu nípa ara rẹ̀ fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí ohun yìí gan-an, níní tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye àti níní tí ó ní ìmọ̀ mi, pé èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé.”—Jeremáyà 9:24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

“Póòpù Innocent Kẹwàá,” látọwọ́ Don Diego Rodríguez de Silva Velázquez

[Credit Line]

Scala/Art Resource, NY

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́