ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 11/1 ojú ìwé 4-7
  • Ìṣọ̀kan Ayé—Báwo Ni Yóò Ṣe Wáyé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣọ̀kan Ayé—Báwo Ni Yóò Ṣe Wáyé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Jíjó ní Bèbè Ikú”
  • Ipá Láti Òde Ń Bẹ Lẹ́nu Iṣẹ́
  • Ìjọba Kan Ṣoṣo fún Gbogbo Ayé
  • Àwọn Ènìyàn Oníṣọ̀kan Láti Inú Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
  • Ibo Ni Ayé Yìí Ń lọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ǹjẹ́ Ayé Lè Ṣọ̀kan?
    Jí!—2000
  • “Àlàáfíà Kì Yóò Lópin”
    Jí!—2019
  • Ayé Máa Tó Di Párádísè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 11/1 ojú ìwé 4-7

Ìṣọ̀kan Ayé—Báwo Ni Yóò Ṣe Wáyé?

BÍ ILÉ ẹgẹrẹmìtì tí àwọn ayálégbé tí wọ́n jẹ́ aláìbìkítà ti bà jẹ́ gan-an, kìkì ohun kan ṣoṣo ni ó yẹ ètò ayé nǹkan ìsinsìnyí—kí a wó o palẹ̀, kí a sì fi òmíràn rọ́pò rẹ̀. Èyí kì í ṣe ojú ìwòye olùsàsọtẹ́lẹ̀ ibi rárá. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, ìyẹn nìkan ṣoṣo ni ojú ìwòye tòótọ́. Èé ṣe?

Àwọn ìpìlẹ̀ ètò ayé ìsinsìnyí ń mì. Ikán ti jẹ gbogbo ilé náà, igi rẹ̀ sì ti ju. Àwọn òpó irin rẹ̀ ti ń dípẹtà. Àwọn ògiri tí ó gbé e dúró ti lanu. Òrùlé rẹ̀ ti ń sẹ̀. Àwọn páìpù omi rẹ̀ ti ń jò. Ètò iná mànàmáná kò fi bẹ́ẹ̀ gbéṣẹ́ mọ́, ó sì léwu. Àwọn ayálégbé máa ń jà ṣáá, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú ba gbogbo inú ilé jẹ́. Gbogbo ilé náà àti àyíká rẹ̀ ni ìdun ti gbà kan, ibẹ̀ sí léwu gidigidi.

“Jíjó ní Bèbè Ikú”

Nítorí ìforígbárí ìṣèlú tí kò dáwọ́ dúró, ìwọra, ìgbógundìde, àti kèéta rírinlẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà àti ìran, “gbogbo ìran ẹ̀dá ènìyàn ń jó ní bèbè ikú,” gẹ́gẹ́ bí Gwynne Dyer ṣe sọ. Jákèjádò ayé, àwọn àwùjọ kéréje tí ọkàn wọ́n le—àwọn ẹgbẹ́ tí ń lo agbára lórí ìlànà ìjọba, àwọn ẹgbẹ́ ajàjàgbara, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn, àwọn akópayàbáni jákèjádò ayé, àti àwọn mìíràn—ń lépa àwọn ìwéwèé onímọtara-ẹni-nìkan wọn, tí ó sì dà bíi pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti dabarú ohunkóhun tí ó lè mú àlàáfíà wá nínú ayé nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́. Bí àwọn oníbàjẹ́ ayálégbé, wọ́n lè fi ayé sú gbogbo ènìyàn yòó kù.

Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé ti sọ, kì í ṣe àwọn ẹgbẹ́ ọlọ̀tẹ̀ tàbí àwọn ewèlè ẹ̀dá nìkan ní ń ṣèdíwọ́ fún ìṣọ̀kan ayé. Orílẹ̀-èdè tí ó dá dúró ni ìdènà gíga jù lọ. Òǹkọ̀wé lórí ọ̀ràn ogun S. B. Payne, Kékeré, sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dá dúró ń bẹ nínú “ipò rúdurùdu tí ó kárí ayé.” Wọ́n ń ṣe ohunkóhun tí ó bá jẹ́ fún ire orílẹ̀-èdè wọn jù lọ, láìka ipá tí ó ní lórí àwọn ẹlòmíràn sí. Nítorí èyí, jálẹ̀ ìtàn, “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.

Ní tòótọ́, àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan ti ṣàṣeyọrí dé ìwọ̀n kan ní gbígbógunti àìṣèdájọ́ òdodo àti ìnilára tí ń bẹ nínú ààlà ìpínlẹ̀ wọn àti, dé ìwọ̀n àyè kan, jákèjádò ayé. Wọ́n ti gbé ìṣọ̀kan jákèjádò ayé kalẹ̀ dé ìwọ̀n kan, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn kan tilẹ̀ pawọ́ pọ̀ láti fìyà jẹ orílẹ̀-èdè òfínràn kan, lọ́pọ̀ ìgbà, ìfura máa ń wà pé nítorí ire ti ara wọn ni wọ́n ṣe gbégbèésẹ̀ kì í ṣe nítorí ojúlówó àníyàn tí wọ́n ní fún àwọn ẹlòmíràn. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ìjọba ènìyàn kò ní ojútùú kíkún, tí ó wà pẹ́ títí sí àìṣọ̀kan ayé. Gwynne Dyer sọ pé: “Èrò náà pé gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò kóra jọ pọ̀ láti dí ìfínràn orílẹ̀-èdè aṣetinú-ẹni kan lọ́wọ́, tàbí láti fìyà jẹ ẹ́, dún dáradára létí, ṣùgbọ́n ta ni yóò sọ ìgbà tí orílẹ̀-èdè kan di òfínràn, ta ni yóò sì forí fá ìnáwó àti ìfẹ̀míṣòfò tí yóò bá a rìn kí ó tó ṣíwọ́?”

Dájúdájú, fífín tí orílẹ̀-èdè kan ń fín orílẹ̀-èdè míràn níràn yóò ṣẹlẹ̀ bí èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ kò bá ta ko ìfínràn náà. Ìtàn fi hàn lemọ́lemọ́ pé kì í ṣe ní kìkì “orílẹ̀-èdè aṣetinú-ẹni” nìkan ni àwọn aráàlú ti máa ń ti àwọn aṣáájú wọn lẹ́yìn, yálà wọ́n tọ̀nà tàbí wọn kò tọ̀nà. Ní ti gidi, èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn olùgbé ayé ni ó ti ṣe èyí. Wọ́n ti kù gbùù tẹ̀ lé “irọ́, ọ̀rọ̀ dídùn àti ìgbékèéyíde,” gẹ́gẹ́ bí èdè tí ìwé ìròyìn Time lò, tí ń wá láti ọ̀dọ̀ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú ìṣèlú àti ìsìn.

Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti ru ìgbónára àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùfòyebánilò àti oníyọ̀ọ́nú tẹ́lẹ̀ rí sókè, ó sì ti mú kí wọ́n hùwà búburú jáì sí àwọn ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé orílẹ̀-èdè míràn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí òpìtàn J. M. Roberts ń sọ nípa Ogun Àgbáyé Kìíní, ó sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ṣeni ní kàyéfì ní ọdún 1914 ni pé, lọ́nà tí ó yani lẹ́nu, ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ògìdìgbó àwọn ènìyàn, ti gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú, ìgbàgbọ́ àti ìran, jọ bí ẹni tí ó fi tinútinú àti tayọ̀tayọ̀ lọ sí ojú ogun.” Àwọn ènìyàn ha ti kọ́gbọ́n láti ìgbà náà wá bí? Rárá o! Ẹranko ẹhànnà “onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, tí ń fọ́ni lójú,” gẹ́gẹ́ bí orúkọ tí oníròyìn Rod Usher pè é, ń bá a lọ láti dabarú ọ̀nà èyíkéyìí láti mú ìṣọ̀kan ayé wá.

Ipá Láti Òde Ń Bẹ Lẹ́nu Iṣẹ́

Àmọ́ ṣáá o, ìdènà títóbi jù ń bẹ fún ìṣọ̀kan ayé. Bíbélì ṣí i payá pé àwọn ipá láti òde ń bẹ lẹ́nu iṣẹ́. A fi àwọn wọ̀nyí hàn gẹ́gẹ́ bíi Sátánì Èṣù àti àwọn dòǹgárì rẹ̀, àwọn ẹ̀mí èṣù. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, Sátánì ni “ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí [tí ó] ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú,” kí “ìhìn rere ológo nípa Kristi” má baà nípa kankan lórí wọn.—Kọ́ríńtì Kejì 4:4; Ìṣípayá 12:9.

Dájúdájú, èyí kò mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan mórí bọ́ nínú jíjíhìn àwọn ohun tí wọ́n ṣe. Ṣùgbọ́n, ó ṣàlàyé ìdí tí ìjọba ènìyàn kò fi lè gbé ayé tí ó ṣọ̀kan ní tòótọ́ kalẹ̀ láé. Bí Sátánì Èṣù bá ṣì ń bá a lọ láti wà, yóò máa nípa lórí àwọn ọkùnrin àti obìnrin láti mú ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara” dàgbà, títí kan ‘ìṣọ̀tá, gbọ́nmisi-omi-ò-to, asọ̀, àti ìpínyà.’—Gálátíà 5:19-21.

Ìjọba Kan Ṣoṣo fún Gbogbo Ayé

Kí wá ní ojútùú náà? Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún sẹ́yìn, ìlúmọ̀ọ́ká eléwì àti ọlọ́gbọ́n èrò orí ará Ítálì náà, Dante, sọ ìdáhùn náà. Ó jiyàn pé kìkì ìjọba kan ṣoṣo fún gbogbo ayé ni ó lè mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan aráyé dáni lójú. Fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ríretí irú ìjọba kan ṣoṣo fún gbogbo ayé bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀tàn pátápátá, kì í ṣe ohun tí a lè gbọ́kàn lé. Òǹṣèwé Payne, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, parí èrò sí pé: “Ìjọba kan ṣoṣo fún gbogbo ayé kò ṣeé ṣe rárá ní àkókò yí nínú ìtàn.” Èé ṣe? Nítorí ìjọba kan ṣoṣo fún gbogbo ayé tí yóò bá kẹ́sẹ járí ní láti fi ohun méjì tí ó jọ bíi pé ó kọjá agbára ènìyàn pátápátá dáni lójú, ìyẹn ni pé, “ìjọba kan ṣoṣo fún gbogbo ayé yóò mú òpin dé bá ogun àti pé ìjọba kan ṣoṣo fún gbogbo ayé kì yóò jẹ́ òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ kárí ayé.”

Ó dájú pé kò sí ìjọba ènìyàn kankan tí ó tó bẹ́ẹ̀ láéláé. Ṣùgbọ́n, Ìjọba Ọlọ́run ní ọwọ́ Jésù Kristi lè mú ogun kúrò, yóò sì mú un kúrò. (Orin Dáfídì 46:9, 10; Mátíù 6:10) Àní, yóò mú gbogbo àwọn arógunyọ̀ kúrò pàápàá. Wòlíì Dáníẹ́lì fi hàn pé ní òpin àkókò tí Ọlọ́run ti yàn kalẹ̀ fún àkóso ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, ìjọba ènìyàn yóò “yà sí ara rẹ̀” bí “irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀.” (Dáníẹ́lì 2:41-43) Èyí yóò yọrí sí ìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ ìṣèlú àti ìforígbárí tí a kò lè yẹ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, Dáníẹ́lì sọ pé Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba [onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti aláìṣọ̀kan] wọ̀nyí túútúú,” yóò sì fi Ìjọba rẹ̀ tí a ti ń retí tipẹ́, tí ó ti fi lé Jésù Kristi lọ́wọ́, rọ́pò rẹ̀.—Dáníẹ́lì 2:44, NW.

Kò ní sí ìdí kankan láti dá àyíká rèǹtè rente kan fún àwọn ènìyàn bí ó bá jẹ́ àwọn ènìyàn afiniṣèjẹ, tí ń bá a lọ láti mú ayé sú àwọn ẹlòmíràn, ní ń gbé inú ayé. Ṣùgbọ́n, “a óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò.” (Orin Dáfídì 37:1, 2, 9, 38; Òwe 2:22) Nítorí náà, Kristi yóò palẹ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kọ ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run sílẹ̀ tàbí tí wọ́n ti àwọn aláṣẹ ayé tí ó ń ṣèparun lẹ́yìn, mọ́. Yóò pa gbogbo àwọn tí ń ba pílánẹ́ẹ̀tì yí jẹ́ run. Ọlọ́run ṣèlérí “láti mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.”—Ìṣípayá 11:18.

Èyí kì yóò jẹ́ ìjọba òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ kan kárí ayé. Jésù Kristi yóò gbégbèésẹ̀ “nítorí òtítọ́ àti ìwà tútù àti òdodo,” nígbà tí ó bá ya àwọn ènìyàn rere kúrò lára àwọn ènìyàn búburú. (Orin Dáfídì 45:3, 4; Mátíù 25:31-33) Èyí kì í ṣe ìwà ìkà tí a pète láti fi pani run, àṣìlò agbára. Rárá o! Kì í ṣe bí ìgbà tí oníwọra akọ́létà kan bá fẹ́ wó ilé rèǹtè rente ìṣẹ̀ǹbáyé kan. Yóò dà bí ìgbà tí a bá wó ilé ẹgẹrẹmìtì hẹ́gẹhẹ̀gẹ kan láti mú àyíká tí ó mọ́ tónítóní, tí ó rí mèremère wá.

Ṣùgbọ́n, àwọn ipá láti òde, tí wọ́n ti fa àìsíṣọ̀kan ní àtẹ̀yìnwá ńkọ́? Wọn yóò ha lómìnira láti kó wọnú ètò ìgbékalẹ̀ tuntun yìí débi pé àwọn olùgbé rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ètò ìṣèparun náà lẹ́ẹ̀kan sí i, ní bíbá àwọn tí wọ́n jọ ń gbé jà, àti ní fífi ayé sú gbogbo ènìyàn bí? Rárá o. Ìmúkúrò àti àtúnṣe yí yóò jẹ́ àṣekágbá àti àṣetán. “Ìpọ́njú kì yóò dìde lẹ́rìnkejì.”—Náhúmù 1:9.

Bíbélì fi ìparun pátápátá Sátánì wé sísun pàǹtírí. Ó sọ pé “a . . . fi Èṣù tí ń ṣi [àwọn olùgbé ayé] lọ́nà sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́.” (Ìṣípayá 20:10) Ẹ wo irú ohun ìṣàpẹẹrẹ ńlá tí èyí jẹ́! Rò ó wò ná, kì í ṣe ilé ìsun-nǹkan-deérú kékeré tí kò lè gba nǹkan púpọ̀ ni a fi ìparun náà wé bí kò ṣe odindi adágún iná, tí ń jó gbogbo ohun tí ó jẹ́ ibi run, tí ó sì ń sọ ọ́ deérú. Kò sí ẹnikẹ́ni, ì báà jẹ́ ènìyàn tàbí ẹ̀mí èṣù, tí a óò yọ̀ǹda fún láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn nǹkan tí ń wu ìṣètò àgbáyé léwu, tí ń tẹ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run lójú ní ti ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, tàbí tí ń fa ìrora fún ọmọnìkejì wọn. Gbogbo olùba ìṣọ̀kan jẹ́ yóò ti pòórá!—Orin Dáfídì 21:9-11; Sefanáyà 1:18; 3:8.

Àwọn Ènìyàn Oníṣọ̀kan Láti Inú Gbogbo Orílẹ̀-Èdè

“Ogunlọ́gọ̀ ńlá kan . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ni yóò para pọ̀ jẹ́ àwọn tí yóò la ìfọ̀mọ́ yìí já. (Ìṣípayá 7:9) Ìyàtọ̀ nínú orílẹ̀-èdè wọn àti ẹ̀yà wọn kì yóò pín wọn níyà. Wọn yóò ti kọ́ láti gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan alálàáfíà. (Aísáyà 2:2-4) Ohun tí ó tún mú kí ó jẹ́ àgbàyanu ni pé, àwọn tí wọ́n ti gbé pílánẹ́ẹ̀tì yí rí, tí a óò mú pa dà bọ̀ láti gbé nínú ayé tí a ti wẹ̀ mọ́, nípasẹ̀ ìpèsè àgbàyanu ti àjíǹde, yóò dara pọ̀ mọ́ wọn.—Jòhánù 5:28, 29.

Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbé nínú irú ayé bẹ́ẹ̀ bí? Kìkì àwọn tí ó bá ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè ni yóò ṣe bẹ́ẹ̀, a sì kọ àwọn ohun tí ó ń béèrè sílẹ̀ kedere nínú Bíbélì. (Jòhánù 17:3; Ìṣe 2:38-42) Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè, kí o baà lè ní ìrètí gbígbádùn ìwàláàyè títí láé nínú ayé tí ó wà níṣọ̀kan ní tòótọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìjọba lọ́wọ́ Jésù Kristi yóò mú ayé oníṣọ̀kan dájú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́