ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 9/1 ojú ìwé 24-28
  • Mo Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìdánwò Lílekoko
  • Ọ̀ràn Ìjuwọ́sílẹ̀
  • Inúnibíni Ń Le sí I
  • Lílọ sí Ìlà Oòrùn—àti Sísálà
  • A Lómìnira, Ṣùgbọ́n Ìbànújẹ́ Wà sí I
  • Òmìnira Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
  • Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia
    Jí!—2003
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
  • Ìṣàkóso Ọlọ́run Làwá Fara Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 9/1 ojú ìwé 24-28

Mo Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

GẸ́GẸ́ BÍ JÁN KORPA-ONDO ṢE SỌ Ọ́

Ọdún 1942 ni, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Hungary ló ń ṣọ́ mi nítòsí Kursk, Rọ́ṣíà. A jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ àwọn ológun Alájọṣe tí ń bá Rọ́ṣíà jà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Wọ́n gbẹ́ sàréè fún mi, wọ́n sì fún mi ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá kí n fi pinnu bóyá n ó fọwọ́ síwèé tó sọ pé n kì í ṣe ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Kí n tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe débẹ̀ fún yín.

ABÍ mi ní 1904, ní abúlé kékeré tí ń jẹ́ Zahor, tó wà ní ìhà ìlà oòrùn Slovakia nísinsìnyí. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, Zahor di apá kan orílẹ̀-èdè Czechoslovakia tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Abúlé wa ní nǹkan bí 200 ilé àti ṣọ́ọ̀ṣì méjì, ọ̀kan ti Kátólíìkì ilẹ̀ Gíríìkì, èkejì sì jẹ́ ti àwọn ọmọlẹ́yìn Calvin.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń lọ sí Ìjọ Ọmọlẹ́yìn Calvin, mo ń gbé ìgbésí ayé tí kò bá ìlànà ìwà rere mu. Ọkùnrin kan tó ń gbé ìtòsí mi yàtọ̀ pátápátá. Lọ́jọ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá mi jíròrò, ó sì yá mi ní Bíbélì kan. Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí n óò fọwọ́ kan ìwé yẹn. Ní nǹkan bí àkókò yìí, ní 1926, mo gbé Barbora níyàwó, láìpẹ́, a bí ọmọ méjì, Barbora àti Ján.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì náà, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni ohun tí kò yé mi níbẹ̀. Nítorí náà, mo lọ bá pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì mi pé kí ó ràn mí lọ́wọ́. Ó wí pé: “Àwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ni Bíbélì wà fún, má wulẹ̀ gbìyànjú láti lóye rẹ̀.” Ó wá pè mí pé ká jọ máa ta káàdì.

Lẹ́yìn náà, mo lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin tó yá mi ní Bíbélì náà. Ó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Ó láyọ̀ láti ràn mí lọ́wọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí lóye òtítọ́ láìpẹ́. Mo ṣíwọ́ ọtí àmujù, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé oníwà rere; mo tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Òtítọ́ Bíbélì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní Zahor níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920, ní kété tí wọ́n ti dá àwùjọ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara kan sílẹ̀ níbẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, àtakò ìsìn gbígbónájanjan ṣẹlẹ̀. Àlùfáà àdúgbò mú kí ọ̀pọ̀ ju lọ àwọn ẹbí mi lòdì sí mi, tí wọ́n ń sọ pé orí mi ti yí. Àmọ́ ìgbésí ayé mi bẹ̀rẹ̀ sí ní ète nínú, mo sì pinnu pátápátá láti sin Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà. Nítorí náà, ní 1930, mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe batisí.

Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìdánwò Lílekoko

Ní 1938, àgbègbè wa bọ́ sábẹ́ àkóso ilẹ̀ Hungary, tó fara mọ́ Germany nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà yẹn, nǹkan bí 50 Ẹlẹ́rìí ló wà ní abúlé wa tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ kò pé ẹgbẹ̀rún kan. A ń wàásù nìṣó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń wu ẹ̀mí wa àti òmìnira wa léwu.

Ní 1940, wọ́n fipá forúkọ mi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun ti ilẹ̀ Hungary. Kí ni kí n ṣe? Mo ti ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì nípa àwọn ènìyàn tí ń sọ àwọn ohun ìjà wọn di àwọn ohun èlò àlàáfíà, mo sì mọ̀ pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò mú kí ogun kásẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 46:9; Aísáyà 2:4) Ìyẹn ti mú kí n kórìíra ogun, mo sì pinnu láti má wọ ẹgbẹ́ ọmọ ológun kankan, láìka ohun tó lè tìdí rẹ̀ jáde sí.

Wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n oṣù 14, mo sì ṣe ẹ̀wọ̀n mi ní Pécs, Hungary. Àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún mìíràn wà lẹ́wọ̀n kan náà tí mo wà, a sì mọrírì pé a láǹfààní láti kẹ́gbẹ́ pọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, fún ìwọ̀n àkókò kan, wọ́n fi mí sí àhámọ́ aládàágbé, wọ́n sì kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀. Wọ́n lù wá nígbà tí a kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ tó bá ti jẹ ìtìlẹ́yìn fún ogun náà. Bákan náà ni wọ́n fipá mú wa gan sóòró bí ológun látàárọ̀ ṣúlẹ̀, àyàfi ní wákàtí méjì péré, lọ́sàn-án. Ìdánwò ńlá yìí ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Síbẹ̀, a láyọ̀, nítorí pé, a ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run wa.

Ọ̀ràn Ìjuwọ́sílẹ̀

Lọ́jọ́ kan, àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì 15 wá láti gbìyànjú láti yí wa lérò padà pé, ó ṣe pàtàkì fún wa láti ṣètìlẹyìn fún ogun náà nípa dídi ọmọ ogun. Nígbà ìjíròrò náà, a wí pé: “Bí ẹ bá lè fi ẹ̀rí hàn wá láti inú Bíbélì pé ọkàn kò lè kú àti pé ọ̀run la ó lọ bí a bá kú sínú ogun náà, a ó di ọmọ ogun.” Bí a ti lè retí, wọn kò lè fi ẹ̀rí ìyẹn hàn, wọ́n sì jáwọ́ lára ìjíròrò náà.

Ní 1941, mo parí ẹ̀wọ̀n mi, mo sì ń retí láti tún dara pọ̀ mọ́ ìdílé mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dè mí tọwọ́tẹsẹ̀ lọ sí ibùdó ológun kan ní Sárospatak, Hungary. Nígbà tí a débẹ̀, wọ́n fún mi láǹfààní kan láti gba ìtúsílẹ̀. Wọ́n sọ fún mi pé: “Gbogbo ohun tí o ní láti ṣe ni kí o fọwọ́ sí ìlérí yìí pé bí o bá padà délé, wàá san 200 pengö.”

Mo béèrè pé: “Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Kí lẹ fẹ́ fi owó yẹn ṣe?”

Wọ́n sọ fún mi pé: “Bí o bá san owó yẹn, a óò fún ọ ní ìwé ẹ̀rí pé o kò yege nínú àyẹ̀wò ìlera àwọn ọmọ ogun.”

Èyí gbé ìpinnu tó ṣòro kan ka iwájú mi. Ó ti lé ní ọdún kan tí wọ́n ti ń hùwà ìkà sí mi; ó sì ti ń sú mi. Nísinsìnyí, bí mo bá gbà láti san iye owó kan, wọ́n lè tú mi sílẹ̀. Mo sọ pé: “N ó ronú lé e lórí.”

Ìpinnu wo ni kí n wá ṣe? Ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi wà níbẹ̀ láti ronú lé. Ní àkókò yẹn gan-an ni mo gba lẹ́tà kan tí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi kan fi fún mi níṣìírí. Ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Hébérù 10:38, níbi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti wí pé, Jèhófà sọ pé: “‘Olódodo mi yóò yè nítorí ìgbàgbọ́,’ àti pé, ‘bí ó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní ìdùnnú nínú rẹ̀.’” Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn ológun Hungary méjì ní bárékè náà bá mi sọ̀rọ̀, ọ̀kan sì sọ pé: “O kò mọ bí a ti bọ̀wọ̀ fún ọ tó nítorí bí o ṣe rọ̀ pinpin mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì! Má juwọ́ sílẹ̀!”

Lọ́jọ́ kejì, mo lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fi òmìnira lọ̀ mí fún 200 pengö, mo sì sọ pé: “Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti yọ̀ǹda kí ẹ fi mí sẹ́wọ̀n, yóò tún rí sí ìtúsílẹ̀ mi. N kò ní fowó rà á.” Nítorí náà, wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Àmọ́ ìyẹn kọ́ ni òpin àwọn ìgbìdánwò láti mú kí n juwọ́ sílẹ̀. Ilé ẹjọ́ gbà láti dá mi sílẹ̀ bí mo bá ṣáà ti lè gbà láti ṣe oṣù méjì péré nínú iṣẹ́ ológun, n kò sì tilẹ̀ ní gbé ohun ìjà kankan! Mo kọ ìfilọni yẹn náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀wọ̀n.

Inúnibíni Ń Le sí I

Wọ́n gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Pécs. Lọ́tẹ̀ yìí, ìdálóró náà tilẹ̀ le sí i ni. Wọ́n di ọwọ́ mi sẹ́yìn, wọ́n sì fi so mí rọ̀ fún nǹkan bí wákàtí méjì. Èyí mú kí èjìká mi méjèèjì yẹ̀. Wọ́n ń fún mi ní irú ìdálóró bẹ́ẹ̀ léraléra fún bí oṣù mẹ́fà. Jèhófà nìkan ló ni ọpẹ́ pé n kò kú.

Ní 1942, wọ́n kó àwa kan—ẹlẹ́wọ̀n òṣèlú, àwọn Júù, àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà 26—lọ sí ìlú Kursk ní àgbègbè tí àwọn ọmọ ogun Germany wà. Wọ́n kó wa fún àwọn ará Germany, wọ́n sì yan àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà láti máa bá àwọn jagunjagun náà kó oúnjẹ, ohun ìjà, àti aṣọ lọ sí ojú ogun. Àwa Ẹlẹ́rìí kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà nítorí pé yóò ba àìdásí tọ̀tún tòsì Kristẹni wa jẹ́. Nítorí náà, wọ́n dá wa padà fún àwọn ará Hungary.

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n kó wa sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Kursk. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ kọjá, tí wọ́n ń fi rọ́bà lù wá lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́. Wọ́n gbá mi lẹ́ṣẹ̀ẹ́ ní gògóńgò, mo sì ṣubú lulẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń lù mí, mo ronú pé, ‘Ikú gan-an kò nira tó báyìí.’ Gbogbo ara mi ti kú, nítorí náà, n kò nímọ̀lára kankan. Ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi fún wa lóúnjẹ. Wọ́n wá kó wa lọ sílé ẹjọ́, wọ́n sì dájọ́ ikú fún mẹ́fà nínú wa. Nígbà tí wọ́n pa àwọn yẹn, a ṣẹ́ ku 20.

N kò rí ìdánwò ìgbàgbọ́ tó nira tó àwọn tí mo rí ní Kursk ní October 1942 rí. Ìmọ̀lára wa rí bí èyí tí Jèhóṣáfátì Ọba ìgbàanì sọ, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ kojú ìṣòro kíkàmàmà, pé: “Kò sí agbára kankan nínú wa níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí tí ń bọ̀ wá gbéjà kò wá; àwa alára kò sì mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.”—2 Kíróníkà 20:12.

Wọ́n kó àwa 20 tí àwọn ọmọ ogun ará Hungary 18 ń ṣọ́ lọ síbi tí a ti gbẹ́ sàréè tí wọn yóò sin wá sí lápapọ̀. Nígbà tí a gbẹ́ sàréè náà tán, wọ́n sọ fún wa pé, àwọn fún wa ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá láti fọwọ́ sí àkọsílẹ̀ kan, tó kà lápá kan pé: “Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tọ̀nà. N kò ní gbà á gbọ́ tàbí tì í lẹ́yìn mọ́. N ó jà fún ilẹ̀ ìbí Hungary . . . Mo sì fi ìfọwọ́sí yìí sọ pé mo dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Roman Kátólíìkì.”

Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́wàá, wọ́n pàṣẹ pé: “Ẹ yí sápá ọ̀tún! Ẹ máa yan lọ síbi sàréè náà!” Wọ́n tún pàṣẹ pé: “Kí ẹlẹ́wọ̀n kìíní àti ìkẹta bọ́ sínú ihò!” Wọ́n fún àwọn méjèèjì ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá mìíràn láti pinnu láti fọwọ́ sí ìwé náà. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Ẹ jáwọ́ nínú ẹ̀sìn yin, kí ẹ sì jáde kúrò nínú sàréè!” Kẹ́kẹ́ pa. Ọ̀gá ológun náà wá yìnbọn pa àwọn méjèèjì.

Ọmọ ogun kan bi ọ̀gá ológun náà léèrè pé: “Àwọn tó kù ń kọ́?”

Ó dáhùn pé: “Ẹ dè wọ́n. A ó jẹ wọ́n níyà díẹ̀ sí i, a ó sì wá yìnbọn pa wọ́n láago mẹ́fà àárọ̀.”

Lójijì, ẹ̀rù bà mí, kì í ṣe ìbẹ̀rù ti ikú, ṣùgbọ́n ti pé bóyá n kò ní lè fara da ìjìyà náà, kí n sì wá juwọ́ sílẹ̀. Nítorí náà, mo bọ́ síwájú, mo sì wí pé: “Ọ̀gá, ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ni àwa àti àwọn arákùnrin wa tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ yìnbọn pa tán ṣẹ̀. Ẹ kò ṣe kúkú yìnbọn pa àwa náà lẹ́ẹ̀kan?”

Ṣùgbọ́n wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n dè wá lọ́wọ́ sẹ́yìn. Wọ́n wá fi ìyẹn so wá rọ̀. Nígbà tí a bá dákú, wọn á rọ́ omi sí wa lórí. Ìrora náà pọ̀ gan-an nítorí pé bí ara wa ṣe wúwo mú kí a yẹ̀ léjìká. Wọ́n ń dá wa lóró báyìí fún bí wákàtí mẹ́ta. Lójijì, àṣẹ dé pé wọn kò gbọ́dọ̀ yìnbọn fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan mọ́.

Lílọ sí Ìlà Oòrùn—àti Sísálà

Lọ́sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n tò wá, a sì fi ọjọ́ mélòó kan yan títí a fi dé etí Odò Don. Àwọn tí a fà wá lé lọ́wọ́ ṣàlàyé pé, a kò retí kí àwọn kó wa padà láàyè. Lọ́sàn-án, àwọn iṣẹ́ tí kò nítumọ̀ ni wọ́n ń fún wa ṣe, bí a ti ń gbẹ́ kòtò la ń dí wọn padà. Nírọ̀lẹ́, wọ́n ń fún wa lómìnira díẹ̀ láti rìn kiri.

Lójú mi, ohun méjì ló lè ṣẹlẹ̀. A lè kú síbẹ̀, a sì lè sá lọ mọ́ àwọn ará Germany lọ́wọ́, kí a sì fi ara wa lé àwọn ara Rọ́ṣíà lọ́wọ́. Àwa mẹ́ta péré ni a pinnu láti gbìyànjú, kí a sá ré kọjá Odò Don olómi dídì náà. Ní December 12, 1942, a gbàdúrà sí Jèhófà, a sì gbéra. A wọ ilẹ̀ àwọn ará Rọ́ṣíà, wọ́n mú wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì sọ wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó ní nǹkan bí 35,000 ẹlẹ́wọ̀n nínú. Nígbà ti ó fi di ìgbà ìrúwé, nǹkan bí 2,300 ẹlẹ́wọ̀n péré ni kò ì kú. Ebi ti pa àwọn tó kù kú fin-ínfin-ín.

A Lómìnira, Ṣùgbọ́n Ìbànújẹ́ Wà sí I

Mo jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ àwọn ará Rọ́ṣíà títí ogun náà fi parí àti títí oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà. Níkẹyìn, ní November 1945, mo délé ní Zahor. Oko wa ti di ìgbòrò, nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun ni. Ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi ti ń ṣiṣẹ́ lóko náà nígbà tí ogun ń lọ lọ́wọ́, àmọ́, bí àwọn ará Rọ́ṣíà ti ń kógun sún mọ́ ní October 1944, wọ́n kó wọn lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Gbogbo ohun tí a ní ni wọ́n ti jí kó tán.

Èyí tó burú jù ni pé, nígbà tí mo fi padà délé, ara ìyàwó mi kò yá rárá. Ó kú ní February 1946. Ọmọ ọdún 38 péré ni. A kò ní àkókò púpọ̀ láti fi gbádùn àtúnríra wa lẹ́yìn èyí tó lé lọ́dún márùn-ún, tó nira gan-an, tí a ti ya ara wa.

Wíwà láàárín àwọn arákùnrin mi tẹ̀mí, lílọ sí àwọn ìpàdé àti kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé tù mí nínú. Ní 1947, ó ṣeé ṣe fún mi láti yá owó díẹ̀ láti lọ sí àpéjọpọ̀ kan ní Brno, ìrìn àjò nǹkan bí 400 kìlómítà. Mo rí ìtùnú àti ìṣírí gbà níbẹ̀ gan-an láàárín àwọn Kristẹni arákùnrin mi, títí kan Nathan H. Knorr, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà.

A kò gbádùn òmìnira ẹ̀yìn ogun náà pẹ́ títí. Ní 1948, àwọn Kọ́múníìsì bẹ̀rẹ̀ sí pọ́n wa lójú. Wọ́n mú ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin tí ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Czechoslovakia, ní 1952, wọ́n sì fún mi ní ẹrù iṣẹ́ bíbójútó àwọn ìjọ. Ní 1954, wọ́n mú èmi náà, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin. Wọ́n sọ ọmọkùnrin mi, Ján, àti ọmọkùnrin rẹ̀, Juraj, sẹ́wọ̀n pẹ̀lú, nítorí tí wọ́n di àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni wọn mú. Mo lo ọdún méjì ní ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ti Pankrác, ní Prague. Wọ́n kéde ìdáríjì kan ní 1956, wọ́n sì dá mi sílẹ̀.

Òmìnira Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Níkẹyìn, ní 1989, ètò ìjọba Kọ́múníìsì forí ṣánpọ́n ní Czechoslovakia, a sì fi òfin ti iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn. Nípa bẹ́ẹ̀, a lómìnira láti máa pàdé pọ̀, kí a sì máa wàásù ní gbangba. Nígbà yẹn, Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Zahor ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún, tó túmọ̀ sí pé, nǹkan bí ẹni kan nínú ẹni 10 lábúlé náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba fífẹ̀ kan, tó jojú ní gbèsè, tó sì lè gba 200 ènìyàn, ní Zahor.

Ara mi kò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́, nítorí náà, àwọn ará máa ń fọkọ̀ gbé mi lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Inú mi máa ń dùn láti wà níbẹ̀, mo sì ń gbádùn lílóhùnsí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ní pàtàkì, inú mi ń dùn bí mo ti ń rí àwọn aṣojú ìran mẹ́ta nínú ìdílé mi, tí wọ́n ń sin Jèhófà, títí kan púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ọmọ mi. Ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ti jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Czechoslovakia, títí di ìgbà tí ẹrù iṣẹ́ bíbójútó ìdílé rẹ̀ kò jẹ́ kí ó lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí bí ó ṣe fún mi lókun ní ọ̀pọ̀ àkókò ìdánwò tí mo dojú kọ. Pípa ọkàn mi pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀—“bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí”—ni ohun tó ti mú mi dúró. (Hébérù 11:27) Ní gidi, mo mọ ọwọ́ ìdáǹdè rẹ̀ lílágbára lára. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, nísinsìnyí pàápàá, mo ń gbìyànjú wíwà ní àwọn ìpàdé ìjọ, kí n sì kópa nínú pípolongo orúkọ rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní gbangba, bí mo ti lè ṣe tó.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Zahor

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mo mọrírì àǹfààní lílóhùnsí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́