ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bh ojú ìwé 199-ojú ìwé 201 ìpínrọ̀ 4
  • Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
  • Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Fẹ̀rí Hàn Pé Jésù Ni Mèsáyà Náà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Mèsáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Wọ́n Retí Mèsáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jesu Kristi Kọ́kọ́rọ́ Náà Sí Ìmọ̀ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
bh ojú ìwé 199-ojú ìwé 201 ìpínrọ̀ 4

ÀFIKÚN

Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

JÈHÓFÀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè dá Mèsáyà tó ṣèlérí pé yóò jẹ́ Olùdáǹdè mọ̀. Bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní pé ó mí sí àwọn wòlíì rẹ̀ pé kí wọ́n sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí Mèsáyà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àti ikú rẹ̀. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tá a rí nínú Bíbélì ló ṣẹ sára Jésù Kristi, kò já létí; bí wọ́n sì ṣe sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ṣe ṣẹ ni wọ́n ṣe ṣẹ. Kó o lè mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ mélòó kan tó sọ nípa ìbí Jésù àti nípa ìgbà tó wà ní kékeré.

Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì. (Aísáyà 9:7) Inú ìran ìdílé Dáfídì ni wọ́n sì bí Jésù sí lóòótọ́.—Mátíù 1:1, 6-17.

Wólìí Ọlọ́run mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni wọn yóò bí ọmọ yìí sí ó sì tún sọ pé yóò di olùṣàkóso lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. (Míkà 5:2) Lákòókò tí wọ́n bí Jésù, ìlú méjì ni wọ́n ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ọ̀kan wà nítòsí ìlú Násárétì tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, èkejì sì wà nítòsí Jerúsálẹ́mù ní Júdà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Éfúrátà ni wọ́n ń pe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù. Bí àsọtẹ́lẹ̀ Míkà sì ṣe sọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù yìí ni wọ́n bí Jésù sí!—Mátíù 2:1.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé Ọlọ́run yóò pe Ọmọ rẹ̀ “láti Íjíbítì.” Nígbà tí Jésù wà ní kékeré, wọ́n gbé e lọ́ sí Íjíbítì. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọba Hẹ́rọ́dù kú, wọ́n gbé Jésù padà láti Íjíbítì. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ nìyẹn.—Hóséà 11:1; Mátíù 2:15.

Nínú àtẹ ìsọfúnnni tá a pe àkọ́lé rẹ̀ ní “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà,” a to àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà sábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Àsọtẹ́lẹ̀.” Jọ̀wọ́ fi àwọn ẹsẹ Bíbélì náà wé àwọn èyí tá a tò sábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Ìmúṣẹ.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tó o ní, pé òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò lágbára sí i.

Bó o ṣe ń gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí yẹ̀ wò, fi sọ́kàn pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù ni wọ́n ti kọ àwọn tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.” (Lúùkù 24:44) Bí ìwọ náà ṣe rí i kà nínú Bíbélì, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa Mèsáyà ló nímùúṣẹ, kò já létí!

ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÍPA MÈSÁYÀ

ÌṢẸ̀LẸ̀

ÀSỌTẸ́LẸ̀

ÌMÚṢẸ

Ẹ̀yà Júdà ni wọn ti bí i

Jẹ́nẹ́sísì 49:10

Lúùkù 3:23-33

Wúńdíá ló bí i

Aísáyà 7:14

Mátíù 1:18-25

Àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì ni

Aísáyà 9:7

Mátíù 1:1, 6-17

Jèhófà kéde pé Ọmọ òun ni

Sáàmù 2:7

Mátíù 3:17

Ọ̀pọ̀ ni kò gbà á gbọ́

Aísáyà 53:1

Jòhánù 12:37, 38

Ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù

Sekaráyà 9:9

Mátíù 21:1-9

Ẹni tó sún mọ́ ọn dáadáa ló dà á

Sáàmù 41:9

Jòhánù 13:18, 21-30

Ọgbọ̀n owó fàdákà lẹni tó dà á gbà

Sekaráyà 11:12

Mátíù 26:14-16

Kò dá àwọn tó fẹ̀sùn kàn án lóhùn

Aísáyà 53:7

Mátíù 27:11-14

Wọ́n ṣẹ́ kèké lé ẹ̀wù rẹ̀

Sáàmù 22:18

Mátíù 27:35

Wọ́n fi í ṣẹ̀sín nígbà tó wà lórí òpó igi

Sáàmù 22:7, 8

Mátíù 27:39-43

Wọn kò ṣẹ́ egungun rẹ̀ kankan

Sáàmù 34:20

Jòhánù 19:33, 36

Wọ́n sin ín pọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́rọ̀

Aísáyà 53:9

Mátíù 27:57-60

Ẹran ara rẹ̀ kò jẹrà tó fi jíǹde

Sáàmù 16:10

Ìṣe 2:24, 27

Ọlọ́run gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀

Sáàmù 110:1

Ìṣe 7:56

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́