ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 8/1 ojú ìwé 20-25
  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Kọ́ Mi Láti Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà
  • Inúnibíni Náà Le Koko Sí I
  • Àkókò Ráńpẹ́ Tí Ó Kún fún Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí Àfìtaraṣe
  • Ìtìlẹ́yìn Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Arákùnrin Mi Nípa Tẹ̀mí
  • Jèhófà Dá Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Adúróṣinṣin Nídè
  • Kí Ni Mo Lè San Pa Dà Fún Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Mo Gbọ́kàn Lé Jèhófà Pé Á Bójú Tó Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́
    Jí!—1998
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 8/1 ojú ìwé 20-25

Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi

GẸ́GẸ́ BÍ RUDOLF GRAICHEN ṢE SỌ Ọ́

Gẹ́gẹ́ bíi mànàmáná tí ń kọ mọ̀nà, ọ̀ràn ìbànújẹ́ dé bá ìdílé mi nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 12 péré. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ju bàbá mi sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi agbára mú èmi àti ìbejì mi kúrò nílé, wọ́n sì mú wa lọ gbé pẹ̀lú àwọn àjèjì. Lẹ́yìn náà, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fi àṣẹ ọba mú èmi àti ìyá mi. Mo lọ sẹ́wọ̀n, òun sì bá ara rẹ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

ÀWỌN ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀léra yẹn wulẹ̀ sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ àkókò onínúnibíni afàrora tí mo jìyà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà tí mo wà léwe. Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Nazi olórúkọ burúkú, àti lẹ́yìn náà, Stasi Ìlà Oòrùn Germany gbìyànjú láti ba ìwà títọ́ mi sí Ọlọ́run jẹ́. Nísinsìnyí, lẹ́yìn 50 ọdún iṣẹ́ ìsìn oníyàsímímọ́ sí i, mo lè sọ bí onísáàmù náà ti sọ pé: “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá: síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.” (Orin Dáfídì 129:2) Ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ tó fún Jèhófà!

A bí mi ní June 2, 1925, ní ìletò Lucka, nítòsí Leipzig ní Germany. Kí a tilẹ̀ tó bí mi, àwọn òbí mi, Alfred àti Teresa, ti rí ẹ̀rí ìdánilójú òtítọ́ Bíbélì nínú àwọn ìtẹ̀jáde àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà lọ́hùn-ún. Mo rántí pé mo máa ń wo àwòrán ìràn Bíbélì, tí a fi kọ́ ara ògiri nínú ilé wa lójoojúmọ́. Àwòrán kan fi ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ọmọ ewúrẹ́ àti àmọ̀tẹ́kùn, ọmọ màlúù àti kìnnìún hàn—tí gbogbo wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, tí ọmọdékùnrin kékeré kan sì ń dà wọ́n. (Aísáyà 11:6-9) Irú àwòrán bẹ́ẹ̀ ṣì wà lọ́kàn mi títí di òní olónìí.

Nígbàkigbà tí ó bá ṣeé ṣe, àwọn òbí mi máa ń fi mí kún àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Fún àpẹẹrẹ, ní February 1933, ọjọ́ díẹ̀ péré lẹ́yìn tí Hitler gba ìjọba, wọ́n fi “Photo-Drama of Creation” (Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá)—pẹ̀lú àwòrán ara ògiri, àwòrán tí ń rìn, àti ìgbohùnsílẹ̀ tí ń ṣàlàyé ìran náà—hàn ní ìletò wa. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó, ọmọdékùnrin ọlọ́dún méje péré, láti wà lẹ́yìn ọkọ̀ akẹ́rù tí ń lọ káàkiri ìlú gẹ́gẹ́ bí ara ìpolówó sinimá “Photo-Drama”! Ní àkókò yí àti ní àwọn àkókò míràn, àwọn ará mú kí n nímọ̀lára pé mo jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ tí ó wúlò, láìka pé mo jẹ́ ọmọdé sí. Nítorí náà, láti ìgbà kékeré, Jèhófà kọ́ mi, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì nípa lórí mi.

A Kọ́ Mi Láti Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà

Nítorí àìdásí tọ̀tún tòsì Kristẹni tí a dì mú, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ nínú ìṣèlú Nazi. Nítorí èyí, ní 1933, ìjọba Nazi ṣòfin tí ó ka wíwàásù, lílọ sí ìpàdé, àti kíka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa pàápàá léèwọ̀. Ní September 1937, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fi àṣẹ ọba mú gbogbo arákùnrin tí ó wà nínú ìjọ wa, títí kan bàbá mi. Ìyẹn bà mí nínú jẹ́ púpọ̀. A rán bàbá mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún.

Nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í nira fún wa nílé. Ṣùgbọ́n, kíá ni a kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí mo darí dé láti ilé ẹ̀kọ́, màmá mi ń ka Ilé Ìṣọ́. Ó fẹ́ sáré se oúnjẹ fún mi, nítorí náà, ó fi ìwé ìròyìn náà lé orí kọ́bọ́ọ̀dù kékeré kan. Lẹ́yìn tí a jẹun tán, bí a ti ń palẹ̀ mọ́, a gbọ́ tí ẹnì kan ń kan ilẹ̀kùn gbàgbàgbà. Ọlọ́pàá tí ó fẹ́ tú ilé wa láti wá àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni. Ẹ̀rù bà mí gidigidi.

Oòrùn ọjọ́ yẹn ga. Nítorí náà, ohun àkọ́kọ́ tí ọlọ́pàá náà ṣe ni láti ṣí akoto rẹ̀, ó sì fi lé orí tábìlì kan. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í túlé kiri. Bí ó ti ń wo abẹ́ tábìlì, akoto rẹ̀ fẹ́ ré bọ́. Nítorí náà, màmá mi sáré gbá akoto náà mú, ó sì fi lórí kọ́bọ́ọ̀dù, lórí Ilé Ìṣọ́ náà gan-an! Ọlọ́pàá náà wá gbogbo inú ilé wa látòkè délẹ̀, ṣùgbọ́n kò rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí. Dájúdájú, kò sọ sí i lọ́kàn láti wo abẹ́ akoto rẹ̀. Nígbà tí ó ṣe tán àti máa lọ, ó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ìyá mi bí ó ti ń nawọ́ sẹ́yìn mú akoto rẹ̀. Ẹ wo bí ará ti tù mí tó!

Àwọn ìrírí bí irú ìyẹn mú mi gbára dì fún àwọn àdánwò tí ó túbọ̀ le koko. Fún àpẹẹrẹ, ní ilé ẹ̀kọ́, wọ́n fòòró ẹ̀mí mi láti dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Èwe Hitler, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ọmọdé ní ìlànà iṣẹ́ ológun, tí wọ́n sì ń fi ọgbọ́n èrò orí ìjọba Nazi kọ́ wọn. Àwọn olùkọ́ kan gbé góńgó ara ẹni kalẹ̀ láti rí i pé gbogbo àkẹ́kọ̀ọ́ wọn pátá ni ó kópa. Olùkọ́ mi, Herr Schneider, ti ní láti ronú pé aláìlèṣàṣeyọrí ni òun, nítorí pé, láìdà bí àwọn olùkọ́ yòó kù ní ilé ẹ̀kọ́ mi, akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kan kò kópa. Èmi sì ni akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ní ọjọ́ kan, Herr Schneider polongo fún gbogbo kíláàsì pé: “Ẹ̀yin ọmọ, gbogbo kíláàsì wa yóò ròde lọ́la.” Gbogbo wa pátá ni ó nífẹ̀ẹ́ sí èrò náà. Àmọ́, ó fi kún un pé: “Kí gbogbo yín wọ aṣọ Èwe Hitler yín, kí gbogbo ènìyàn lè rí i pé ọmọ dáradára ọmọ Hitler ni yín, nígbà tí a bá ń yan bí ológun káàkiri lópòópónà.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, gbogbo àwọn ọmọdékùnrin náà ni wọ́n wọ aṣọ ẹgbẹ́ wọn wá, àfi èmi nìkan. Olùkọ́ náà pè mí sí iwájú kíláàsì, ó sì bi mí pé: “Wo gbogbo àwọn ọmọ yòó kù, kí o sì wo ara rẹ.” Ó fi kún un pé: “Mo mọ̀ pé àwọn òbí rẹ kò ní lọ́wọ́, wọn kò sì lágbára àtira aṣọ ẹgbẹ́ fún ọ, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n fi ohun kan hàn ọ́.” Ó mú mi lọ sí àyè rẹ̀, ó ṣí dúrọ́ọ̀ kan, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ fún ọ ní aṣọ tuntun yìí. Kò ha dára bí?”

Èmi yóò yàn láti kú ju láti gbé ẹ̀wù ìjọba Nazi wọ̀ lọ. Nígbà tí olùkọ́ mi rí i pé n kò ní in lọ́kàn láti wọ̀ ọ́, inú bí i, gbogbo kíláàsì sì hó yèè lé mi lórí. Lẹ́yìn náà, ó mú wa ròde náà, ṣùgbọ́n ó gbìyànjú láti fi mí pa mọ́ nípa mímú kí n rìn ní àárín gbogbo àwọn ọmọdékùnrin yòó kù, tí wọ́n wọ aṣọ ẹgbẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú lè rí mi, bí mo ti dá yàtọ̀ pátápátá láàárín àwọn ọmọ kíláàsì mi. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ pé èmi àti àwọn òbí mi jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún fífún mi ní okun tẹ̀mí tí mo nílò nígbà tí mo wà ní kékeré.

Inúnibíni Náà Le Koko Sí I

Ní ọjọ́ kan ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1938, wọ́n mú èmi àti ìbejì mi láti ilé ẹ̀kọ́, wọ́n sì fi ọkọ̀ ọlọ́pàá gbé wa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ atúnwà-ẹni-ṣe ní Stadtroda, nǹkan bí 80 kìlómítà sílé. Èé ṣe? Ilé ẹjọ́ ti pinnu pé kí wọ́n mú wa kúrò ní ibi tí àwọn òbí wa ti lè nípa lórí wa, kí wọ́n sì sọ wá di ọmọ ìjọba Nazi. Kò pẹ́ tí ẹni tí ń bójú tó ilé ẹ̀kọ́ náà fi kíyè sí i pé èmi àti ìbejì mi jẹ́ onígbọràn ọmọ, tí ń bọ̀wọ̀ fúnni, bí a tilẹ̀ dúró gbọn-in nínú àìdásí tọ̀tún tòsì Kristẹni wa. Orí olùdarí náà wú tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ láti rí màmá mi sójú. Wọ́n fúnni ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan, wọ́n sì yọ̀ǹda fún ìyá láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wa. Inú èmi, ìbejì mi, àti ìyá mi dùn gan-an, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún fífún wa ní àǹfààní láti wà pa pọ̀ fún fífún tọ̀tún tòsì níṣìírí fún odindi ọjọ́ kan gbáko. A nílò rẹ̀ gan-an.

A wà ní ilé ẹ̀kọ́ àtúnwà-ẹni-ṣe náà fún nǹkan bí oṣù mẹ́rin. Lẹ́yìn náà, wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ìdílé kan ní Pahna láti máa gbé. Wọ́n fún wọn nítọ̀ọ́ni láti má ṣe jẹ́ kí a fojú gán-ánní àwọn mọ̀lẹ́bí wa. Wọn kò tilẹ̀ fún ìyá mi pàápàá láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò. Síbẹ̀, ní àwọn ìgbà bíi mélòó kan, ó wá ọ̀nà láti kàn sí wa. Ní lílo àwọn àkókò àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wọ̀nyẹn ní kíkún, ìyá mi ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti gbin ìpinnu láti máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà sí wa lọ́kàn, láìka àdánwò àti ipò tí ó bá yọ̀ǹda sí.—Kọ́ríńtì Kíní 10:13.

Àwọn àdánwò náà sì dé ní tòótọ́. Ní December 15, 1942, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 17 péré, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú mi, wọ́n sì fi mí sí ibùdó àhámọ́ ní Gera. Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, wọ́n fi àṣẹ ọba mú ìyá mi pẹ̀lú, ó sì dara pọ̀ mọ́ mi nínú ẹ̀wọ̀n kan náà. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ọmọ aláìtójúúbọ́, ilé ẹjọ́ kò lè pè mí wá sí ìgbẹ́jọ́. Nítorí náà, èmi àti ìyá mi lo oṣù mẹ́fà ní àhámọ́, bí ilé ẹjọ́ ti ń dúró di ìgbà tí n óò pé ọmọ ọdún 18. Ní ọjọ́ gan-an tí mo pé ọmọ ọdún 18, wọ́n pe èmi àti ìyá mi wá sí ìgbẹ́jọ́.

Kí n tó mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ti mú gbogbo rẹ̀ wá sí òpin. N kò mọ̀ rárá pé n kò ní fojú rí ìyá mi mọ́. Ohun tí mo rántí gbẹ̀yìn nípa rẹ̀ ni pé mo rí i tí ó jókòó sórí àga gbọọrọ dúdú onígi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi ní ilé ẹjọ́. Wọ́n dá àwa méjèèjì lẹ́bi. Wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin, wọ́n sì rán ìyá mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún kan ààbọ̀.

Ní ayé ijọ́un, ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni a fi sì ẹ̀wọ̀n àti sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n, wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n ní Stollberg, níbi tí ó jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni Ẹlẹ́rìí. Mo lo ohun tí ó lé ní ọdún kan nínú àhámọ́ ànìkanwà, síbẹ̀, Jèhófà wà pẹ̀lú mi. Ìfẹ́ tí mo ti mú dàgbà fún un láti ìgbà èwe mi ni àṣírí tí ń bẹ lẹ́yìn bí mo ṣe wà láàyè nìṣó nípa tẹ̀mí.

Ní May 9, 1945, lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún méjì ààbọ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, a rí ìròyìn rere gbà—ogun ti parí! Wọ́n tú mi sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn gan-an. Lẹ́yìn rírin 110 kìlómítà, mo délé, rírẹ̀ tí ó rẹ̀ mí àti ebi tí ń pa mí kó àìsàn bá mi. Ó tó oṣù bíi mélòó kan kí n tó jèrè ìlera mi pa dà.

Gbàrà tí mo délé ni mo gbọ́ àwọn ìròyìn tí ń kó ìrora ọkàn báni. Àkọ́kọ́, nípa ìyá mi. Lẹ́yìn tí ó ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọdún kan ààbọ̀, ìjọba Nazi sọ pé kí ó fọwọ́ sí ìwé àkọsílẹ̀ kan ní sísẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jèhófà. Ó kọ̀. Nítorí náà, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú un lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àwọn obìnrin, ní Ravensbrück. Àrùn typhus ṣekú pá a níbẹ̀ kété ṣáájú kí ogun tó parí. Kristẹni tí ó gbóyà gidi gan-an ni òun—ajàfitafita, tí kò juwọ́ sílẹ̀ láé. Ǹjẹ́ kí Jèhófà rántí rẹ̀ fún rere.

Mo tún gbọ́ròyìn nípa Werner, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí kò fìgbà kan ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ sí Jèhófà. Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany, wọ́n sì pa á ní Rọ́ṣíà. Bàbá mi ńkọ́? Ó wá sílé ní tòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ tí ó fọwọ́ sí ìwé àkọsílẹ̀ olórúkọ burúkú náà, ní sísẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Nígbà tí mo rí i, ìrísí rẹ̀ jọ ti ẹni tí nǹkan ti sú, tí ìyọnu ọkàn bá.—Pétérù Kejì 2:20.

Àkókò Ráńpẹ́ Tí Ó Kún fún Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí Àfìtaraṣe

Ní March 10, 1946, mo lọ sí àpéjọ mi àkọ́kọ́ lẹ́yìn ogun ní Leipzig. Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ni nínú tó nígbà tí wọ́n ṣèfilọ̀ pé ìrìbọmi yóò wáyé ní ọjọ́ yẹn gan-an! Bí mo tilẹ̀ ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, èyí ni àǹfààní àkọ́kọ́ tí mo ní láti ṣe ìrìbọmi. N kò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn láé.

Ní March 1, 1947, lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún oṣù kan, wọ́n ké sí mi wá sí Bẹ́tẹ́lì ní Magdeburg. Bọ́ǹbù ti ba àwọn ọ́fíìsì Society jẹ́ gan-an. Ẹ wo irú àǹfààní ńlá tí ó jẹ́ láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ àtúnṣe náà! Lẹ́yìn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn náà, wọ́n rán mi lọ sí ìlú Wittenberge, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ní àwọn oṣù kan, mo lo iye tí ó lé ní 200 wákàtí ní wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ mi nínú tó pé mo wà lómìnira lẹ́ẹ̀kan sí i—kò sí ogun, kò sí inúnibíni, kò sí ìfisẹ́wọ̀n!

Ó bani nínú jẹ́ pé, òmìnira náà kò wà pẹ́ títí. Lẹ́yìn ogun, a pín Germany sí méjì, àgbègbè ibi tí mo ń gbé bọ́ sábẹ́ àkóso Kọ́múníìsì. Ní September 1950, àwọn ọlọ́pàá inú ti Ìlà Oòrùn Germany, tí a mọ̀ sí Stasi, bẹ̀rẹ̀ sí í fi àṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin lọ́kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mi pani lẹ́rìn-ín. Wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mo ń ṣamí fún ìjọba America. Wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n Stasi tí ó burú jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà, ní Brandenburg.

Ìtìlẹ́yìn Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Arákùnrin Mi Nípa Tẹ̀mí

Níbẹ̀, àwọn Stasi kì í jẹ́ kí n sùn ní ojú mọmọ. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi ìbéèrè wá mi lẹ́nu wò ní gbogbo òru. Lẹ́yìn tí wọ́n pọ́n mi lójú lọ́nà yí fún ọjọ́ díẹ̀, nǹkan túbọ̀ burú sí i. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, dípò kí wọ́n mú mi pa dà sínú àhámọ́ tí wọ́n fi mí sí, wọ́n mú mi lọ sí ọ̀kan lára àwọn U-Boot Zellen olórúkọ burúkú (tí a mọ̀ sí àhámọ́ inú ọkọ̀ abẹ́ omi nítorí ibi tí wọ́n wà nínú ihò ilẹ̀ lọ́hùn-ún). Wọ́n ṣí ilẹ̀kùn irin ògbólógbòó dídípẹtà kan, wọ́n sì ní kí n wọlé. Mo ní láti fẹsẹ̀ lórí igi gíga tí ó wà nísàlẹ̀ ilẹ̀kùn náà. Nígbà tí mo gbẹ́sẹ̀ mi sílẹ̀, mo rí i pé omi kún gbogbo ilẹ̀. Wọ́n palẹ̀kùn dé gbàgà pẹ̀lú ariwo ńlá. Kò sí iná, kò sì sí fèrèsé. Gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri.

Nítorí omi tí ó kúnlẹ̀, n ò lè jókòó, n ò lè dùbúlẹ̀, n ò sì lè sùn. Lẹ́yìn dídúró fún ohun tí ó dà bí ayérayé, wọ́n mú mi pa dà láti fi ìbéèrè wá mi lẹ́nu wò lábẹ́ iná títàn yòò. N kò mọ èyí tí ó burú jù—láti dúró lórí omi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ nínú òkùnkùn biribiri tàbí láti fara da ìrora iná mànàmáná títàn yòò tí a kọjú rẹ̀ sí mi ní gbogbo òru.

Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n halẹ̀ pé àwọn yóò yìn mí níbọn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ìbéèrè wá mi lẹ́nu wò ní àwọn alẹ́ bíi mélòó kan, ọ̀gá ológun ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan. Mo ní àǹfààní láti sọ fún un pé, àwọn Stasi ará Germany ń hùwà ìkà sí mi ju bí Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìjọba Nazi ti ṣe lọ. Mo sọ fún un pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dá sí tọ̀tún tòsì lábẹ́ ìjọba Nazi, wọ̀n kò sì dá sí tọ̀tún tòsì lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì pẹ̀lú, pé a kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, mo sọ pé, ọ̀pọ̀ tí ó jẹ́ ọlọ́pàá Stasi nísinsìnyí jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Èwe Hitler tẹ́lẹ̀ rí, níbi tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti kọ́ bí a ti ń ṣe inúnibíni oníwà ìkà gbáà sí àwọn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀. Bí mo ti ń sọ̀rọ̀, ara mi ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nítorí òtútù, ebi, àti àìlókun nínú.

Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ pé, ọ̀gá ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà kò bínú sí mi. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ó fi kúbùsù kan bò mí, ó sì fi inú rere hàn sí mi. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìbẹ̀wò rẹ̀, wọ́n dá mi pa dà sí yàrá ẹ̀wọ̀n tí ó sàn díẹ̀. Ní ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n fà mí lé ilé ẹjọ́ Germany lọ́wọ́. Nígbà tí ẹjọ́ mi ṣì wà nílẹ̀, mo gbádùn àǹfààní àtàtà láti ṣàjọpín yàrá ẹ̀wọ̀n kan náà pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún mìíràn. Lẹ́yìn fífarada ọ̀pọ̀ ìwà ìkà, ẹ wo bí ó ti tù mí lára tó láti gbádùn ìkẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn arákùnrin mi nípa tẹ̀mí!—Orin Dáfídì 133:1.

Ní ilé ẹjọ́, a dá mi lẹ́bi ṣíṣamí, a sì rán mi lọ ṣe ọdún mẹ́rin ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ka ìyẹn sí ìdájọ́ tí kò le koko jù. A rán àwọn arákùnrin kan lọ sẹ́wọ̀n tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá. Wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n tí ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ le jù lọ. Mo rò pé eku pàápàá kò lè rá wọlé tàbí rá jáde nínú ẹ̀wọ̀n yẹn—ẹ̀ṣọ́ náà lágbára. Síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin onígboyà kan láti gbé odindi Bíbélì wọlé. A yọ ọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, a sì pín-ín sí ìwé kọ̀ọ̀kan, a sì pín-in kiri láàárín àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n.

Báwo ni a ṣe ṣe é? Ó nira gidigidi. Ìgbà kan ṣoṣo tí a ń bá ara wa pàdé ni ìgbà tí a bá mú wa wá sí ilé ìwẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ méjì. Ní ìgbà kan, nígbà tí mo ń wẹ̀ lọ́wọ́, arákùnrin kan sọ̀rọ̀ sí mi létí pé òun ti fi àwọn ojú ìwé Bíbélì mélòó kan pa mọ́ sínú aṣọ ìnura òun. Lẹ́yìn tí mo bá wẹ̀ tán, mo ní láti he aṣọ ìnura rẹ̀ dípò tèmi.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i nígbà tí arákùnrin náà ń sọ̀rọ̀ sí mi létí, ó sì fi kóńdó ọlọ́pàá nà án bí ẹní máa kú. Mo ní láti sáré he aṣọ ìnura náà, kí n sì wọ àárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòó kù. Mo dúpẹ́ pé wọn kò ká àwọn ojú ìwé Bíbélì náà mọ́ mi lọ́wọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìtòlẹ́sẹẹsẹ bíbọ́ ara wa nípa tẹ̀mí kò bá ti wà nínú ewu. A fara gbá ọ̀pọ̀ ìrírí tí ó fara jọ èyí. Gbogbo ìgbà ni a máa ń fara pa mọ́ láti ka Bíbélì, ní fífẹ̀mí ara wa wewu ńlá. Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù náà pé, “Ẹ pa àwọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára,” bá a mu wẹ́kú ní ti gidi.—Pétérù Kíní 5:8.

Fún ìdí kan, àwọn aláṣẹ pinnu láti máa gbé díẹ̀ lára wa kiri láti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan sí òmíràn. Láàárín ọdún mẹ́rin, wọ́n ti mú mi lọ sí nǹkan bí ọgbà ẹ̀wọ̀n mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, ó máa ń ṣeé ṣe fún mi nígbà gbogbo láti rí àwọn arákùnrin. Mo wá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wọ̀nyí gidigidi, ó sì máa ń bà mí nínú jẹ́ gidigidi láti fi wọ́n sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá mú mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n míràn.

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rán mi lọ sí Leipzig, níbẹ̀ ni wọ́n sì ti tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ó tú mi sílẹ̀ kò sọ pé ó dìgbòó ṣe sí mi, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ó sọ ni pé, “A óò pa dà rí ọ láìpẹ́.” Ọkàn rẹ̀ burúkú ń fẹ́ kí wọ́n fi mi sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kan sí i. Mo sábà máa ń ronú lórí Orin Dáfídì 124:2, 3, níbi tí ó ti sọ pé: “Ì bá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa: Nígbà náà ni wọ́n ì bá gbé wa mì láàyè, nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa.”

Jèhófà Dá Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Adúróṣinṣin Nídè

Nísinsìnyí, mo ti wà lómìnira lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìbejì mi, Ruth, àti Arábìnrin Herta Schlensog, ń dúró dè mí níta. Ní gbogbo ọdún tí mo fi wà lẹ́wọ̀n, Herta ń fi àpò kékeré tí oúnjẹ wà nínú rẹ̀ ránṣẹ́ sí mi lóṣooṣù. Mo gbà gbọ́ ní tòótọ́ pé, tí kì í bá á ṣe àwọn àpò kéékèèké wọ̀nyẹn ni, ǹ bá ti kú sẹ́wọ̀n. Ǹjẹ́ kí Jèhófà rántí rẹ̀ fún rere.

Láti ìgbà tí a ti tú mi sílẹ̀, Jèhófà ti fi ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bù kún mi. Mo ṣiṣẹ́ sìn lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, ní Gronau, Germany, àti gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní àwọn Òkè Germany. Nígbà tí ó yá, wọ́n ké sí mi láti forúkọ sílẹ̀ fún kíláàsì kọkànlélọ́gbọ̀n ti Watchtower Bible School of Gilead fún àwọn míṣọ́nnárì. Ìkẹ́kọ̀ọ́yege wa wáyé ní Pápá Ìṣeré Yankee nígbà àpéjọ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní 1958. Mo ní àǹfààní bíbá àwùjọ ńlá àwọn arákùnrin àti arábìnrin sọ̀rọ̀ àti láti sọ díẹ̀ lára àwọn ìrírí tí mo ní fún wọn.

Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́yege, mo rìnrìn àjò lọ sí Chile láti lọ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Níbẹ̀, mo sìn lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, ní ìsàlẹ̀ Chile pátápátá—a rán mi ní ti gidi lọ sí ìpẹ̀kun ayé. Ní 1962, mo fẹ́ Patsy Beutnagel, míṣọ́nnárì òrékelẹ́wà kan láti San Antonio, Texas, U.S.A. Mo gbádùn ọ̀pọ̀ ọdún alárinrin nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi.

Nínú ìgbésí ayé mi tí ó lé ní 70 ọdún, mo ti nírìírí ọ̀pọ̀ àkókò aláyọ̀ àti ọ̀pọ̀ àjálù. Onísáàmù náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣùgbọ́n Olúwa gbà á nínú wọn gbogbo.” (Orin Dáfídì 34:19) Ní 1963, nígbà tí a ṣì wà ní Chile, èmi àti Patsy nírìírí ikú burúkú tí ó pa ọmọ ọwọ́ wa obìnrin jòjòló. Lẹ́yìn náà, Patsy ṣàìsàn gan-an, a sì ṣí lọ sí Texas. Nígbà tí ó jẹ́ ẹni ọdún 43 péré, ó kú, lábẹ́ ìpo burúkú pẹ̀lú. Mo sábà máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà rántí aya mi olùfẹ́ fún rere.

Nísinsìnyí, bí mo tilẹ̀ ń ṣàìsàn, tí mo sì ti gbó, mo ń gbádùn àǹfààní sísìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé àti alàgbà ní Brady, Texas. Ní tòótọ́, ìgbésí ayé kò fìgbà gbogbo rọrùn fún mi, àwọn àdánwò míràn ṣì lè wà tí mo ní láti kojú. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà, mo lè sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá; àti di ìsinsìnyí ni èmi ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ.”—Orin Dáfídì 71:17.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

(1) Sísìn lónìí gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti aṣáájú ọ̀nà, (2) pẹ̀lú Patsy, kété ṣáájú ìgbéyàwó wa, (3) nínú kíláàsì Herr Schneider, (4) Teresa, ìyá mi, tí ó kú ní Ravensbrück

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́