Orin 25
Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ọmọ Ẹ̀yìn Kristi Ni Wá
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Òfin kan wà fáwa Kristẹni.
Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ tẹ̀ lée.
Ọba òfin látòkè wá ni;
Òun nìfẹ́ tí Kristi kọ́ wa.
Ìfẹ́ Kristi Olúwa pọ̀ gan-an;
Ó fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ fún wa.
Ó fàpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa,
Ká tẹ̀ lée bí ọmọ ẹ̀yìn.
2. Ìfẹ́ tòótọ́ tí kìí kùnà láé,
Ó ńṣèrànwọ́ fáláìlera.
Gbogbo wa la jẹ gbèsè ìfẹ́,
Ojoojúmọ́ la ó máa sanán.
Kò síbòmíràn táa ti lè rí
Ọ̀rẹ́ tó nírú ìfẹ́ yìí.
Ó dájú pé ìfẹ́ ló so wá pọ̀;
Ẹ jẹ́ ká jọ máa lo ìfẹ́.
(Tún wo Róòmù 13:8; 1 Kọ́r. 13:8; Ják. 2:8; 1 Jòh. 4:10, 11.)