-
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Ṣẹ PátápátáIlé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Ṣẹ Pátápátá
“Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.”—JÓṢÚÀ 23:14.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé, láyé àtijọ́, tí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ tàbí àwọn ọlọ́pẹ̀lẹ̀ bá ń sọ ohun tí wọ́n rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ṣe ni wọ́n sábà máa ń sọ ọ́ lọ́nà tó fi máa ní ìtumọ̀ tó pọ̀, wọn kò sì ṣeé gbára lé. Lónìí náà, àwọn awòràwọ̀ kò ṣeé gbára lé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ sì ni àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la sábà máa ń gbé àsọbádé wọn kà, wọn kì í sì í lè sọ ní pàtó pé àwọn nǹkan báyìí-báyìí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ ní ti Bíbélì, ó máa ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kúnrẹ́rẹ́, tó sì máa ń ṣẹ láìyẹ̀, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé “ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn [ló ti] sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—Aísáyà 46:10.
ÀPẸẸRẸ: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Dáníẹ́lì rí ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọba Gíríìsì ṣe máa ṣẹ́gun ìjọba Mídíà àti Páṣíà ní wàrà-ǹ-ṣeṣà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ pé kété lẹ́yìn tí ọba ilẹ̀ Gíríìsì tó ṣẹ́gun yẹn bá ti “di alágbára,” ìjọba rẹ̀ yóò “ṣẹ́.” Ta ló máa wá rọ́pò rẹ̀? Dáníẹ́lì sọ pé: “Ìjọba mẹ́rin ni yóò dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 8:5-8, 20-22.
OHUN TÍ ÀWỌN ÒPÌTÀN SỌ: Ní èyí tó ju igba [200] ọdún lọ lẹ́yìn ìgbà ayé Dáníẹ́lì, Alẹkisáńdà Ńlá di ọba ilẹ̀ Gíríìsì. Láàárín ọdún mẹ́wàá, Alẹkisáńdà ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà, ó sì mú kí Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì gbòòrò dé Odò Íńdọ́sì (tó wà ní orílẹ̀-èdè Pakísítánì lónìí). Àmọ́, ó kú lójijì nígbà tó wà ní ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32]. Níkẹyìn, ogun tó wáyé nítòsí ìlú Ipisọ́sì, tó wà ní Éṣíà Kékeré, jẹ́ kí ilẹ̀ ọba rẹ̀ pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ni àwọn mẹ́rin tó jagun ṣẹ́gun níbi ogun yẹn bá pín Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì mọ́ra wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó lágbára bíi ti Alẹkisáńdà.
KÍ LÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ ìwé míì tún wà tó sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, tó sì ní ìmúṣẹ bíi ti Bíbélì yìí? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì . . . pọ̀ ré kọjá ohun tí èèyàn fi lè máa rò pé ṣe ni wọ́n kàn ṣèèṣì ń ṣẹ.”—A LAWYER EXAMINES THE BIBLE, LÁTI ỌWỌ́ IRWIN H. LINTON
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
© Robert Harding Picture Library/SuperStock
-
-
Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì Kì Í Ṣe Àlọ́Ilé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì Kì Í Ṣe Àlọ́
“Mo ti tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.”—LÚÙKÙ 1:3.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Ìtàn àlọ́ tàbí ìtàn àròsọ máa ń dùn gbọ́ àmọ́ kì í sábà ní orúkọ ibi pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, ọjọ́ pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ àti orúkọ àwọn èèyàn tó ti gbé ayé rí tó ṣẹlẹ̀ sí, téèyàn lè fi wádìí òótọ́ rẹ̀. Àmọ́ ti Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì ní ọ̀kẹ́ àìmọye kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni tó jẹ́ kó lè dá àwọn tó bá kà á lójú pé “ọ̀rọ̀” inú rẹ̀ jẹ́ “òtítọ́.”—Sáàmù 119:160.
ÀPẸẸRẸ: Bíbélì sọ pé “Nebukadinésárì ọba Bábílónì . . . mú Jèhóákínì [ọba Júdà] lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.” Àti pé lẹ́yìn náà, “Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tí ó di ọba, gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè kúrò ní àtìmọ́lé.” Ó sì sọ pé “ohun tí a yọ̀ǹda ni a ń fi fún un [ìyẹn Jèhóákínì] nígbà gbogbo láti ọ̀dọ̀ ọba, lójoojúmọ́ bí ó ti yẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.”—2 Àwọn Ọba 24:11, 15; 25:27-30.
OHUN TÍ ÀWỌN AWALẸ̀PÌTÀN ṢÀWÁRÍ: Àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn ìwé kan tó jẹ mọ́ ti àbójútó ìlú lára àwọn àwókù ìlú Bábílónì ìgbàanì. Ìgbà ìṣàkóso Nebukadinésárì Ọba Kejì ni wọ́n sì ti kọ àwọn ìwé náà. Wọ́n kọ ìwọ̀n oúnjẹ tí wọ́n ń fún ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ọ̀kan àti àwọn míì tó ń gba oúnjẹ ní àgbàlá ọba síbẹ̀. Nínú àkọsílẹ̀ yẹn ni a ti rí “Yaukin [ìyẹn Jèhóákínì],” tó jẹ́ “ọba ilẹ̀ Yahud (ìyẹn Júdà),” àti agbo ilé rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn awalẹ̀pìtàn tiẹ̀ sọ nǹkan kan nípa ẹni tó rọ́pò Nebukadinésárì, ìyẹn Efili-méródákì? Wọ́n rí àkọlé kan tó wà lára àwo òdòdó kan tí wọ́n rí lẹ́bàá ìlú Súsà, tó sọ pé: “Ààfin Amil-Marduk [ìyẹn Efili-méródákì], Ọba Bábílónì, ọmọ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì.”
KÍ LÈRÒ RẸ? Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìtàn, ǹjẹ́ ìwé ẹ̀sìn míì tún wà tí wọ́n ti kọ tipẹ́tipẹ́, tó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé bíi ti Bíbélì? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa bí àwọn nǹkan ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra àti àkókò tí wọ́n ṣẹlẹ̀ àti bí ojú ilẹ̀ ṣe rí láyé ìgbà yẹn, péye ó sì ṣeé gbára lé ju ti ìwé àtijọ́ èyíkéyìí míì lọ.”—A SCIENTIFIC INVESTIGATION OF THE OLD TESTAMENT, LÁTI ỌWỌ́ ROBERT D. WILSON
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìwé àwọn ará Bábílónì kan tó mẹ́nu kan Jèhóákínì ọba Júdà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
© bpk, Berlin/Vorderasiatisches Museum, SMB/Olaf M. Tessmer/Art Resource, NY
-
-
Ohun Tí Bíbélì Sọ Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì MuIlé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
Ohun Tí Bíbélì Sọ Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu
“Èmi kò ha ti kọ̀wé sí ọ ṣáájú àkókò yìí pẹ̀lú àwọn ìgbani- nímọ̀ràn àti ìmọ̀, láti fi ìjótìítọ́ àwọn àsọjáde tòótọ́ hàn ọ́, láti lè mú àwọn àsọjáde tí í ṣe òtítọ́ padà?”—ÒWE 22:20, 21.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Àwọn ìwé ayé àtijọ́ sábà máa ń sọ àwọn nǹkan tí kò ṣeé gbára lé tó sì tún léwu, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní sì ti já wọn nírọ́ pátápátá. Kódà lónìí, ó pọndandan pé kí àwọn òǹṣèwé máa ṣe àwọn àyípadà sí ohun tí wọ́n ti kọ sínú ìwé wọn látìgbàdégbà kó lè bá àwọn àwárí tuntun mu. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa ló ni Bíbélì àti pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “wà títí láé.”—1 Pétérù 1:25.
ÀPẸẸRẸ: Nínú Òfin Mósè Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀, kí wọ́n gbẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n máa ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí “ní òde ibùdó,” kí wọ́n sì bò ó mọ́lẹ̀ lẹ́yìn náà. (Diutarónómì 23:12, 13) Àti pé tí wọ́n bá fọwọ́ kan òkú ẹranko tàbí ti èèyàn, wọ́n gbọ́dọ̀ fi omi fọ aṣọ wọn. (Léfítíkù 11:27, 28; Númérì 19:14-16) Láyé ìgbà yẹn, ṣe ni wọ́n máa ń sé àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ títí dìgbà tí àyẹ̀wò yóò fi hàn pé àrùn ara wọn kò lè ranni mọ́.—Léfítíkù 13:1-8.
OHUN TÍ ÌMỌ̀ ÌṢÈGÙN ÒDE ÒNÍ SỌ: Pípalẹ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́ bó ṣe yẹ, fífọ ọwọ́ wa àti sísé ẹni tó ní àrùn tó lè ranni mọ́, jẹ́ ọ̀nà tó dára jù láti fi gbógun ti àrùn. Níbi tí kò bá sí ṣáláńgá tàbí oríṣi ilé ìgbọ̀nsẹ̀ míì, ìmọ̀ràn tí Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (U.S. Centers for Disease Control and Prevention) gbani ni pé: “Jẹ́ kí ibi tó o máa ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ rẹ sí jìnnà tó ọgbọ́n [30] mítà síbi tí odò èyíkéyìí wà, lẹ́yìn náà, kó o bò ó mọ́lẹ̀.” Ohun tí Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ ni pé, tí gbogbo ará ìlú bá ń palẹ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́ bó ṣe yẹ, àrùn ìgbẹ́ gbuuru máa dín kù gan-an. Kò tíì tó igba [200] ọdún sí ìsinsìnyí tí àwọn oníṣègùn ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i pé àwọn ń kó àrùn ran ọ̀pọ̀ aláìsàn tí àwọn kò bá fọwọ́ lẹ́yìn tí àwọn fọwọ́ kan òkú èèyàn, tí àwọn sì lọ fi ọwọ́ yẹn kan náà tọ́jú aláìsàn. Ibùdó Ìkáwọ́ àti Ìdènà Àrùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Fífọ ọwọ́ ni ọ̀nà kan tó dára jù lọ láti gbà dènà títan àrùn tó ń ranni kálẹ̀.” Sísé àwọn tó lárùn ẹ̀tẹ̀ tàbí àrùn míì tó lè ranni mọ́ ńkọ́? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ohun tí ìwé kan tó ń jẹ́ Saudi Medical Journal sọ ni pé: “Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó jọ pé yíya àwọn tó ní àrùn yẹn sọ́tọ̀ àti sísé wọn mọ́ ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti gbà dènà ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn tó ń ranni.”
KÍ LÈRÒ RẸ? Ṣé o rò pé èyíkéyìí lára àwọn ìwé àtijọ́ tí wọ́n ń pè ní ìwé mímọ́ tún wà tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu bíi ti Bíbélì? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Kò sí ẹni tó bá kà nípa àwọn ètò ìmọ́tótó tí wọ́n là kalẹ̀ láti dènà àrùn nígbà ayé Mósè, tí kò ní wú u lórí gan-an.”—MANUAL OF TROPICAL MEDICINE, LÁTI ỌWỌ́ DỌ́KÍTÀ ALDO CASTELLANI ÀTI ALBERT J. CHALMERS
-
-
Gbogbo Ìwé Inú Bíbélì Wà Níṣọ̀kanIlé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
Gbogbo Ìwé Inú Bíbélì Wà Níṣọ̀kan
“A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 PÉTÉRÙ 1:21.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Àwọn àkọsílẹ̀ ayé àtijọ́ sábà máa ń ta kora, kódà bí wọ́n tiẹ̀ kọ wọ́n láàárín ìgbà kan náà. Tí èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá kọ̀wé, ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ní àkókò tó yàtọ̀ síra, àwọn ìwé náà kò ní ṣàì ta kora ní àwọn ibì kan. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé ẹnì kan ṣoṣo ni Òǹṣèwé gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] inú Bíbélì, tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bára mu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí láì ta kora.—2 Tímótì 3:16.
ÀPẸẸRẸ: Mósè tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ nínú ìwé àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì pé “irú-ọmọ” kan ń bọ̀ tó máa gba aráyé là. Nígbà tó yá, ìwé yìí tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irú-ọmọ yẹn máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:17, 18; 26:24; 28:14) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn náà, wòlíì Nátánì jẹ́ ká mọ̀ pé irú-ọmọ náà yóò wá láti ìlà ìdílé Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 7:12) Ẹgbẹ̀rún ọdún kan lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù àti àwọn kan tí Ọlọ́run yàn lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ló máa para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ náà. (Róòmù 1:1-4; Gálátíà 3:16, 29) Níkẹyìn, ìgbà tó máa fi di ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ìwé Ìṣípayá tó kẹ́yìn Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn tó para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ yẹn máa jẹ́rìí nípa Jésù lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á jíǹde sókè ọ̀run, wọ́n yóò sì bá Jésù ṣàkóso lọ́run fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. Àti pé àwọn tó para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ yìí máa pa Èṣù run, wọn á sì gba aráyé là.—Ìṣípayá 12:17; 20:6-10.
OHUN TÍ ÀWỌN TÓ Ń ṢÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀ INÚ BÍBÉLÌ SỌ: Lẹ́yìn tí ọ̀gbẹ́ni Louis Gaussen ti fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tó wà nínú Bíbélì dáadáa, ó kọ̀wé pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún òun láti rí “bí ìwé yìí, tó gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún kí onírúurú òǹkọ̀wé tó kọ ọ́ parí, ṣe wà níṣọ̀kan pátápátá, . . . tí àwọn òǹkọ̀wé yẹn sì kọ̀wé lórí kókó kan náà, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, lọ́nà tó ṣọ̀kan, bíi pé àwọn fúnra wọn ti mọ kókó tí wọ́n ń kọ̀wé lé lórí dunjú, ìyẹn ìtàn bí Ọmọ Ọlọ́run ṣe gba aráyé là.”—Theopneusty—The Plenary Inspiration of the Holy Scriptures.
KÍ LÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ o rò pé ìwé kan tí nǹkan bí ogójì [40] èèyàn kọ, tó sì gba ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún kí wọ́n tó kọ ọ́ parí, lè wà ní ìṣọ̀kan láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí láì ta kora níbì kankan? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Tí a bá wo ìwé Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá pa pọ̀, a óò rí i pé ṣe ni gbogbo rẹ̀ para pọ̀ jẹ́ ìwé kan ṣoṣo . . . Nínú gbogbo ìwé ayé yìí, kò sì ìwé tó dà bí tirẹ̀, tàbí èyí tó tiẹ̀ sún mọ́ ọn.”—THE PROBLEM OF THE OLD TESTAMENT, LÁTI ỌWỌ́ JAMES ORR
-
-
Bíbélì Wúlò Fún Wa Lóde ÒníIlé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
Bíbélì Wúlò Fún Wa Lóde Òní
“Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—SÁÀMÙ 119:105.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Ìwé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lè jẹ́ ìwé tó fakọ yọ, àmọ́ ìyẹn ò fi hàn pé wọ́n lè tọ́ni sọ́nà lórí ọ̀rọ̀ ìwà rere. Ó sì jẹ́ dandan láti máa ṣe àwọn àyípadà sí àwọn ìwé atọ́nà òde òní látìgbàdégbà. Àmọ́ Bíbélì sọ ní tiẹ̀ pé: “Ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.”—Róòmù 15:4.
ÀPẸẸRẸ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ìmọ̀ ìṣègùn, àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an lórí béèyàn ṣe lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìlera tó dáa wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Bíbélì sì tún kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Àmọ́ ó wá sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
OHUN TÍ ÌWÁDÌÍ FI HÀN: Ẹ̀mí sùúrù, níní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, àti jíjẹ́ ọ̀làwọ́, lè mú kí ìlera ẹni túbọ̀ dáa. Ìwé ìròyìn Journal of the American Medical Association sọ pé: “Àwọn ọkùnrin tó máa ń bínú gan-an máa ń tètè ní àrùn rọpárọsẹ̀ ju àwọn tí kì í tètè bínú lọ.” Ìwádìí tí àwọn kan ṣe fún ọdún mẹ́wàá ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà fi hàn pé àwọn àgbàlagbà tó bá ní “àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń kàn síra àti alábàárò tí wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀” sábà máa ń pẹ́ díẹ̀ láyé. Lọ́dún 2008, àwọn olùṣèwádìí kan ní orílẹ̀-èdè Kánádà àti Amẹ́ríkà rí i pé “téèyàn bá ń fi owó rẹ̀ ṣoore fún àwọn èèyàn, ìyẹn máa ń fúnni ní ayọ̀ ju kéèyàn kàn máa ná an sórí ara rẹ̀ lọ.”
KÍ LÈRÒ RẸ? Yàtọ̀ sí Bíbélì, ṣé wàá lè fi gbogbo ara gbára lé ìmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìlera tó bá wà nínú ìwé kan tó o mọ̀ pé wọ́n ti kọ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún-ún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
“Mo fẹ́ràn Bíbélì gan-an . . . torí ó ní àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gidigidi lórí ọ̀rọ̀ ìṣègùn.”—HOWARD KELLY, M.D., Ọ̀KAN NÍNÚ ÀWỌN TÓ JẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀTI OLÙDÁSÍLẸ̀ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌṢÈGÙN TI THE JOHNS HOPKINS UNIVERSITY SCHOOL OF MEDICINE
-