ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ísákì ní kí Jékọ́bù lọ sí Padani-árámù (1-9)

      • Àlá tí Jékọ́bù lá ní Bẹ́tẹ́lì (10-22)

        • Ọlọ́run tún ìlérí rẹ̀ sọ fún Jékọ́bù (13-15)

Jẹ́nẹ́sísì 28:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:34, 37; Ẹk 34:15, 16; 1Ọb 11:1-3; 2Kọ 6:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1995, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 28:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:16

Jẹ́nẹ́sísì 28:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:5; 46:15, 19; 1Kr 2:1, 2

Jẹ́nẹ́sísì 28:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:2, 3
  • +Jẹ 12:7; 15:13; 17:1, 8; Heb 11:9

Jẹ́nẹ́sísì 28:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:20
  • +Jẹ 24:29

Jẹ́nẹ́sísì 28:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:1; 2Kọ 6:14

Jẹ́nẹ́sísì 28:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:43

Jẹ́nẹ́sísì 28:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:46

Jẹ́nẹ́sísì 28:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:2, 3

Jẹ́nẹ́sísì 28:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 11:31; 27:43

Jẹ́nẹ́sísì 28:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:18, 19

Jẹ́nẹ́sísì 28:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àkàbà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:51; Heb 1:7, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2004, ojú ìwé 28

    10/15/2003, ojú ìwé 28-29

Jẹ́nẹ́sísì 28:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:24, 25
  • +Jẹ 12:7; 28:4; Sm 105:9-11

Jẹ́nẹ́sísì 28:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Tàbí “gba ìbùkún fún ara wọn.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 13:14, 16; 1Ọb 4:20
  • +Jẹ 18:18; 22:15, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 91-92

Jẹ́nẹ́sísì 28:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:6
  • +Jẹ 31:3; Nọ 23:19; Joṣ 23:14; Heb 6:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 20-21

Jẹ́nẹ́sísì 28:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 47:2
  • +Jẹ 35:1

Jẹ́nẹ́sísì 28:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:13

Jẹ́nẹ́sísì 28:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:6; Joṣ 16:1, 2

Jẹ́nẹ́sísì 28:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:1

Àwọn míì

Jẹ́n. 28:1Jẹ 24:34, 37; Ẹk 34:15, 16; 1Ọb 11:1-3; 2Kọ 6:14
Jẹ́n. 28:2Jẹ 29:16
Jẹ́n. 28:3Jẹ 17:5; 46:15, 19; 1Kr 2:1, 2
Jẹ́n. 28:4Jẹ 12:2, 3
Jẹ́n. 28:4Jẹ 12:7; 15:13; 17:1, 8; Heb 11:9
Jẹ́n. 28:5Jẹ 25:20
Jẹ́n. 28:5Jẹ 24:29
Jẹ́n. 28:6Jẹ 28:1; 2Kọ 6:14
Jẹ́n. 28:7Jẹ 27:43
Jẹ́n. 28:8Jẹ 27:46
Jẹ́n. 28:9Jẹ 36:2, 3
Jẹ́n. 28:10Jẹ 11:31; 27:43
Jẹ́n. 28:11Jẹ 28:18, 19
Jẹ́n. 28:12Jo 1:51; Heb 1:7, 14
Jẹ́n. 28:13Jẹ 26:24, 25
Jẹ́n. 28:13Jẹ 12:7; 28:4; Sm 105:9-11
Jẹ́n. 28:14Jẹ 13:14, 16; 1Ọb 4:20
Jẹ́n. 28:14Jẹ 18:18; 22:15, 18
Jẹ́n. 28:15Jẹ 35:6
Jẹ́n. 28:15Jẹ 31:3; Nọ 23:19; Joṣ 23:14; Heb 6:18
Jẹ́n. 28:17Sm 47:2
Jẹ́n. 28:17Jẹ 35:1
Jẹ́n. 28:18Jẹ 31:13
Jẹ́n. 28:19Jẹ 35:6; Joṣ 16:1, 2
Jẹ́n. 28:22Jẹ 35:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 28:1-22

Jẹ́nẹ́sísì

28 Torí náà, Ísákì pe Jékọ́bù, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì!+ 2 Lọ sí Padani-árámù, ní ilé Bẹ́túẹ́lì bàbá ìyá rẹ, kí o sì fẹ́ ìyàwó níbẹ̀ láàárín àwọn ọmọbìnrin Lábánì,+ arákùnrin ìyá rẹ. 3 Ọlọ́run Olódùmarè yóò bù kún ọ, yóò mú kí o bímọ tó pọ̀, yóò mú kí o pọ̀ gan-an, ó sì dájú pé ìwọ yóò di àwùjọ àwọn èèyàn.+ 4 Yóò bù kún ọ bó ṣe ṣèlérí fún Ábúráhámù,+ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ, kí ilẹ̀ tí ò ń gbé bí àjèjì, tí Ọlọ́run ti fún Ábúráhámù+ lè di ohun ìní rẹ.”

5 Ísákì wá ní kí Jékọ́bù máa lọ, ó sì forí lé Padani-árámù, ó lọ sọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bẹ́túẹ́lì ará Arémíà,+ arákùnrin Rèbékà  + tó jẹ́ ìyá Jékọ́bù àti Ísọ̀.

6 Ísọ̀ mọ̀ pé Ísákì ti súre fún Jékọ́bù, ó sì ti ní kó lọ sí Padani-árámù, kó lọ fẹ́ ìyàwó níbẹ̀, ó mọ̀ pé nígbà tó súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé: “Má lọ fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì,”+ 7 ó sì mọ̀ pé Jékọ́bù ṣe ohun tí bàbá àti ìyá rẹ̀ sọ, ó forí lé Padani-árámù.+ 8 Ìgbà yẹn ni Ísọ̀ wá rí i pé inú Ísákì+ bàbá òun ò dùn sí àwọn ọmọ Kénáánì, 9 torí náà, Ísọ̀ lọ sọ́dọ̀ Íṣímáẹ́lì ọmọ Ábúráhámù, ó sì fẹ́ Máhálátì ọmọ Íṣímáẹ́lì tó jẹ́ arábìnrin Nébáótì. Ó fẹ́ ẹ kún àwọn ìyàwó tó ti ní.+

10 Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, ó sì ń lọ sí agbègbè Háránì.+ 11 Nígbà tó yá, ó dé ibì kan, ó sì fẹ́ sun ibẹ̀ mọ́jú torí oòrùn ti wọ̀. Torí náà, ó gbé ọ̀kan lára àwọn òkúta tó wà níbẹ̀, ó gbé e sílẹ̀ kó lè gbórí lé e, ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.+ 12 Ó wá lá àlá, sì wò ó! àtẹ̀gùn* kan wà ní ayé, òkè rẹ̀ sì kan ọ̀run; àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀.+ 13 Wò ó! Jèhófà wà lókè rẹ̀, ó sì sọ pé:

“Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá rẹ àti Ọlọ́run Ísákì.+ Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ*+ rẹ ni màá fún ní ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí. 14 Ó dájú pé àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,+ ìwọ yóò sì tàn káàkiri dé ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn, dé àríwá àti gúúsù, ó sì dájú pé gbogbo ìdílé ayé yóò rí ìbùkún gbà*+ nípasẹ̀ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ. 15 Mo wà pẹ̀lú rẹ, màá dáàbò bò ọ́ ní gbogbo ibi tí o bá lọ, màá sì mú ọ pa dà sí ilẹ̀ yìí.+ Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí màá fi ṣe ohun tí mo ṣèlérí fún ọ.”+

16 Jékọ́bù jí lójú oorun, ó sì sọ pé: “Jèhófà wà níbí lóòótọ́, mi ò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù wá ń bà á, ó sì sọ pé: “Ibí yìí mà ń bani lẹ́rù o! Ó ní láti jẹ́ pé ilé Ọlọ́run+ ni ibí, ẹnubodè ọ̀run+ sì nìyí.” 18 Jékọ́bù wá jí ní àárọ̀ kùtù, ó sì gbé òkúta tó gbórí lé, ó gbé e dúró bí òpó, ó sì da òróró sórí rẹ̀.+ 19 Ó wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì,* àmọ́ Lúsì+ ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.

20 Jékọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan pé: “Tí Ọlọ́run ò bá fi mí sílẹ̀, tó dáàbò bò mí lẹ́nu ìrìn àjò mi, tó sì fún mi ní oúnjẹ tí màá jẹ àti aṣọ tí màá wọ̀, 21 tí mo sì pa dà sí ilé bàbá mi ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà ti fi hàn dájú pé òun ni Ọlọ́run mi. 22 Òkúta tí mo gbé kalẹ̀ bí òpó yìí yóò di ilé Ọlọ́run,+ ó sì dájú pé màá fún ọ ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí o fún mi.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́