Orin 6
Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Baba Ọ̀run, Ọba Aláṣẹ,
Títí láé, ògo fórúkọ ńlá rẹ.
Àánú rẹ yóò wà títí ayé,
Lódodo dájúdájú, láéláé.
Lódodo dájúdájú,
Àánú rẹ̀ yóò wà láéláé.
2. Gbin ìfẹ́ òtítọ́ sínú wa.
Jáà, jẹ́ ká lè máa ṣèfẹ́ rẹ dáadáa.
Gbogbo òfin rẹ la fẹ́ pa mọ́,
Aó máa wá àgùntàn rẹ ọ̀wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ ni, aó sì máa bọ́ wọn,
Òfin rẹ la fẹ́ pa mọ́.
3. A ńtọrọ ọgbọ́n àtọ̀runwá.
Jọ̀ọ́ fọgbọ́n yìí òun ìfẹ́ sọ́kàn wa.
Ká lè máa lo ìfẹ́ òun àánú,
Káráyé lè mọ̀ọ́ ní Ọlọ́run.
Kí wọ́n mọ̀ ọ́ l’Ọ́lọ́run,
Ká lo ìfẹ́ òun àánú.
(Tún wo Sm. 143:10; Jòh. 21:15-17; Ják. 1:5.)