ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | December 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

      Ǹjẹ́ O Sún Mọ́ Ọlọ́run?

      “Téèyàn bá sún mọ́ Ọlọ́run, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀, ayé rẹ̀ á tòrò, á sì mọ̀ ọ́ lára pé Ọlọ́run fẹ́ òun fún ire.”​—CHRISTOPHER, Ọ̀DỌ́KÙNRIN KAN TÓ Ń GBÉ NÍ GÁNÀ.

      “Ọlọ́run rí ìdààmú ọkàn rẹ, á sì máa fìfẹ́ hàn sí ẹ ju bó o ṣe rò lọ.”​—HÁNÀ, ỌMỌ ỌDÚN MẸ́TÀLÁ TÓ Ń GBÉ NÍ ALASKA, NÍLẸ̀ AMẸ́RÍKÀ.

      “Kò sóhun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó sì ń dùn mọ́ni tó kéèyàn mọ̀ pé òun jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!”​—GINA, OBÌNRIN ARÁ JÀMÁÍKÀ TÓ TI LÉ NÍ ẸNI OGÓJÌ ỌDÚN.

      Christopher, Hánà àti Gina nìkan kọ́ ló ní irú èrò yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn, ó sì ka àwọn sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣé irú èrò tí ìwọ náà ní nìyẹn? Ṣé o gbà pé o sún mọ́ Ọlọ́run? Àbí wàá fẹ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? Ó ṣeé ṣe kó o máa rò ó pé: ‘Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún èèyàn lásánlàsàn bíi tèmi láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lèèyàn ṣe lè ṣe é?’

      ÈÈYÀN LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

      Bíbélì fi dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ábúráhámù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí Ọlọ́run pè ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Aísáyà 41:⁠8) Ọlọ́run wá nawọ́ ìkésíni sí àwa náà nínú ìwé Jákọ́bù 4:8 pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Gbogbo èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ìrísí Ọlọ́run ò dàbí tàwa èèyàn torí ẹni àìrí ni. Báwo wá la ṣe lè “sún mọ́” Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀?

      Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ronú nípa bí ẹni méjì ṣe máa ń di ọ̀rẹ́. Wọ́n á kọ́kọ́ mọ orúkọ ara wọn, wọ́n á sí máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Bí ọ̀rọ̀ wọn bá ṣe ń wọ̀, tí wọ́n sì tún ń ṣe aájò ara wọn, ni okùn ọ̀rẹ́ wọn á túbọ̀ máa lágbára, wọ́n á wá di kòríkòsùn. Bó ṣe máa ń rí náà nìyẹn tá a bá fẹ́ bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀.

  • Ǹjẹ́ O Mọ Orúkọ Ọlọ́run, Ṣé O Máa Ń Lò Ó?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | December 1
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

      Ǹjẹ́ O Mọ Orúkọ Ọlọ́run, Ṣé O Máa Ń Lò Ó?

      Ǹjẹ́ ẹnì kankan wà nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o kò mọ orúkọ rẹ̀? Bóyá ni. Obìnrin kan ní Bulgaria tó ń jẹ́ Irina sọ pé, “Kò ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run tó ò bá mọ orúkọ rẹ̀.” Ṣé o rántí pé ohun tá a sọ nínú àkòrí tó ṣáájú nìyẹn. Inú wa sì dùn pé Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun, ó tiẹ̀ sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì, ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.”​—Aísáyà 42:8.

      Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun, ó tiẹ̀ sọ orúkọ rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.”​—Aísáyà 42:8

      Ǹjẹ́ Jèhófà fẹ́ kó o máa lo orúkọ òun? Rò ó wò ná: Lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà. Kò sí orúkọ míì tó fara hàn tó bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Àmì nìyẹn jẹ́ pé Jèhófà fẹ́ kó o mọ orúkọ òun, kó o sì máa lò ó.a

      Táwọn méjì bá fẹ́ di ọ̀rẹ́, orúkọ ara wọn ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ béèrè. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ Ọlọ́run?

      Ṣùgbọ́n ohun táwọn kan rò ni pé torí Ọlọ́run jẹ́ ẹni mímọ́, òun sì ni olódùmarè, ìwà àrífín ni kéèyàn máa la orúkọ mọ́ ọn. Ká sòótọ́, ìwà àrífín ni téèyàn bá lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò tọ́, ó ṣe tán, àwa náà ò jẹ́ fi orúkọ ọ̀rẹ́ wa wọ́lẹ̀. Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ máa gbé orúkọ rẹ̀ ga kí wọ́n sì máa pòkìkí rẹ̀ fún aráyé gbọ́. (Sáàmù 69:​30, 31; 96:​2, 8) Ṣé o rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Ó ní kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Bí ìwọ náà bá ń sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, ńṣe lò ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run sí i.​—Mátíù 6:9.

      Bíbélì tiẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dìídì fiyè sí “àwọn tó ń ronú lórí [tàbí “mọyì”] orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Jèhófà ṣèlérí fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: ‘Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi. Òun yóò ké pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn. Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà wàhálà.’ (Sáàmù 91:​14, 15) Ẹ ò rí i báyìí pé tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, ó ṣe pàtàkì ká mọ orúkọ Ọlọ́run ká sì máa lò ó.

      a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yẹn fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, èyí táwọn kan ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, ó yani lẹ́nu pé àwọn kan dìídì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì. Wọ́n wá fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tá a sọ yìí, wo ojú ìwé 195 sí 197 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-⁠an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | December 1
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

      Ǹjẹ́ O Máa Ń Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀?

      Ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé, ì báà jẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, lórí fóònú tàbí kí wọ́n kọ lẹ́tà síra wọn. Bí àwa náà bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Àmọ́, báwo la ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀?

      A lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, ṣùgbọ́n a ò kàn lè máa sọ̀rọ̀ bí ìgbà tá à ń bá ọ̀rẹ́ wa tàkúrọ̀sọ. A gbọ́dọ̀ máa rántí pé òun ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, òun sì ni Ọ̀gá Ògo láyé àtọ̀run. Torí náà, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló yẹ ká máa bá a sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Àmọ́ bá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa kó sì dáhùn rẹ̀, ó ní àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta yẹ̀ wọ̀.

      Àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run ló yẹ ká darí àdúrà wa sí kì í ṣe Jésù tàbí ère tàbí àwọn kan tí wọ́n ń pè ní “ẹni mímọ́.” (Ẹ́kísódù 20:​4, 5) Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílípì 4:6) Èkejì ni pé ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lórúkọ Jésù Kristi. Ìdí nìyẹn tí Jésù fúnra rẹ̀ fi sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Ìkẹta ni pé àdúrà wa gbọ́dọ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Torí Bíbélì sọ pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”a​—1 Jòhánù 5:14.

      Ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé

      Síbẹ̀, máa rántí pé bí ẹni méjì bá ń ṣọ̀rẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ jọ máa sọ̀rọ̀, ẹnì kìíní sí ẹnì kejì, kì ọ̀rẹ́ wọn lè kalẹ́. Bí àwa náà bá fẹ́ bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́ kalẹ́, kì í ṣe ohun tá a fẹ́ bá Ọlọ́run sọ nínú àdúrà nìkan ló yẹ kó jẹ wá lógún, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọlọ́run máa bá wa sọ̀rọ̀ ká sì fetí sí ohun tí ó bá sọ. Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọ́run ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀?

      Lónìí, Bíbélì ni Jèhófà fi ń bá wa “sọ̀rọ̀.” (2 Tímótì 3:​16, 17) Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó dáa, ká ní ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kọ lẹ́tà sí ẹ, ó dájú pé inú rẹ á dùn gan-⁠an, kódà lẹ́yìn tó o bá kà á tán, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi lẹ́tà náà han àwọn èèyàn pé “ẹ wá gbọ́ ohun tí ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi!” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó kọ ọ̀rọ̀ náà sínú ìwé ni kò bá ẹ sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Bákan náà, bó o bá ń ka Bíbélì, ńṣe lò ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ń sọ fún ẹ. Ìdí nìyẹn tí Gina tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkòrí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé yìí fi sọ pé: “Bí mo bá fẹ́ kí Ọlọ́run kà mí sí ọ̀rẹ́ rẹ̀, àfi kí n máa ka Bíbélì torí òun ni ‘lẹ́tà’ tí Ọlọ́run kọ sí wa. Bí mo ṣe ń ka Bíbélì déédéé ti jẹ́ kí n sún mọ́ Ọlọ́run gan-⁠an.” Ṣé ìwọ náà máa ń jẹ́ kí Jèhófà bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa kíka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé? Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

      a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí o ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-⁠an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | December 1
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

      Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́?

      Ká sọ pé o rí àjèjì kan, ǹjẹ́ o lè sọ fún un pé: “Ohunkóhun tó o bá fẹ́, ìwọ ṣáà ti sọ fún mi, inú mi á dùn láti ṣe é fún ẹ láìjáfara”? Kò dájú pé wàá sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ á rọrùn fún ẹ láti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́, torí pé ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ máa ń ran ara wọn lọ́wọ́, ẹnì kìíní sì máa ń ṣe ohun tó máa múnú ẹnì kejì dùn.

      Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó máa múnú àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ dùn. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba tí òun náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa. . . . Wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ!” (Sáàmù 40:5) Pabanbarì rẹ̀ ni pé oore Ọlọ́run kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, títí kan àwọn tí kò mọ̀ ọ́n pàápàá, gbogbo wọn pátá ló ń fi ‘oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.’​—Ìṣe 14:17.

      Ó máa ń rọ̀ wá lọ́rùn láti ṣoore fún àwọn tá a fẹ́ràn tá a sì kà sí

      Jèhófà ń ṣe ipa tiẹ̀ láti ṣe ohun tó máa múnú gbogbo ẹ̀dá dùn, torí náà gbogbo ẹní tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó máa “mú ọkàn-àyà” rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tó máa múnú Ọlọ́run dùn? Bíbélì sọ fún wa, ó ní: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Ṣé ohun tá a wa ń sọ ni pé béèyàn bá ṣáà ti ń ṣoore, tó sì lawọ́, ó parí náà nìyẹn?

      Bíbélì sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 11:6) Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,” ló tó di “Ọ̀rẹ́ Jèhófà.” (Jákọ́bù 2:23) Jésù pàápàá jẹ́rìí sí i pé a gbọ́dọ̀ “lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run” bá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run bù kún wa. (Jòhánù 14:1) Báwo wá la ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run fà wá mọ́ra bí ọ̀rẹ́ rẹ̀? A gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Èyí ló máa jẹ́ ká ní “ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀,” àá sì mọ bí a ṣe lè “wù ú dáadáa.” Bí ìmọ̀ wa nípa Jèhófà ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tá a sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò láyé wa, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i, Jèhófà náà á sì túbọ̀ sún mọ́ wa.​—Kólósè 1:​9, 10.

  • Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù
    Ilé Ìṣọ́—2014 | December 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

      Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù

      Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run? A ti gbé ọ̀nà bíi mélòó kan yẹ̀ wò tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn ni:

      1. Mọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, kó o sì máa lò ó.

      2. Máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà lóòrèkóòrè kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

      3. Máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

      Wàá sún mọ́ Ọlọ́run tó o bá ń lo orúkọ rẹ̀, tó o bá ń bá ń gbàdúrà sí i, tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó o sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́

      Ǹjẹ́ ò ń ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run? Àbí àwọn ibì kan wà tó yẹ kó o tún ṣe? Ká sòótọ́, ó gba ìsapá, àmọ́ tó o bá tẹra mọ́ ọn, wàá ṣe é yọrí.

      Bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọmọ Amẹ́ríkà kan tó ń jẹ́ Jennifer nìyẹn, ó ní: “Gbogbo ìsapá tó o bá ṣe kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìbùkún sì pọ̀ níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wàá túbọ̀ gbára lé Ọlọ́run, wàá sì mọ irú ẹni tó jẹ́, ju gbogbo rẹ̀ lọ, wàá túbọ̀ fẹ́ràn rẹ̀. Kò sí ìgbésí ayé tó tún dára jùyẹn lọ!”

      Bó o bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tán láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o lè ṣe fún ẹ. A máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láì gba kọ́bọ̀. Àǹfààní sì wà fún ẹ láti máa wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tó wà ládùúgbò rẹ, ìyẹn ibi tí á ti máa ń jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tó o bá wá síbẹ̀ wàá rí bá a ṣe máa ń ṣe síra wa bí ọmọ ìyá torí pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a sì mọyì ìrẹ́pọ̀ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀.a Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìdí tí onísáàmù kan fi sọ pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”​—⁠Sáàmù 73:28.

      a Tó o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ládùúgbò rẹ, sọ fún ẹni tó fún ẹ ní ìwé yìí tàbí kó o lọ sórí ìkànnì www.jw.org/yo. Wo ìlujá tá a pè ní KÀN SÍ WA tó wà ní ìsàlẹ̀ ojúde ìkànnì náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́