-
Ṣé Sátánì Wà Lóòótọ́?Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ SÁTÁNÌ WÀ LÓÒÓTỌ́?
Ṣé Sátánì Wà Lóòótọ́?
Ère kan ní ìlú Madrid lórílẹ̀-èdè Sípéènì ń ṣàpẹẹrẹ Sátánì gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì burúkú tó ti tẹ́
“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, bí mo bá ṣe ìjàngbọ̀n, màmá mi á sọ fún mi pé, ‘Èṣù ń bọ̀ wá mú ẹ o!’ Èmi náà á dáhùn pé, ‘Ẹ jẹ́ kó máa bọ̀!’ Ọlọ́run ni mo mọ̀, mi o mọ Sátánì.”—ROGELIO, EL SALVADOR.
Ṣé ìwọ náà gba ohun tí Rogelio sọ gbọ́? Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí lo gbà pé ó jóòótọ́?
tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan búburú ni Sátánì, kì í ṣe ẹni gidi.
Sátánì wà, àmọ́ kò rí tiwa rò.
Ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni Sátánì, òun ló ń rúná sí ohun tó ń lọ láyé.
Èrò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wọ́pọ̀ láàárín ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lónìí. Àmọ́, ṣé ó pọn dandan ká mọ òótọ́ nípa Sátánì? Bẹ́ẹ̀ nì, torí pé tí Sátánì kì í bá ṣe ẹni gidi, a jẹ́ pé àwọn tó gbà pé Sátánì wà ti ṣìnà. Bákan náà, tó bá jẹ́ pé Sátánì wà, àmọ́ tí kò rí tiwa rò, a jẹ́ pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ kàn ń bẹ̀rù rẹ̀ láìnídìí. Tó bá sì jẹ́ pé lóòótọ́ ni Sátánì máa ń fọgbọ́n àrékérekè tanni jẹ́, a jẹ́ pé ó burú ju ohun tí ọ̀pọ̀ rò lọ.
Ẹ jẹ́ ká wo bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Ta ni Sátánì? Ṣé ẹni gidi ni àbí àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan búburú? Tí Sátánì bá jẹ́ ẹni gidi, ṣé ó lè pa wá lára? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè dáàbò bò ara wa?
-
-
Ṣé Àmì Tó Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Búburú ni Sátánì?Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ SÁTÁNÌ WÀ LÓÒÓTỌ́?
Ṣé Àmì Tó Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Búburú ni Sátánì?
Ó rọrùn láti sọ pé Sátánì kì í ṣe ẹni gidi, àmọ́ ṣé ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn? Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí, kí wá ló dé tí Bíbélì fi sọ pé Sátánì bá Jésù Kristi àti Ọlọ́run Olódùmarè sọ̀rọ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì lára irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀.
ÌGBÀ TÍ SÁTÁNÌ BÁ JÉSÙ SỌ̀RỌ̀
Kété tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni Èṣù ti gẹ̀gùn dè é, ó sì dán Jésù wò lọ́nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tí ebi ń pa Jésù, Sátánì ní kí Jésù lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara rẹ̀ kí ebi má bàa gbẹ̀mí ẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù sọ fún Jésù pé kó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu lọ́nà tí kò tọ́ káwọn èèyàn lè kan sárá sí i. Níkẹyìn, Sátánì sọ pé bí Jésù bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan péré, òun máa fún un ní gbogbo ìjọba ayé. Jésù ká gbogbo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí Sátánì lò yìí, ó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa á lẹ́nu mọ́.—Mátíù 4:1-11; Lúùkù 4:1-13.
Ta ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn? Ṣé èrò búburú kan tó wá sí Jésù lọ́kàn ni àbí ẹni gidi kan ló ń bá sọ̀rọ̀? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dáhùn pé: “A ti dán [Jésù] wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:15) Ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ pé: “[Jésù] kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:22) Èyí fi hàn pé ẹni pípé ni Jésù látòkèdélẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, èrò búburú ò sì fìgbà kankan wá sí i lọ́kan rí. Nígbà náà, ó dájú pé ẹni gidi kan ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀.
Ìjíròrò yẹn tún jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan míì tó fi hàn pé ẹni gidi ni Sátánì.
Rántí pé Èṣù lóun máa fún Jésù ní gbogbo ìjọba ayé tó bá jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. (Mátíù 4:8, 9) Sé o rò pé ìyẹn máa nítumọ̀ ká ní Sátánì kì í ṣe ẹni gidi? Àti pé Jésù kò jiyàn bóyá Sátánì ní ọlá àṣẹ yẹn àbí kò ní in.
Lẹ́yìn tí Jésù ti bẹ́gi dí gbogbo àrékérekè tí Sátánì fi dẹ ẹ́ wò, Bíbélì sọ pé “Èṣù fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Nínú ọ̀rọ̀ yìí, a ti rí i pé Sátánì kì í ṣe àmì kan tó ṣàpẹẹrẹ ohun búburú, àmọ́ ó jẹ́ aléni-má-dẹ̀yìn ọ̀tá tó dìídì dájú sọ Jésù kó lè mú un balẹ̀.
Ṣé o rántí pé “àwọn áńgẹ́lì wá ṣe ìránṣẹ́ fún” Jésù? (Mátíù 4:11) Àwọn áńgẹ́lì tó wá ran Jésù lọ́wọ́ tí wọ́n sì fún un níṣìírí kì í ṣe àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan, àmọ́ wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ní ti gidi. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Sátánì náà ò lè jẹ́ àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan búburú, ẹni gidi kan tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí lòun náà.
ÌGBÀ TÍ SÁTÁNÌ BÁ ỌLỌ́RUN SỌ̀RỌ̀
Ìjíròrò kejì tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò dá lórí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èṣù àti Ọlọ́run jọ sọ̀rọ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì yìí náà ni Ọlọ́run yin Jóòbù fún ìdúróṣinṣin rẹ̀. Sátánì sọ pé torí ohun tí Jóòbù ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín, ìyẹn ni pé Ọlọ́run ń fún Jóòbù ní ẹ̀gúnjẹ kó lè máa ṣe tiẹ̀. Ohun tí Èṣù fẹ́ fà yọ ni pé òun mọ Jóòbù ju bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ ọ́n lọ. Jèhófà wá gba Sátánì láyè láti ṣèfẹ́ inú rẹ̀.a Èṣù kọ́kọ́ sọ Jóòbù di ẹdun arinlẹ̀, gbogbo ohun tó ti fi àárọ̀ ọjọ́ kó jọ ló pa run lójijì. Àwọn ọmọ rẹ̀ ṣán ku lójú ẹ̀mí rẹ̀, àìsàn sì tún gbé e dè. Láìka èyí sí, Jóòbù ò sẹ́ Ọlọ́run, èyí fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa, ó sì dá Jèhófà láre pé òótọ́ ni ohun tó sọ nípa Jóòbù. Níkẹyìn, Ọlọ́run bù kún Jóòbù nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀.—Jóòbù 1:6-12; 2:1-7.
Nínú àwọn ìjíròrò yìí, ṣé ẹni gidi kan ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ ni àbí èrò búburú kan tó ń sọ sí i lọ́kàn? Jèhófà kò lè ní èrò búburú kankan lọ́kàn torí ó pé pérépéré láìkù síbì kan. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 22:31) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè.” (Ìṣípayá 4:8) Mímọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí kí nǹkan mọ́ tónítóní, kó jẹ́ aláìlẹ́gbin, aláìní àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kankan.
Lẹ́yìn tí Sátánì bá Ọlọ́run jíròrò tán, Sátánì fa àdánù ńlá bá Jóòbù
Síbẹ̀ àwọn kan ò rò pé Jóòbù pàápàá jẹ́ ẹni gidi, wọ́n sọ pé fàbú ni ìtàn yẹn. Àmọ́ tá a bá wò ó dáadáa, àá rí i pé ìtàn náà kì í ṣe fàbú rárá. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi ni Jóòbù. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Jákọ́bù 5:7-11 sọ pé Jóòbù jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà táwa Kristẹni lónìí lè fara wé nígbà tá a bá kojú àwọn àdánwò tó le koko, ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa san èrè fáwọn tó bá ní ìfaradà. Àmọ́ ṣé àpẹẹrẹ yẹn máa wọni lọ́kàn tó bá jẹ́ pé Jóòbù ò gbé láyé rí tí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn sì jẹ́ àròsọ? Bákan náà, ìwé Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20 mẹ́nu kan Jóòbù lára àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì bíi Nóà àti Dáníẹ́lì. Bí Nóà àti Dáníẹ́lì ṣe jẹ́ ẹni gidi, bẹ́ẹ̀ náà ni Jóòbù jẹ́ ẹni gidi tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé tí Jóòbù bá jẹ́ ẹni gidi, Sátánì ìyẹn ẹni tó fojú Jóòbù gbolẹ̀ tó sì hàn án léèmọ̀, gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni gidi.
Àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Sátánì jẹ́ ẹni gidi, ẹ̀dá ẹ̀mí sì ni. Àmọ́ o lè máa ronú pé, ‘ayé àtijọ́ nìyẹn, kò dájú pé Sátánì lè ṣe èmi àti ìdílé mi ní jàǹbá lóde òní.’
ÒDE ÒNÍ ŃKỌ́?
Ká sọ pé àwọn jàǹdùkú ṣàdédé ya wọ àdúgbò rẹ tí wọ́n sì sọ ibẹ̀ dilé, ó dájú pé ìwà ìpáǹle á bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀, ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn á sì wà nínú ewu. Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí nìyẹn, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n jọ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ti wà lórí ilẹ̀ ayé. Ìwọ náà fara balẹ̀ wo ohun tí ìyẹn ti fà nínú àwọn ìròyìn tó ń jáde nílé lóko:
Ǹjẹ́ o kíyè sí pé àwọn ìwà burúkú tó bùáyà túbọ̀ ń pọ̀ sí i láìka ìsapá ìjọba láti fòpin sí ìwà ipá?
Ṣé o rí i pé àwọn fíìmù tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láìka bí ọ̀pọ̀ òbí ṣe kórìíra rẹ̀?
Ǹjẹ́ o kíyè sí pé gbogbo àyíká túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i láìka ètò gbálùúmọ́ àtàwọn ìsapá míì tí ìjọba ń ṣe?
Ǹjẹ́ o kíyè sí bí ayé yìí ṣe ń dojú rú sí i àfi bíi pé agbára àìrí kan ló ń dà á rú kí gbogbo nǹkan lè pa run pátápátá?
Bíbélì ṣàlàyé ohun tó fa gbogbo rúdurùdu yìí, ó ní: “A fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. . . . Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:9, 12) Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n wá gbà pé ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú kan ni Sátánì, òun ló sì ń rúná sí ohun tó ń lọ láyé.
O dájú pé ìwọ náà ò ní fẹ́ kó sínú pańpẹ́ Sátánì. Àkòrí tó tẹ̀ lé e máa sọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti dáàbò bò ara rẹ.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
-
-
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù Sátánì?Ilé Ìṣọ́—2014 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ SÁTÁNÌ WÀ LÓÒÓTỌ́?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù Sátánì?
Bí èéfín carbon monoxide ṣe léwu tí kò sì ṣe é fojú rí, bẹ́ẹ̀ náà ni Sátánì rí
Èéfín olóró kan wà tí wọ́n ń pè ní carbon monoxide irú èyí tó máa ń jáde nínú jẹnẹrétọ̀. Májèlé ni èéfín yìí, ó sì ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn. Ibi tó burú sí ni pé kì í fu èèyàn lára rárá títí tá á fi wọni lára, tá a sì ṣọṣẹ́. Kò ṣe fojú rí, kò sì lóòórùn. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà téèyàn lè ṣe láti dáàbò bò ara rẹ̀ lọ́wọ́ èéfín gbẹ̀mígbẹ̀mí yìí. Ọ̀kan lára ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò ni aago ìdágìrì tó ń tani lólobó tí èéfín yìí bá ti wà nínú afẹ́fẹ́, àwọn náà á sì tètè gbéra sọ tó bá ti ké.
Bíi ti èéfín olóró yìí, ewèlè ẹ̀dá tí kò ṣe é fojú rí ni Sátánì, òun náà sì máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́. Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù rẹ̀ torí pé Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà àbáyọ fún wa. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára rẹ̀ yẹ̀ wò, ká sì rí bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa:
Òmìnira láti ṣe ìpinnu. Ìwé Jákọ́bù 4:7 sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Sátánì lágbára lóòótọ́, àmọ́, kò lè fipá mú ẹ ṣe ohun tí kò wù ẹ́. Bóyá tibí ni wàá ṣe tàbí tọ̀hún, ìpinnu yẹn dọwọ́ ẹ. Ìwé 1 Pétérù 5:9 sọ pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Èṣù], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” Rántí pé Sátánì fi Jésù sílẹ̀ lẹ́yìn tó dẹ ẹ́ wò lẹ́ẹ̀mẹ́ta, tó sì rí i pé ìpinnu Jésù ṣe ṣàkó. (Mátíù 4:11) Ìwọ náà lè pinnu pé o kò ní gbà fún Sátánì.
Bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́. Ìwé Jákọ́bù 4:8 gbà wá níyànjú pé ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” Jèhófà dìídì nawọ́ àǹfààní yẹn sí ẹ pé kó o bá òun ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ o lè máa rò ó pé báwo lo ṣe fẹ́ ṣe é? Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ kó o ṣe ní pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì. (Jòhánù 17:3) Ohun tó o bá kọ́ nípa Jèhófà máa mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìfẹ́ tó o bá ní fún un ló máa sún ẹ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Jòhánù 5:3) Ìwé Jákọ́bù yẹn fi kún un pé bó o bá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Bàbá rẹ ọ̀run, ‘[Ọlọ́run] yóò sún mọ́ ẹ.’
Jèhófà pèsè ọ̀nà àbáyọ fún wa
Ààbò tí Ọlọ́run ń pèsè. Ìwé Òwe 18:10 kà pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé orúkọ Ọlọ́run dà bí oògùn téèyàn ṣe sára fún ààbò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run lè ké pè é nígbàkigbà tí wọ́n bá nílò ààbò rẹ̀.
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Ìwé Ìṣe 19:19 sọ ohun kan tó jọni lójú nípa àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni nílùú Éfésù, ó ní: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣe àròpọ̀ iye owó wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] ẹyọ fàdákà.”a Gbogbo ohun èlò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò làwọn Kristẹni wọ̀nyẹn dà nù pátápátá láìka iye tó ná wọn sí. Àpẹẹrẹ nìyẹn jẹ́ fún àwa Kristẹni torí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ti wọnú onírúurú ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, wọ́n sì ti jingíri sínú àwọn àṣà ìbẹ́mìílò gbogbo. Kódà àwọn nǹkan téèyàn ò kà kún tẹ́lẹ̀ tàbí tí ò tó nǹkan ti wá léwu báyìí, ó sì lè mú káwọn ẹ̀mí èṣù máa dani láàmú. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká yẹ ara wa wò, ká sì kó àwọn nǹkan yìí dà nù láìka ohun tó lè ná wa sí.—Diutarónómì 18:10-12.
Rogelio tá a mẹ́nu kàn ní àkòrí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé yìí kò kọ́kọ́ gbà pé Sátánì wà, àmọ́ lẹ́yìn àádọ́ta ọdún, ó tún èrò rẹ̀ pa. Òun fúnra rẹ̀ sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, mo gba Bíbélì kan. Ẹ̀kọ́ tí mo sì kọ́ nínú rẹ̀ jẹ́ kí n rí i pé Èṣù wà lóòótọ́. Ohun tí mo kọ́ ló ń ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi kó sí pańpẹ́ rẹ̀.”
“Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kì n rí i pé Èṣù wà lóòótọ́. Ohun tí mo kọ́ yìí ló ń ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi kó sí pańpẹ́ rẹ̀”
Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ kó o jí lọ́jọ́ kan kó o sì gbọ́ pé Sátánì ò sí mọ́? Ọjọ́ náà dínkan lónìí. Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa fi Èṣù tó ń ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà “sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́.” (Ìṣípayá 20:10) Àmọ́ iná gidi àti imí ọjọ́ kò lè ṣèpalára kankan fún ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣe é fojú rí yìí. Torí náà, adágún iná yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé. Ọjọ́ náà á mà lárinrin o fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí pé a ò tún ní gbúròó Sátánì mọ́ láé.
Ní báyìí, túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti àwọn ìlànà rẹ̀.b Fojú inú wo ìgbà yẹn tí gbogbo èèyàn á fi ìdùnnú ké jáde pé, “A dúpẹ́, Sátánì ò sí mọ́!”
a Tó bá jẹ́ pé ẹyọ fàdákà tá à ń sọ yìí jẹ́ owó dínárì Róòmù, a jẹ́ pé owó gọbọi làwọn ìwé tí wọ́n kó dà nù yẹn, torí iye rẹ̀ to owó iṣẹ́ téèyàn máa fi ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] ọjọ́ ṣe!
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Sátánì àti ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìbẹ́mìílò, ka orí 10 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè béèrè ẹ̀dá kan lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá rí
-