Orin 84
“Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ìfẹ́ ńlá lọ́mọ Jáà fi hàn
Torí ó fi ọ̀run sílẹ̀
Kó lè bá èèyàn gbé,
Kó fòótọ́ kọ́ni;
Ìgbà gbogbo lóń sòótọ́ yìí.
Ìtúnú ńlá ló fún èèyàn,
Oríṣi àìlera ló wò.
Ó fòótọ́ ọkàn ṣiṣẹ́ Ọlọ́run,
Ó fìfẹ́ sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”
2. Ìrànwọ́ ńlá ni Jáà fún wa
Tó pèsè ẹrú olóòótọ́,
Táa ńfayọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀,
Táa ńsa ipá wa,
Kónírẹ̀lẹ̀ lè rígbàlà.
Àwọn aláìní sì máa ńmọ̀
Bí a bá nífẹ̀ẹ́ wọn dénú.
Bọ́mọ òrukàn àtopó bá dé,
Ǹjẹ́ fìfẹ́ sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”
(Tún wo Jòh. 18:37; Éfé. 3:19; Fílí. 2:7.)