Orin 57
Àṣàrò Ọkàn Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jẹ́ kí àṣàrò ọkàn mi,
Kí èrò mi ojoojúmọ́,
Dùn mọ́ ọ nínú, Ọlọ́run,
Fẹsẹ̀ mi múlẹ̀ lọ́nà rẹ.
Bí àníyàn gbà mí lọ́kàn,
Tí kò jẹ́ kí nlè sùn lóru,
Ìwọ àti ohun tó tọ̀
Ni màá fọkàn ṣàṣàrò lé.
2. Ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́,
Tó jẹ́ òótọ́ àti rere,
Táa ńròyìn rẹ̀ dáradára,
Kíwọ̀nyí fún mi lálàáfíà.
Ọ̀rọ̀ rẹ wuyì Olúwa.
Ó pọ̀ kọjá àfẹnusọ!
Jẹ́ kí nlè ronú lórí rẹ̀,
Kó gbà mí lọ́kàn tán pátá.
(Tún wo Sm. 49:3; 63:6; 139:17, 23; Fílí. 4:7, 8; 1 Tím. 4:15.)