Orin 43
Ẹ Wà Lójúfò, Ẹ Dúró Gbọn-in, Ẹ Di Alágbára
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Wà lójúfò dúró gbọn-in gbọn-in,
Pinnu láti fara dà.
Ẹ ṣe bí akin ọkùnrin,
Torí ìṣẹ́gun dájú.
Àṣẹ Kristi Jésù la ńtẹ̀ lé,
A dúró gbọn-in gbọn-in ní ẹ̀yìn rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Wà lójúfò, di alágbára!
Fara dàá títí dópin!
2. Wà lójúfò, ronú jinlẹ̀,
Múra láti ṣègbọràn.
Fiyè sí ìtọ́ni Kristi
Tẹ́rú olóòótọ́ ńfúnni.
Gba ìmọ̀ràn àwọn alàgbà,
Tó ńdáàbò bàgùntàn òun òótọ́.
(ÈGBÈ)
Wà lójúfò, di alágbára!
Fara dàá títí dópin!
3. Wà lójúfò, wà níṣọ̀kan
Báa ti ńsọ ìhìn rere.
Àwọn ọ̀tá lè gbéjà kòó,
Aó wàásù títí dópin.
Ẹ kọrin ìyìn kárí ayé.
Wòó! Ọjọ́ Jèhófà ti dé tán!
(ÈGBÈ)
Wà lójúfò, di alágbára!
Fara dàá títí dópin!
(Tún wo Mát. 24:13; Héb. 13:7, 17; 1 Pét. 5:8.)