ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́—2015 | June 1
    • Àwọn nǹkan bíi mọ́tò, ẹ̀rọ GPS, ẹ̀rọ sátẹ́láìtì, ọkọ̀ òfúrufú àti ìmọ̀ ìṣègùn fi hàn pé ìtẹ̀síwájú ti bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ TI RỌ́PÒ BÍBÉLÌ?

      Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa

      Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé bí ewéko, ẹranko àtàwọn nǹkan míì. Wọ́n tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó wà lójú sánmà bí oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń ṣe ìwádìí taápọntaápọn nípa kíkíyèsí bí àwọn nǹkan yìí ṣe ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni iṣẹ́ yìí. Wọ́n lè wà nídìí iṣẹ́ kan fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ oṣù, kódà wọ́n lè lo ọ̀pọ̀ ọdún nídìí rẹ̀ pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà míì wà tí ìsapá wọn máa ń já sí pàbó, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìsapá wọn máa ń ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní. Wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

      Ilé iṣẹ́ kan ní ilẹ̀ Yúróòpù fi ike tó nípọn àti àwọn asẹ́ ìgbàlódé ṣe ẹ̀rọ kan. Ẹ̀rọ yìí máa ń sẹ́ omi ìdọ̀tí, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti mu omi náà láìkó àrùn. Wọ́n máa ń lo ẹ̀rọ yìí ní àwọn àgbègbè tí ìjábá bá ti ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lò ó nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti lọ́dún 2010.

      Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tún gbé àwọn ẹ̀rọ sátẹ́láìtì tó so kọ́ra sí ojú sánmà. Àwọn ẹ̀rọ yìí máa ń jẹ́ kí èèyàn mọ ọ̀nà ibi tó ń lọ. Wọ́n ń pe ẹ̀rọ̀ náà ní Global Positioning System (GPS). Àwọn ológun ni wọ́n dìídì ṣe ẹ̀rọ yìí fún, àmọ́ ní báyìí, àwọn onímọ́tò, àwọn awakọ̀ òfúrufú, àwọn atukọ̀ òkun àti àwọn ọlọ́dẹ ti ń lo ẹ̀rọ yìí. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ṣe ẹ̀rọ yìí, ó ti jẹ́ kó rọrùn láti lọ sí ibikíbi láìbẹ̀rù pé èèyàn máa sọnù.

      Ṣé o máa ń lo fóònù, kọ̀ǹpútà tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì? Ṣé o ti lo àwọn oògùn ìgbàlódé tó mú kí ara rẹ túbọ̀ jí pépé? Ṣé o ti wọ ọkọ̀ òfúrufú rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ìwọ náà ń jèrè nínú àwọn ọ̀nà tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbà ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti gbà ṣe ẹ́ láǹfààní.

      IBI TÍ ÒYE ÀWỌN ONÍMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ DÉ

      Kí òye àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè pọ̀ sí i, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń walẹ̀ jìn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí àwọn onímọ̀ nípa átọ́ọ̀mù ṣe ń tú tìfun-tẹ̀dọ̀ àwọn átọ́ọ̀mù tín-tìn-tín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ nípa ojú sánmà ń ṣe ìwádìí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún sẹ́yìn kí wọ́n lè mọ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run. Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe túbọ̀ ń walẹ̀ jìn débí tí ojú ẹ̀dá èèyàn kò lè tó, àwọn kan nínú wọn ronú pé tí Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní Ẹlẹ́dàá bá wà, ó yẹ kí àwọn lè rí i.

      Àwọn kan tó jẹ́ abẹnugan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tún gbé ọwọ́ tó le jùyẹn lọ. Wọ́n ṣagbátẹrù ohun tí òǹṣèwé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ Amir D. Aczel sọ pé, “ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fi hàn dájú pé kò sí Ọlọ́run.” Bí àpẹẹrẹ, onímọ̀ físíìsì kan tó gbajúmọ̀ kárí ayé sọ pé kò sí ẹ̀rí kankan tó ṣe gúnmọ́ tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run wà. Fún ìdí yìí, ó hàn gbangba pé kò sí Ọlọ́run rárá. Àwọn míì sọ pé pidánpidán kan lásán ni Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní Ẹlẹ́dàá.a

      Àmọ́, ìbéèrè kan ni pé: Ṣé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ gbogbo nǹkan tán nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run, débi tí wọ́n fi ń fọwọ́ sọ̀yà pé kò sí Ọlọ́run? Rárá o. Ká sòótọ́, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti tẹ̀síwájú gan-an, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ò tíì mọ̀, àwọn nǹkan míì sì wà tí àwọn ò lè mọ̀ láéláé. Ọ̀gbẹ́ni Steven Weinberg, tó jẹ́ onímọ̀ físíìsì, tó sì tún gba àmì ẹ̀yẹ Nobel sọ nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run pé: “A ò lè rídìí gbogbo nǹkan láé.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Martin Rees tó jẹ́ ọ̀gá àwọn onímọ̀ nípa ojú sánmà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àìmọye nǹkan ló wà tí àwa èèyàn kò lè lóye láé.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì mọ̀ rárá, látorí sẹ́ẹ̀lì bíńtín dé orí àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà lójú sánmà. Díẹ̀ lára wọn rèé:

      • DNA

        Nǹkan díẹ̀ ni àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ṣì mọ̀ nípa bí àwọn sẹ́ẹ̀lì tín-tìn-tín inú ara ṣe ń ṣiṣẹ́. Wọn ò tíì lóye bí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe ń gba agbára, bí wọ́n ṣe ń pèsè èròjà aṣaralóore tí ara nílò àti bí wọ́n ṣe ń pín ara wọn.

      • Ọmọ kan sọ bọ́ọ̀lù sílẹ̀

        Agbára òòfà ló máa ń jẹ́ kí ohun tá a sọ sókè pa dà wá sílẹ̀. Síbẹ̀ ó ṣì ń ṣe àwọn onímọ̀ físíìsì ní kàyéfì. Títí di báyìí, wọn ò tíì lóye bí agbára yìí ṣe ń mú kí èèyàn wálẹ̀ nígbà tó bá fò sókè àti bó ṣe ń mú kí òṣùpá máa yí ayé po.

      • Ìsálú ọ̀run

        Àwọn onímọ̀ nípa ohun tó wà lójú ọ̀run fojú bù ú pé ohun tó ju ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn nǹkan tó wà ní ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run ni kò ṣe é rí. Kò tiẹ̀ sí ẹ̀rọ kankan tí wọ́n lè fi ṣe ìwádìí nípa wọn. Ohun tí àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ kò tíì yé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.

      Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan míì ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tíì mọ̀ tó sì máa ń ṣe wọ́n ní kàyéfì. Kí nìdí táwọn nǹkan yìí fi ṣe pàtàkì? Òǹkọ̀wé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó gbajúmọ̀ sọ pé: “Ohun tá a mọ̀ kò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tá ò tíì mọ̀. Ní tèmi o, ńṣe lohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí yẹ kó wúni lórí, kó sì mú kéèyàn fẹ́ mọ ohun púpọ̀ sí i, dípò tí èèyàn á fi máa ṣe lámèyítọ́.”

      Tó bá ń ṣe ẹ́ bí i pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì máa tó rọ́pò Bíbélì, tí kò sì ní jẹ́ káwọn èèyàn gba Ọlọ́run gbọ́ mọ́, á dáa kó o ronú nípa kókó yìí: Ìmọ̀ díẹ̀ ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ní nípa ayé àti ìsálú ọ̀run láìka àwọn ẹ̀rọ ńláńlá tí wọ́n fi ń ṣe ìwádìí sí. Tó fi hàn pé àwọn nǹkan kan ṣì wà tí wọn ò tíì mọ̀, ṣe a wá lè sọ pé àwọn nǹkan tí wọn ò mọ̀ yẹn kò ṣe pàtàkì ni? Kókó yìí ni ìwé Encyclopedia Britannica fi parí àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí ìtàn àti ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ àwọn onímọ̀ nípa sánmà, ó ní: “Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún táwọn èèyàn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa sánmà, wọ́n ò tíì lè ṣàlàyé gbogbo ohun tó wà ní ìsálú ọ̀run bí àwọn ará Bábílónì ìgbàanì kò ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀.”

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kálukú ló ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tó máa gbà gbọ́ lórí kókó yìí. A máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣàyẹ̀wò bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe bá Bíbélì mu.

      a Àwọn kan ò gba Bíbélì gbọ́ torí pé wọn kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi kọ́ni láyé àtijọ́ àti èyí tí wọ́n fi ń kọ́ni lóde òní. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni pé ńṣe ni oòrùn, òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ń yí ayé po. Wọn ò tún fara mọ́ ẹ̀kọ́ náà pé ọjọ́ mẹ́fà tó jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún péré ni Ọlọ́run fi dá ayé.—Wo àpótí náà “Bí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ṣe Bá Bíbélì Mu.”

      Bí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ṣe Bá Bíbélì Mu

      Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Síbẹ̀, àwọn tó kọ Bíbélì sọ ohun tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì lọ́nà tó péye gan-an, èyí sì gba àfiyèsí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lóde òní. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn.

      • Ìsálú ọ̀run

        Ìgbà tí ayé àti ìsálú ọ̀run ti wà

        Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé ayé yìí ti wà láti nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rin ọdún sẹ́yìn. Wọ́n tún sọ pé ìsálú ọ̀run ti wà láti nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́tàlá sí bílíọ̀nù mẹ́rìnlá ọdún sẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ìgbà tí ayé àti ìsálú ọ̀run ti wà, síbẹ̀, kò sí ibi kankan tó ti sọ pé ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni Ọlọ́run dá ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Bí Bíbélì kò ṣe sọ ìgbà kan pàtó tí Ọlọ́run dá ayé yìí ti mú kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lo ìlànà ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti fojú bu ìgbà tí ayé yìí ti wà.

      • Àwọn òkè ńlá, ewéko àti omi

        Bí ọjọ́ ìṣẹ̀dá ṣe gùn tó

        Ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí 1 lo ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” láti jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe dá ayé yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé kó báa lè ṣeé ṣe fún onírúurú ẹ̀dá abẹ̀mí láti gbé inú rẹ̀. Nínú àwọn nǹkan abẹ̀mí yìí, àwa èèyàn ni Ọlọ́run dá gbẹ̀yìn. Bíbélì ò sọ bí “ọjọ́” mẹ́fà tí ìṣẹ̀dá fi wáyé ṣe gùn tó. Èyí mú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní lè ṣèwádìí, kí wọ́n sì sọ bí ọjọ́ ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ṣe gùn tó. Ohun tó dájú ni pé “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún.

      • Ilẹ̀ ayé

        Ohun tó gbé ayé dúró

        Àwọn ìtàn àròsọ ayé àtijọ́ kan sọ pé orí èjìká erin tàbí ẹ̀yìn erin ńlá kan tó dúró sórí ìjàpá ni ayé yìí wà. Àmọ́, kì í ṣe ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn. Ohun tó sọ ni pé ayé yìí “rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Ohun tí Bíbélì sọ yìí ti mú kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ìwádìí nípa ohun tó gbé ayé dúró. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Nicolaus Copernicus àti Johannes Kepler sọ bí agbára kan tí a kò lè fojú rí ṣe ń mú kí ayé máa yí oòrùn po. Nígbà tó yá, Isaac Newton ṣàlàyé bí agbára òòfà ṣe ń darí àwọn ohun tó wà lójú sánmà.

      • Kòkòrò bacteria

        Béèyàn ṣe lè dènà àrùn, tí á sì jẹ́ onímọ̀ọ́tótó

        Ìwé Léfítíkù sọ ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè dènà àjàkálẹ̀ àrùn. Ó sọ pé kí ẹni tó bá ní àrùn lọ máa gbé ẹ̀yìn òde ìlú. Lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, òfin tó wà nínú ìwé Diutarónómì 23:12, 13, sọ pé ẹ̀yìn ibùdó ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ máa ṣe ìgbọ̀nsẹ̀. Wọ́n sì tún gbọ́dọ̀ ‘bo ìgbọ̀nsẹ̀’ náà mọ́lẹ̀. Kò tíì ju igba [200] ọdún báyìí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn oníṣègùn ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé ó yẹ káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀.

      Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a gbé yẹ̀ wò yìí ti wà láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Báwo ni àwọn tó kọ Bíbélì ṣe mọ àwọn òtítọ́ yìí nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀wé ìgbà ayé wọn kò mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ọlọ́run tó mí sí àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.”—Aísáyà 55:9.

  • Ibi Tí Òye Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mọ
    Ilé Ìṣọ́—2015 | June 1
    • Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ń ṣe ìwádìí

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ TI RỌ́PÒ BÍBÉLÌ?

      Ibi Tí Òye Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mọ

      Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n tẹ àwọn ìwé kan jáde. Àwọn ìwé náà ṣàlàyé èrò àwọn tó gbà pé kò sí Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ ka ìwé yìí. Ìwé náà sì ti dá àríyànjiyàn ńlá sílẹ̀ nípa bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí. David Eagleman tó jẹ́ onímọ̀ nípa iṣan ara sọ nípa ìwé náà pé, èrò àwọn kan lára àwọn tó ka ìwé náà ni pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ gbogbo nǹkan tán. Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ kì í ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Iṣẹ́ wọn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣàwárí àwọn nǹkan tuntun tó máa ń yani lẹ́nu.

      Onímọ̀ nípa sánmà kan ń lo awò tí wọ́n fi ń wo ọ̀nà jíjìn

      Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọ́ṣẹ́ dunjú ti máa ń ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tó jẹ́ àwámáàrídìí nínú ayé. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n rí máa ń yani lẹ́nu. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lára wọn máa ń ṣe àṣìṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwádìí náà. Bí àpẹẹrẹ, Isaac Newton jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọṣẹ́ jù lọ. Òun ló sọ bí agbára òòfà ṣe ń mú kí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, ìràwọ̀ àti àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wà pa pọ̀, tí wọn ò sì kọlu ara wọn. Òun náà ló ṣàwárí ẹ̀ka ìṣirò kan tí wọ́n fi ń ṣe kọ̀ǹpútà, ìyẹn calculus. Ẹ̀ka ìṣirò yìí náà ni àwọn tó ń rìnrìn àjò lójú òfúrufú máa ń lò, àwọn onímọ̀ nípa átọ́ọ̀mù náà sì ń lò ó. Ṣùgbọ́n Newton tún lọ́wọ́ sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní alchemy, tó ní í ṣe pẹ̀lú wíwo ìràwọ̀ àti idán pípa, torí pé ó ń wá bó ṣe lè sọ irin lásán di góòlù.

      Onímọ̀ nípa sánmà kan wà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ptolemy. Ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ni. Ó gbé ayé ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún kí wọ́n tó bí Newton. Ojú lásán ni ọ̀gbẹ́ni yìí fi ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wà lójú sánmà. Ó máa ń tọpasẹ̀ àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú sánmà lọ́wọ́ alẹ́. Bákan náà, ó mọ̀ nípa yíya àwòrán ilẹ̀ gan-an. Àmọ́, ó gbà pé ààrín ni ayé yìí wà, tí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ sì ń yípo rẹ̀. Carl Sagan tó jẹ́ onímọ̀ nípa sánmà sọ pé, ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún gbáko ni àwọn èèyàn fi gba èrò tí kò tọ́ tí Ptolemy ní yìí gbọ́. Èyí fi hàn pé, èèyàn jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣe àṣìṣe tó bùáyà.

      Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ń ka Bíbélì

      Lónìí, kì í ṣe gbogbo ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ ni èèyàn lè gbára lé. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ lè ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run? Ká sòótọ́, ìtẹ̀síwájú ti bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àǹfààní tó sì ń ṣe wá kúrò ní kèrémí. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣe. Paul Davies tó jẹ́ onímọ̀ nípa físíìsì sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run, kí àlàyé náà sì bára mu délẹ̀délẹ̀.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é já ní koro ni ọ̀gbẹ́ni yìí sọ. Ìyẹn ni pé: Àwa èèyàn kò lè mọ gbogbo nǹkan nípa ayé àti ìsálú ọ̀run láéláé. Fún ìdí yìí, tí àwọn èèyàn kan bá sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣàlàyé nípa gbogbo nǹkan tó wà lọ́run àti láyé, kò yẹ ká gbára lé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pátápátá.

      Láìsí àní-àní, Bíbélì fún wa ní ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè fún wa

      Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà lọ́run àti láyé pé: “Wò ó! Ìwọ̀nyí jẹ́ bèbè àwọn ọ̀nà [Ọlọ́run], àhegbọ́ mà ni ohun tí a sì gbọ́ nípa rẹ̀!” (Jóòbù 26:14) Ọ̀kẹ́ àìmọye nǹkan ló ṣì wà táwa èèyàn ò mọ, tó jẹ́ pé ó kọjá ìrònú àti òye ẹ̀dá. Kò sí àní-àní pé, ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn ṣì jẹ́ òótọ́ títí dòní. Ó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!”—Róòmù 11:33.

      Ìtọ́sọ́nà Tí Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Kò Lè Fún Wa

      Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń pèsè ìsọfúnni nípa ilẹ̀ ayé, àmọ́ Bíbélì nìkan ló lè fún wa ní ìlànà àti ìtọ́sọ́nà tó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ká láyọ̀, kí ìgbésí ayé wa sì tòrò. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.

      • Ọwọ́ kan tí wọ́n fi ṣe àmì dúró

        Dídènà Ìwà Ọ̀daràn

        Jẹ́ kí ẹ̀mí èèyàn jọ ẹ́ lójú

        “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.” —Ẹ́kísódù 20:13.

        “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn.” —1 Jòhánù 3:15.

        Jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà

        “Yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe ohun rere; máa wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.”—Sáàmù 34:14.

        “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.”—Jákọ́bù 3:18.

        Má ṣe hùwà jàgídíjàgan

        “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.

        “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Òwe 3:31, 32.

      • Ìdílé kan

        Bí Ìdílé Ṣe Lè Láyọ̀

        Gbọ́ràn sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu

        “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’”—Éfésù 6:1-3.

        Kọ́ àwọn ọmọ rẹ dáadáa

        “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” —Éfésù 6:4.

        “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21.

        Nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ, kó o sì bọ̀wọ̀ fún un

        “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.

      • Igi kan

        Ìmọ́tótó àyíká

        Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń ba àyíká jẹ́ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “A ti sọ ilẹ̀ náà gan-an di eléèérí lábẹ́ àwọn olùgbé rẹ̀, . . . a sì ka àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ sí ẹlẹ́bi.” (Aísáyà 24:5, 6) Ọlọ́run máa fìyà jẹ gbogbo àwọn ẹni ibi tó ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Wọn kò ní lọ láìjìyà ìwà ìbàjẹ́ wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́